Ariwo sọ bí ọ́kùnrin kan ṣe kéde pé òun ti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọmọdébìnrin ọdún mẹ́jọ tí wọ́n ń wá

Aworan olufẹhonuhan ni Mogadishu, Somalia

Oríṣun àwòrán, Mohamed Salh

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ eeyan lorilẹede Somalia lo tutọ soke foju gba a lẹyin ti wọn ba ọmọdebinrin ọdun mẹjọ ti wọn ti n wa fun oṣu mẹfa nile ọkunrin kan to sọ pe oun ti fẹ ọmọ naa sile gẹgẹ bi iyawo oun.

Loṣu kẹsan an ọdun 2024 ni ẹbi ọmọ naa kede pe awọn n wa ọmọ ọhun lẹkun Puntland.

Lẹyìn oṣu bii meloo kan ni iroyin kan fidi rẹ múlẹ pe baba ọmọ naa ti gba latí fi fun ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Sheikh Mahmoud gẹgẹ bi iyawo.

"Ohun to buru ni pe ọpọ eeyan lo ti ro pe awọn ajinigbe lo gbe ọmọ naa"

Awọn agbofinro rọgba yika ile ọkunrin naa lọsẹ to lọ, amọ, wọn ni lati fi tipa tipa wọle rẹ lẹyin ti ọkunrin naa ti ara rẹ mọ inu yara pẹlu ọmọdebinrin ọhun.

Ẹwẹ, awọn araalu ti n ṣe ifehonuhan ni Mogadishu ti i ṣe olu ilu orilẹede Somalia latari iṣẹlẹ yii.

Iṣẹlẹ yii tun ti jẹ ki ọpọ máa sọ nipa agbekalẹ ofin ti yoo máa daabo b'awọn ọmọde tori ko sì ofin to sọ ọjọ ori ti ọmọbinrin le lọ ile ọkọ ni Somalia lọwọ yii.

Arabinrin Fadumo Ahmed to jẹ adari ajọ to n ja fẹtọọ awọn obinrin ni Somalia sọ fun BBC pe "ohun to buru ju nipa iṣẹlẹ naa ni pe ọpọ lo ti ro pe awọn ajinigbe lo gbe ọmọ naa, koda, awọn ẹbi rẹ gan an ko mọ ibi to wà.

A ni igbagbọ pe awọn ajọ ti ọrọ kan yóò gbe igbesẹ to yẹ lori ọrọ naa."

Sheikh Mahmoud ni oun o ṣetan lati tu igbeyawo naa ka

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi ibatan ọmọdebinrin naa ṣe ṣalaye, o ni iyekan rẹ kan to jẹ obinrin lo mu ọmọ naa lati ilu Bosaso loṣu kẹsan to kọjá lọ si ilu miran.

O ni obìnrin yìí sọ pe oun n mu un lọ si ọdọ ibatan rẹ mii ni.

Amọ, o ni iyalẹnu lo jẹ wí pe awọn ri fidio ọmọ naa lori ayelujara lẹyìn bíi oṣu meloo kan nibi to ti n ka Keu.

Bayii ni awọn ẹbi rẹ bẹrẹ si ni wa ọmọ naa kaakiri, nigba to ya ni wọn mọ pe Carmo lo wa nibi to ti n gbe pẹlu Sheikh Mahmoud.

Sheikh Mahmoud kọkọ sọ pe Kurani nikan loun n kọ ọmọdebinrin naa.

Amọ, o jẹwọ pe oun ti fẹ ẹ ni iyawo ni nigba to ri pe ọrọ naa ti dé ile ẹjọ.

O ni baba ọmọ naa tí yọnda rẹ foun lati fẹ ẹ sile gẹgẹ iyawo.

Nigba ti BBC beere lọwọ rẹ ìdí to fi fẹ ọmọ odún mẹjọ ni iyawo, o ṣalaye pe alakalẹ ẹṣin musulumi ati ti Anabi Muhammad f'aye gba ki eeyan ṣe igbeyawo pẹlu iru ọmọ bẹẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn onimọ nípa ẹsìn islam lo tako bi o ṣe gbe ọmọdebinrin ọdun mẹjọ sile gẹgẹ bi iyawo, Sheikh Mahmoud ni oun ko ṣetan lati tu igbeyawo naa ka.

Ẹwẹ, awọn ọlọpaa ti mu ọmọ naa kuro nile ọkunrin yii, lẹyìn tàwọn ẹbi rẹ lọ fi ẹjọ rẹ sun ọlọpaa.

Ọmọ yii ti pada sọdọ awọn ẹbi rẹ nigba ti ijọba sì ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Igbeyawo pẹlu awọn ọmọde si wọpọ lorilẹede Somalia.