Wo àwọn ànfàní tí wíwà nínú oòrùn ń ṣe fún àgọ́ ara

Ẹni to wa ninu oorun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Fun ọpọ ọdun ni wọn ti n jẹ ko ye wa pe ko dara lati maa wọ inu oorun lai wọ gilaasi to n daabo bo oju lọwọ oorun. Amọ ṣa, agọ ara wa nilo oorun latari awọn anfani ti diduro ninu oorun maa n ṣe fun agọ ara. Oorun maa n mu ara le, o maa n din ẹjẹ riru ku bẹẹ lo maa n fun egugun ati iṣan ara lagbara.

Agbara oorun

Jijoko sinu oorun lati ma gba oorun naa sara le ṣe agọ ara loore pupọ.

Lai si oorun, agọ ara rẹ yoo padanu eroja Vitamin D, eyii to ṣe patati fun Egungun ara rẹ, to fi mọ awon iṣan ati eroja to n gbogun ti aisan ninu agọ ara.

Nilẹ Gẹẹsi, aarin oṣu Kẹrin si oṣu Kẹsan an ọdun ni oorun aṣaraloore maa n mu ju nibẹ.

Pupọ ninu awọn ti vitamin D ara wọn ti dinku lasiko otutu le ri eroja naa pada lasiko ti oorun naa ba n mu.

Amọ ṣa, kii ṣe vitamin D nikan ni anfani oorun.

Agbalagba meji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Mimu inu rẹ dun, mimu ara rẹ ji pepe

Gbogbo wa la mọ pe itanṣan oorun dara pupọ nitori oorun aarọ le mu inu rẹ dun latari bo ṣe maa n tu eroja 'serotonin' silẹ ninu ọpọlọ rẹ, eyii to maa n mu ara balẹ.

Iwadii ijinlẹ kan fi han pe awọn eeyan maa n ni eroja 'serotonin' pupọ lara lọjọ ti oorun ba jade ju awọn ọjọ ti oorun koba jade lọ.

Esi iwadii naa tun fi han pe ọjọ ti oorun ba jade ni ọpọlọ maa n pese 'serotonin' to pọ ju lai ni fi ṣe boya inu ile ni eeyan wa tabi wọn ninu oorun naa nita gbangba.

Yatọ si eyii, iwadii mii tun fi han pe ti eeyan ba duro si abẹ oorun, awọ ara rẹ yoo pese eroja 'endorphin' to maa n mu inu eeyan dun.

O maa n din ẹjẹ riru ku

Iwadii mii tun fi han pe oorun maa mu adinku ba bi ẹjẹ ṣe maa n ru ni agọ ara.

Awọn onimọ sayẹnsi lati fasiti Edinburgh ṣe iwadii kan to fi han pe ti o ba gbe ọwọ rẹ sinu oorun fun ogun iṣẹju pere, yoo to lati pese erojo 'nitric oxide' ninu agọ ara rẹ - eroja naa ni yoo jẹ ki iṣan to n gbe ẹjẹ fẹ si, ti yoo si mu ki bi ẹjẹ ṣe n ru wa silẹ.

Ẹni to n yẹ ifunpa rẹ wo lori ẹrọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ara lile

Vitamin D ṣe pataki fun imularale egungun, ko ni ṣe bi ọjọ ori rẹ ṣe pẹ to, o le mu ọ lagbara si.

Iwadii kan fi han pe lilo eroja vitamin D maa n fun awọn to n ṣe ere idaraya ni okun.

Ẹri tun wa pe vitamin D ọhun maa n dena arun to ni ṣe pẹlu igbọnsẹ ṣiṣe, o si maa n fi agbara kun eroja to n gbogun ti arun ni agọ ara.

Obinrin to n se ere idaraya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oorun jẹ ọna kan gboogi lati ri eroja vitamin D

Ootọ ni pe o le ri eroja vitamin D lati ara ounjẹ amọ o ṣoro lati ri eroja naa lati ara ounjẹ nikan.

Ara ounjẹ ti o ti le ri eroja naa ju ni awọn ẹja kan, ti o ko ba ki n jẹ ẹja, o le ri lati ara inu eyin ati osun, amọ yoo ṣoro lati jẹ eyii ti yoo to ọ fun eroja vitamin D.

Ṣugbọn ọpẹ ni fun Eledua to pese oorun fun ọmọ araye lọfẹẹ, niwọn igba ti oorun ba le kan ọ lara, yoo ṣe ara rẹ loore.

Iwọn iye oorun wo lo to fun agọ ara?

Iwọn iye oorun ti o nilo lati ni eroja vitamin D da lori awọ aa rẹ, ibi ti o n gbe ati bi oorun ṣe le pa ọ lara si.

Ohun to ṣe pataki julọ ni ki oorun naa ma jo ọ lara.

Awọ dudu ni melanin lara, eyii to n daabo bo awọ ara lọwọ oorun to ba pọ ju, amọ aabo yii tun le dena ipese vitamin D.

Awọn ọmọde ninu oorun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kii ṣe oju rẹ nikan ni oorun gbọdọ pa

O le ro pe ki oorun pa oju rẹ nikan ni o nilo amọ oorun naa tun gbọdọ de ọwọ ati ẹsẹ rẹ.

Ọjọgbọn Ann Webb sọ pe aago mejila ọsan ni o le ri oorun ti yoo ṣe ara rẹ loore julọ.

Lootọ lo le nira lati maa wa ninu oorun ni ọsan gangna amọ iwadii ti fi han pe asiko yii gan lo tọ lati ri vitamin D ti yoo ṣe ọ loore.

Oorun to n ran

Oríṣun àwòrán, Getty Images