Àtúnṣe afárá 'Independence Bridge' yóò bẹ̀rẹ̀ padà lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta - ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government
Mínísítà fọ́rọ̀ iṣẹ́ òde, Dave Umahi ti sọ pé ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sí àsìkò yìí ni iṣẹ́ yóò gbéra sọ padà níbi afárá Independence Bridge tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko.
Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹrin, Umahi ní iṣẹ́ yóò bẹ̀rẹ̀ padà níbi afárá náà ní kété tí wọ́n bá ti ṣàrídájú rẹ̀ pé àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi mú afárá náà ní ìsàlẹ̀ ti dúró ire.
Ẹ ó rántí pé ìjọba àpapọ̀ ti kọ́kọ́ ti afárá náà lọ́jọ́ Kìíní, oṣù Kẹrin láti bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe iṣẹ́ lórí rẹ̀.
Èyí fa súnkẹrẹ fàkẹrẹ ní agbègbè Erékùsù Eko, tí ọ̀pọ̀ èèyàn wà nínú rẹ̀ fún ó kéré tán wákàtí mẹ́fà.
Ìnira tí súnkẹrẹ fàkẹrẹ náà fà mú kí ìjọba àpapọ̀ kéde pé kí wọ́n ṣì ọ̀nà náà padà láti mú àdínkù bá ìnira táwọn èèyàn tó ń lo ọ̀nà ń kojú.
Umahi wá ní òun mọ ìṣòro táwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Eko ń là kọjá látàrí bí ọ̀nà náà ṣe wà ní títìpa, tí àwọn sì ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti ri pé àwọn ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ níbi ọ̀nà náà lásìkò.
Ó fi kun pé abala méjì ni àwọn máa pín àtúnṣe ọ̀nà ọ̀hún sí lójúnà à ti ri pé àwọn kò ọ̀nà ọ̀hún fún ìgbà pípẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ.
Ó ní ọjọ́ mọ́kànlélógún ni àwọn yóò lò ní abala kọ̀ọ̀kan, tí àwọn yóò sì máa ṣí ọ̀nà náà lẹ́yìn tí ọjọ́ mọ́kànlélógún àkọ́kọ́ bá ti pé.
Mínísítà náà ṣàlàyé pé ibìkan tó jì wọnú níbi afárá náà ló jẹ́ káwọn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí rẹ̀ àti pé àtúnṣe náà máa parí nígbà tó bá máa fi di ìparí oṣù Karùn-ún.
Bákan náà ló rọ àjọ tó ń tún ọ̀nà ṣe ní Nàìjíríà láti máa fi ìròyìn àtúnṣe ọ̀nà tó àwọn aráàlú létí bó ṣe yẹ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní wọ́n gbọdọ̀ máa ṣàlàyé àwọn ọ̀nà mìíràn tí aráàlú le máa gbà tó wọn létí ṣaájú kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àtúnṣe kankan.
Ìgbòkè-gbodò ọkọ̀ àti èrò fọ́jú pọ̀ lánàá bí Ìjọba Eko ṣe ti afárá Indepence pa, aráàlú ń ké ìrora

