Àǹfàní wo ni ìpadàbọ̀ Abìjà Donald Trump yóò ṣe fún gbogbo àgbáyé?

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oni ogunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2025 ni Donald Trump yoo pada wọ ile Aarẹ Amẹrika, White House, lẹyin to bori ibo to waye loṣu Kọkanla, ọdun to kọja.

Ni ipadabọ rẹ yii lo ti sọ pe oun yoo fi ilẹ Amẹrika ṣe akọkọ ninu gbogbo ohun ti oun ba dawọle lori oye.

Iwọnyii ni awọn ohun to ṣeeṣe ki Trump ṣe to ba pada de ori alefa lẹyin to ti kọkọ joko sori aga naa laarin ọdun 2017 si ọdun 2021,

Ukraine

Trump ati Volodymyr Zelensky

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Trump ati olori Ukraine

Lasiko ipolongo ibo, Trump sọ pe oun yoo fopin si ogun to n lọ lọwọ laarin Russia ati Ukraine "laarin ọjọ kan pere."

O ni oun ko faramọ ẹgbẹlẹgbẹ owo dọla ti ileeṣẹ ologun Amẹrika n na lori ogun naa lati ọdun 2022.

Amọ awọn kan to wa lẹyin Ukraine ti sọ pe ipo Trump naa le mu Ukraine fi awọn ilẹ kan silẹ fun Russia ki ogun naa le tete pari.

Ẹni ti wọn kede gẹgẹ bii aṣoju Trump si Russia ati Ukraine, Keith Kellogg, sọ fun ileeṣẹ iroyin Fox News pe laarin ọgọrun ọjọ pere ni oun yoo wa ojutu si ogun naa laarin orilẹede mejeji.

Trump ni Aarẹ Russia, Vladimir Putin ti ṣetan lati ṣe ipade pẹlu oun, awọn alabaṣiṣẹ oun si ti n ṣeto bi ipde naa yoo ṣe waye.

Nato

US army ni Gniew, Poland

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ ọmọ ogun North Atlantic Treaty Organization (Nato), ti orilẹede mẹtalelọgbọn wa ninu rẹ, ti lara wọn si jẹ ilẹ Amẹrika, Gẹẹsi, Germany ati France jẹ lara ẹgbẹ ti Trump ko fẹran.

Nigba to kọkọ ṣe Aarẹ o dunkoko lati ko ọmọ ogun Amẹrika kuro ninu ẹgbẹ ọmọ ogun naa ti awọn orilẹede to ku ko ba na ida meji owo ti orilẹede wọn n pa wọle lori ẹgbẹ ọhun gẹgẹ bii adehun wọn.

O tun ni Amẹrika ko ni ṣatilẹyin fun orilẹede ti ko ba san owo to yẹ ko san sinu ẹgbẹ ọhun lasiko ogun.

Amọ ṣa, bi awọn kan ṣe n sọ pe yoo ko Amẹrika kuro ninu Nato, lawọn kan n sọ pe ko ni ṣe bẹẹ lailai.

Iha Middle East

Iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iburawọle Trump n waye lẹyin ọjọ diẹ ti Israel at Hamas sọ pe awọn n fẹ dawọ ogun duro.

Amọ awọn onimọ ti n sọ pe yoo ṣoro lati le mu adehun dagunro naa ṣẹ ki ogun le di ohun igbagbe nibẹ.

Nigba saa Trump akọkọ, o ṣe awọn atilẹyin kan fun Israel, lara rẹ ni bo ṣe kede Jerusalem gẹgẹ bii olu ilu Israel, to si gbe ọọfisi ijọba Amẹrika kuro ni Tel Aviv.

Bẹẹ naa lo tun fi iya jẹ Iran lẹyin ti wọn gbẹmi ọgagun Qasem Solemani.

Awọn alatako rẹ sọ pe awọn igbesẹ rẹ ṣakoba fun agbegbe naa, paapaa fun Palestine.

Lẹyin adehun dagunro larin Israel ati Hamas, o ni oun yoo ṣe ohun to yẹ lati mu alaafia wa ni agbegbe ọhun.

China

 Hsinchu, Taiwa, 2024

Oríṣun àwòrán, Getty

Ni saa akọkọ Trump, o gbena woju China, ni saa keji rẹ yii, o ni oun yoo maa gba ida 60% owo ori lori gbogbo ọja to ba wọ Amẹrika lati China.

Awọn eeyan kan gbagbọ pe awọn to yan sipo akọwe ijọba rẹ, Marco Rubio, ati olubadamọran nipa eto abo, Mike Waltz, ni nnnkan ṣe pẹlu iha to kọ si China.

Nipa ọrọ Taiwan, Amẹrika ni oun yoo maa ṣe iranwọ ohun ija ogun sibẹ, amọ igbesẹ naa ko tẹ China lọrun.

Bo tilẹ jẹ pe o ṣoro lati sọ igbesẹ ti Amẹrika yoo gbe ti China ba kọlu Taiwan, amọ Aarẹ to n fi ipo silẹ, Joe Biden ti sọ pe Amẹrika ko ni kawọ gbera ti China ba ṣe bẹẹ.

Ayipada oju ọjọ

 Ventura, California

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ṣeeṣe ki Aarẹ Amẹrika naa yọ ọwọ ilẹ ọhun kuro ninu adehun Paris 2015 lori ayipada oju ọjọ.

Trump sọ pe oun faramọ ki awọn eeyan ṣi maa lo epo rọbi to n jade lati inu ilẹ.

Amọ ṣa, awọn to n ṣegbe lẹyin lilo batiri ati oorun fun ina mọnamọna ati ohun amuṣagbara ti sọ pe Trump yoo fa ọwọ aago idojukọ ayipada oju ọjọ sẹyin.

Irinajo

U.S.-Mexico, Lukeville, Arizona

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Trump ti ṣeleri lati le awọn ọmọ ilẹ okere to n gbe nilẹ naa lai ni iwe igbelu pada silẹ wọn.

O ni ọjọ oun akọkọ nile ijọba ni oun yoo bẹrẹ si n le wọn pada, oun ni yoo si le eeyan to pọ julọ pada silẹ wọn ninu iwe itan.

Nnkan bii miliọnu mọkanla eeyan lo n gbe l'Amẹrika lai ni iwe igbelu, wọn si ti lo ọpọ ọdun nibẹ.

Trump tun ni oun yoo fopin si sisọ ẹnikẹni ti wọn ba bi silẹ naa di ọmọ oniluu.

Greenland ati the Panama Canal

 Ilulissat, Greenland

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Trump ti kọkọ sọ ṣaaju pe oun yoo ra Greenland ti oun yoo si gba iṣakoso Panama Canal.

Nigba ti wọn bere lọwọ rẹ boya yoo lo ologun nibẹ tabi lo oidunkokomọni nipa ti ọrọ aje, o ni oun ko tii mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ.

Greenland yii ni iroyin sọ pe o ni ọpọ ohun alumọni, amọ orilẹede Denmark ati olootu ijọba erekusu naa ti sọ pe kii ṣe fun tita.