Òṣèré tíátà, Biola Adebayo ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ fún Dupe Jaiyesinmi, fẹ́ gba ọmọ tọ́ fún-un lábẹ̀ ìjọba Oyo

Biola Bayo

Oríṣun àwòrán, Biola Bayo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Biola Adebayo, ti ke si ijọba ipinlẹ Oyo fun iranlọwọ lati gba ọmọ tọ fun agba oṣere, Dupe Jaiyesimi.

Biola lo sọ ọrọ naa lasiko ifọrọwerọ rẹ pẹlu Jaiyesimi nibi ti Jaiyesimi si sọ pe oun ko ni ọmọ kankan laye.

Bo tilẹ jẹ pe Jaiyesimi sọ pe ọmọ awọn mọlẹbi atawọn ọmọ ọlọmọ mii loun gba tọ, awọn eeyan na a ko ranti oun lọjọogbo, o si jẹ ibanujẹ fun oun.

Amọ lasiko ti Biola n ṣajọyọ ayajọ ọjọ awọn iya lagbaye fun Jaiyesimi, o ni asiko ti to lati gba ọmọ tọ fun un.

Biola sọ pe "A mọ pe mọmi ni awọn ọmọ to pọ, a ti ko miliọnu mẹwaa naira jọ fun wọn lati bẹrẹ owo.

"Amọ a maa gba ọmọ obinrin ti ilera rẹ pe fun wọn tọ, gomina Seyi Makinde ati ajọ to n ri si ọrọ ọmọde nipinlẹ Oyo, a o kan si yin fun iranlọwọ lori ọrọ yii laipẹ.

"A mọ pe pẹlu ipe ori aago kan ṣoṣo, eyii yoo di ṣiṣe, ohun ti a fẹ ko ju ọmọdebinrin kan ṣoṣo ti ilera rẹ da ṣaka fun mama Jaiyesimi."

Ẹwẹ, mama Jaiyesimi funra rẹ ti sọ pe ọmọ ti ọjọ ori rẹ ko ju ọdun mẹfa lọ ni oun n fẹ.

Biola Bayo

Oríṣun àwòrán, Biola Bayo

Biola Adebayo ra ọkọ ayọkẹlẹ fun Jaiyesimi

Ọkọ yii ni Biola ra fun mama Jaiyesimi lẹyin ifọrọwerọ to ti sọ pe oun ko bi ọmọ kankan latari gbogbo igbiyanju oun, ati pe ilẹ ti ta si ti wọn pe oun fun iṣẹ oṣere kẹyin.

Jaiyesimi sọ ninu ifọrọwerọ naa pe "Mo loyun ki n to ṣe igbeyawo, amọ oyun na bajẹ lẹyin ti mo dele ọkọ tan.

"Inu mi dun nigba naa, wọn ṣe ayẹwo fun mi, inu mi si dun pe mo n reti ọmọ laipẹ.

"Ẹni ogoji ọdun ni mi nigba naa, ṣugbọn mi o mọ pe ẹyin ile ọmọ mi ni ọmọ naa wa.

"Lọdun naa lọhun, ti emi ati ọkọ mi ba ti wa lori ibusun, yoo fi pillo si aari awa mejeji ki a ma baa fi ara kanra.

"Lẹyin ọsẹ meji ti mo ko kuro nibẹ ni obinrin mii ko wọle pẹlu oyun ninu. Mo sunkun gidi gan."

Lẹyin naa lo ṣalaye ibanujẹ titọ awọn eeyan mii to jẹ pe ibi ni wọn fi san oore fun un.

Biola Bayo

Oríṣun àwòrán, Biola Bayo