Ọjọ keji, oṣu Kẹrin ọdun 2025 yii ko ni i tete kuro ni iranti ọpọ eeyan to gba ọna to lọ si Erekuṣu Eko, (Lagos Island) kọja, pẹlu bijọba ṣe ti afara Indepence to so ọpọ ọna pọ, ti kaluku wa n fẹsẹ rin ni popo.
Lati owurọ kutu Ọjọruu naa ni wahala ọhun ti bẹrẹ, awọn ọkọ akero ati aladaani ko rọna gba kọja nitori afara to so Mekwen, Marina, CMS pọ ti wọn ni wọn n tunṣe.
Bi wọn ṣe ti afara kan ṣoṣo yii lo fa a ti awọn ọna to so mọ ọn ṣe di pa.
Ọrọ naa kuro ni sunkẹẹrẹ-fakẹẹrẹ lasan, awọn ọkọ ko tilẹ sun siwaju rara ni, to bẹẹ ti awọn mi-in lo wakati marun-un loju kan.
Bakan naa lọmọ ṣori ni agbegbe Victoria Island, koda, eeyan ko le ri mọto de Obalende.
Awọn to ri mọto wọ ko kuro loju kan, eyi mu ki kawọn ẹlomi-in ko ẹsẹ sọna, wọn rin ibusọ ti wọn ko le ronu ati rin laye.
Awọn mi-in ko tilẹ le kuro ni ọfiisi ninu awọn alakọwe to pọ lawọn agbegbe yii, inu ileeṣẹ wọn ni wọn sun mọju.
Eyi to buru ju ni ti awọn awakọ ero ti wọn sare fi owo nla kun owo ọkọ kia.
Ilọpo mẹta iye ti wọn n gba tẹle lo gun ori owo ọkọ lati Obalende de Eko Hotel ati awọn agbegbe rẹ.
Diẹ ninu iriri awọn eeyan to faragba wahala naa ree, gẹgẹ bi iwadii BBC
Abayomi Micheal- ''Mo wa ninu mọto lai kuro loju kan fun wakati mẹta, mo n bọ lati Obalende lasan ni o, mo si n lọ si VI.
Irin ti ko yẹ ko gba ọgbọn iṣẹju ni mo fi wakati mẹta rin. Mi o pada sile lonii o, mo maa sun si ọfiisi ni''
Rachael Idowu (Alaboyun ni): Mi o kọkọ mọ pe yoo le to bẹẹ. Aarọ ti mo n lọ si VI ni mo kọkọ ri i pe ero pọ ni titi ju bo ṣe yẹ lọ.
''Mo ro pe yoo ti fà nirọlẹ ti mo ba n lọ sile ni, ṣugbọn ori irin ni mo ba ara mi bayii. O ti rẹ mi pẹlu ipo ti mo wa yii, mi o mọ bi mo ṣe maa dele''
Adunni: Aago mẹwaa ni mo kuro nile, aago marun-aabọ ni mo de ibi iṣẹ mi. Mo maa gba ẹnikẹni to ba n lọ sile bayii lati ma ṣe dan an wo. Ọna yii ko ṣee tẹri si.''

''Oṣu meji ni wọn yoo fi ti afara naa pa''

Oríṣun àwòrán, Others
Ninu ikede ti olootu iṣẹ ode ijọba Eko, Abilekọ Olukorede Kesha, kọkọ fi sita ṣaaju lo ti ni oṣu meji gbako ni atunṣe afara naa yoo gba.
Ẹ o ranti pe ijọba apapọ ti kede, pe wọn yoo ti afara Independence pa lati ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin 2025.
Kesha sọ ninu ikede naa pe, "Bi a ṣe fẹẹ ti afara yii pa yoo fa sunkẹẹrẹ-fakẹẹrẹ loju ọna Ahmadu Bello Way ati Adeola Odeku, bi a ba n lọ si Marina, Eko Bridge, ati Onikan lati Zone 2."
Ikede naa ṣalaye pe ipari oṣu Karun-un ni atunṣe afara Indepence yoo too pari.
Ibeere ti araalu n beere bayii ni pe, ṣe bayii naa lawọn yoo maa jiya loju ọna fun oṣu meji.
Awọn ti ko le rin nkọ, alaarẹ, oloyun ati bẹẹ bẹẹ lọ nkọ?
Ẹ ṣi afara Indepence pada - Ijọba apapọ
Lọjọ keji inira naa ti i ṣe Ọjọbọ, Minisita Iṣẹ ode, Sẹnetọ David Umahi, paṣẹ pe ki wọn ṣi afara to n fa inira naa pada kia, ki igbokegbodo ọkọ le rọrun fun ara Eko.
Koda, Olootu iṣe ode Eko, Kesha, fi atẹjade to fi tọrọ aforiji sita.
O ni ileeṣẹ oun koro oju si inira to koju awọn eeyan l'Ọjọruu nitori afara ti wọn ti pa.
Kesha rọ wọn lati fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ode.
"Ileeṣẹ ode ijọba apapọ ti sọ pe wọn yoo maa ṣe atunṣe naa nigba mi-in."
Bẹẹ ni atẹjade naa wi
Ṣugbọn awọn eeyan to ti gba oju ọna naa lowurọ Ọjọbọ, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin yii, sọ pe irọ gbuu ni ṣiṣi ti ijọba kede.
Oṣiṣẹ ileeṣẹ iroyin kan to gba oju ọna naa to si ṣalaye fun BBC, sọ pe:
Irọ gbuu ni, mo ṣi gba ibẹ laaarọ yii, apa ibi ti wọn tipa ṣi wa ni titi.
''Ibi ti wọn si ti ṣi kalẹ fun atunṣe ṣi wa nibẹ pẹlu, wọn ko ti i di i pa, eyi ko le jẹ ki wọn ṣi i pada. Afi bi wọn ba fẹẹ fi nnkan bo o lo ku.''
Ṣaa, inira to koju awọn eeyan ko ti i tan lara, pẹlu bi ọpọ ṣi ṣe n ṣaroye ara ati ẹsẹ riro.















