Ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà kò bá ti gbòòrò tó bá jẹ́ pé ẹ̀mi ni ààrẹ, mo le è ṣe àkóso dára ju Tinubu lọ - Peter Obi, ẹnu dùn ròfọ́ -iléeṣẹ́ ààrẹ fèsì

Bola Tinubu àti Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Peter Obi/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party níbi ètò ìdìbò ọdún 2023, Peter Obi ti ju òkò ọ̀rọ̀ lu ìṣèjọba ààrẹ Bola Tinubu pé wọn kò kójú òṣùwọ̀n láti ṣe àwọn ètò tí yóò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà gbòòrò.

Peter Obi sọ̀rọ̀ yìí níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tó ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn Arise News lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Ó ní kò yẹ kí Tinubu gbé ìgbésẹ̀ tó gbé lórí owó Náírà nígbà tí Nàìjíríà kò ì tíì máa pèsè àwọn ọjà tó bó ṣe yẹ.

Ó sọ pé gbèsè tí Nàìjíríà ń gbà ti pọ̀ jù àti pé iye tí wọ́n fi ń san owó náà padà ju iye tí ìjọba fẹ́ ná sí ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ àti ìlera lọ.

Obi tẹmpẹlẹmọ pé tó bá jẹ́ òun ni ààrẹ, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà máa rí àyípadà tó fojú hàn láàárín ọdún méjì nítorí òun máa kó owó sẹ́ka ìpèsè ọjà èyí tó máa mú ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà dúró ire si.

Ó fi kun ọ̀rọ̀ pé "Tó bá jẹ́ pé èmi ni mo wà nípò ààrẹ ni, mo máa kojú ìwà àjẹbánu pẹ̀lú ọwọ́ líle, mà á mú àdínkù bá iye tí ìjọba ń ná sórí ètò ìṣèjọba. Àwọn ẹ̀ka tó ṣe kókọ ni mà á ná àwọn owó tí a bá yá sí."

Bákan náà ló bu ẹnu àtẹ́ lu iye owó orí táwọn èèyàn àti iléeṣẹ́ ń san lábẹ́ ìṣèjọba Tinubu, ó ní èyí ni kò jẹ́ káwọn iléeṣẹ́ làlùyọ ní Nàìjíríà.

Ó sọ pé kò sí iléeṣẹ́ tó máa fẹ́ dúró ní Nàìjíríà nígbà tí wọ́n bá ń san owó tó lé ní ìdá ogójì (40%) àti pé èyí ló ṣokùnfà ìdá táwọn iléeṣẹ́ tó ń pèsè ọjà kò fi tó nǹkankan ní Nàìjíríà.

Ó ní gbèsè tó wà lọ́rùn Nàìjíríà ń dákún bí ètò ọrọ̀ ajé ṣe ń dẹnu kọlẹ̀, bó ṣe ni iye tí ìjọba fi ń san gbèsè padà lọ́dún ju iye tí wọ́n ń ná lórí ẹ̀kọ́ àti ètò ìlera lọ.

"Ìdá àádọ́rin àwọn ilé ìwòsàn alábọ́dé ni wọn kò ṣiṣẹ́. Gbogbo àwọn ilé ìwòsàn yìí ni mà á ṣe tó bá jẹ́ pé èmi ni ààrẹ ni."

"Ìjọba Tinubu nílò láti gbà pé àwọn ni wọ́n ń fa ìnira tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń kojú nítorí ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ni kò mọ bí ó ṣe máa jẹun."

Peter Obi tún ní Tinubu nílò láti jí gìrì sáwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nítorí àwọn tó ń fi iṣẹ́ rán kò kájú òṣùwọ̀n tó àti pé gẹ́gẹ́ bí olórí, ó nílò agbára àti okún láti sá síbí àti sá sọ́hùn-ún láti ri dájú pé àwọn ètò ń lọ bó ṣe yẹ.

Mo ṣì wà ní Labour Party - Peter Obi

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àjọṣepọ̀ tó ń wáyé láàárín òun àti Atiku, Peter Obi ní ìgbésẹ̀ náà ń wáyé fún ìlọsíwájú Nàìjíríà ni.

Ó ní ọ̀rọ̀ jíjẹ ààrẹ Nàìjíríà kìí ṣe ohun tí òun mú ní dandan bíkòṣe pé ó wu òun láti ri pé Nàìjíríà ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.

Ó fi kun pé ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ṣì ni òun, tí àjọṣepọ̀ sì ń wáyé pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ alátakò mìíràn lójúnà àti mú ìgbà ọ̀tun bá Nàìjíríà.

Iléeṣẹ́ ààrẹ fèsì

Ẹ̀wẹ̀, olùbádámọ̀ràn ààrẹ Bola Tinubu lórí ìròyìn nípa ètò ìjọba, Daniel Bwala lọ́jọ́rú sọ pé ìjákulẹ̀ tí Peter Obi rí lásìkò ètò ìdìbò tó kọjá ni kò ì tíì tán lára rẹ̀.

Bwala nínú àtẹ̀jáde tó fi sórí ìkànnì X rẹ̀ sọ pé Peter Obi ń wá gbogbo ọ̀nà láti máa ṣe àtakò àmọ́ tó kùnà pẹ̀lú àgbékalẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Ó ní nǹkan ire ni fún Nàìjíríà bí wọn kò ṣe dìbò yan Obi lọ́dún 2023.

Ó sọ pé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí Peter Obi ń sọ ni kìí ṣe òótọ́, tó kàn ń ro gbogbo rẹ̀ lórí àti pé ó ń wá ọ̀nà láti sọ ìdí tó fi fẹ́ ṣe igbákejì ààrẹ níbi ètò ìdìbò ọdún 2027.