Wọ́n tú pásítọ̀ ọmọ Nàíjíríà sílẹ́ lẹ́wọ̀n lẹ́yìn ọdún mẹ́jọ torí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ ní South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Wedaeli Chibelushi
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Lẹyin to ti lo ọdun mẹjọ lẹwọn, ajinhinrere ọmọ Naijiria kan to maa n waasu lori amohumaworan, Timothy Omotoso, ti wọn fẹsun ifipaba awọn ọdọbinrin lo pọ kan lorilẹ ede South Africa, ti gba itusilẹ.
Wọn ni ko maa lọ layọ ati alaafia.
Awọn ọmọbinrin ijọ rẹ to wa ni South Africa ni wọn sọ pe Omotoso n fipa ba wọn lo pọ, ti wọn fi mu un.
Ṣugbọn lẹyin ọdun mẹjọ lọgba ẹwọn, wọn ni ko jẹbi ẹsun naa, ko maa lọ sile.
Lati ibẹrẹ pẹpẹ naa ni Pasitọ Omotoso ti loun ko jẹbi ẹsun mejilelọgbọn (32 charges) ti wọn fi kan an.
Lori amohumaworan ni wọn ti ṣeto igbẹjọ ti wọn ti fi ẹsun naa kan an, ti gbogbo eniyan si ri i.
Ni 2018, ẹlẹrii kan sọ fun kootu naa pe pasitọ kan ti fipa ba oun lo pọ ri nigba toun wa ni ọmọ ọdun mẹrinla.
O ni igboro Port Elizabeth ni ṣọọṣi naa wa.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ l'Ọjọruu, Adajọ to gbọ ẹjọ naa sọ pe Omotoso ko jẹbi, o ni awọn oṣiṣẹ to wa nijọ ẹjọ rẹ ni wọn ko yanju ọrọ naa daadaa.
Mo dúpẹ́ f'Ọlọ́run lórí ìdájọ́ yìí - Omotoso
Bakan naa ni ẹka to n ri si fifi ẹsun kan eeyan ni South Africa, National Prosecuting Authority (NPA), sọ pe awọn to kọkọ bẹrẹ igbẹjọ naa ni wọn ko ṣeto rẹ daadaa, wọn ko si beere ibeere to yẹ lọwọ ẹni ti wọn fi ẹsun kan.
Éka NPA sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Omotoso pọ.
Ninu ọrọ rẹ, Omotoso sọ fun awọn oniroyin pe oun dupẹ fun Ọlọrun lori idajọ naa.
Bakan naa ni awọn meji mi-in ti wọn jọ fi ẹsun kan wọn, Lusanda Sulani ati Zikiswa Sitho, gba ominira pẹlu.
Ile ẹjọ sọ pe wọn ko jẹbi.
Ọdun 2017 ni wọn mu Omotoso, bii ẹni n ṣere lo ri nigba ti wọn nawọ gan an lasiko to fẹ kuro lorilẹede naa.
Ẹjọ rẹ ni akọkọ iru rẹ to lagbara ti wọn fi han lori amohumaworan, lorilẹede South Africa ti ẹsun ifipabanilopọ ti pọ gidi.
Ọpọ eeyan lo n da si igbẹjọ naa lasiko to n lọ lọwọ, o si dohun ti wọn n beere ibeere oriṣiiriṣii nipa eto awọn olujẹjọ, aifi ẹjọ ṣegbe ati pe ṣe o yẹ ki wọn maa fi kamẹra si yara igbẹjọ ni kootu.
Bi wọn ṣe pari ẹjọ naa bayii, ẹka iroyin News 24 ni South Africa ti kede pe wọn yoo da Omotoso pada si Naijiria ni.














