Ìbúgbàmù tó wáyé ní Eko gbẹ̀mí èèyàn kan, àwọn mẹ́ta míì farapa

Oríṣun àwòrán, Lagos Police
Kò ní dín èèyàn kan tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ táwọn mẹ́ta mìíràn sì farapa níbi ìbúgbàmù tó wáyé ní agbègbè òpópónà Taiwo Street, Idi- Araba, ìjọba ìbílẹ̀ Mushin, ìpínlẹ̀ Eko.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá Eko, Benjamin Hundeyin tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún BBC News Yorùbá, ṣàlàyé pé àwọn tó máa ń ra irin tí kò dára mọ́ ló ṣokùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àtẹ̀jáde kan tí Hundeyin fi léde ló ti sọ pé nǹkan bíi aago kan àbọ̀ ọ̀sán ọjọ́bọ, ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹrin, ọdún 2025 ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá gba ìpè pé ìbúgbàmù kan wáyé ní agbègbè Idi Araba, Mushin.
Ó ní èyí ló mú kí ikọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìbúgbàmù tètè dìde láti lọ sí agbègbè náà láti mọ nǹkan tó ṣẹlẹ̀.
Ó sọ pé nígbà tí ikọ̀ náà débẹ̀, wọ́n ṣe àrídájú láti ri pé wọ́n dá ààbò tó péye bo agbègbè náà , tí wọ́n sì ṣàwárí okùnfà ìbúgbàmù ọ̀hún.
Hundeyin ní agolo àdó olóró táwọn ológun máa ń lo ni ọ̀kan lára àwọn tó máa ń ra irin àlòkù náà ń gbìyànjú láti túká, tó sì bú gbàmù mọ́-ọn lọ́wọ́.
"Ọkùnrin náà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò tí ìbúgbàmù náà wáyé, táwọn mẹ́ta mìíràn sì farapa."
Ó ní òkú ọkùnrin ọ̀hún ni àwọn ti gbé lọ sí mọ́ṣúárì táwọn mẹ́ta tó farapa náà sì ti wà nílé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ láti ṣàwárí bí agolo àdó olóró ṣe dé ọwọ́ àwọn tó máa ń ṣa ilẹ̀ àti pé àwọn ṣe ti ya àwòrán ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, kò ì tíì sí ẹnikẹ́ni tó mọ òrúkọ àti ibi tí ọkùnrin tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ náà àtàwọn tó farapa náà ti wá.
Àwọn ará àdúgbò tí ìbúgbàmù náà ti wáyé ni wọ́n ń kọminú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, bí wọ́n ṣe ń ṣe kàyééfì lórí bí agolo àdó olóró àwọn ológun náà ṣe dé ọwọ́ ọkùnrin ọ̀hún.















