Ilé ẹjọ́ ju àlùfáà ìjọ tó fipá bá obìnrin lò pọ̀ sí ẹ̀wọ̀n gbére

Bajinder Singh

Oríṣun àwòrán, Prophet Bajinder Singh Ministries/FB

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ilé ẹjọ́ kan ní orílẹ̀ èdè India ti sọ àlùfáà kan tó máa ń ṣe wàásù lọ́wọ́ ara a rẹ̀, Bajinder Singh sí ẹ̀wọ̀n gbére fẹ̀sùn wí pé ó fi tipátipá bá obìnrin kan lò pọ̀ lọ́dún 2018.

Obìnrin náà fẹ̀sùn kan Singh pé ó fi tipá bá òun lòpọ̀ ní ilé rẹ̀ tó wà ní ẹkùn àríwá Punjab, tó sì tún ká ìbálòpọ̀ náà sórí èyí tó ń lò láti máa fi gba owó lọ́wọ́ òun.

Singh, ẹni tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń tẹ̀lé, di ìlúmọ̀ọ́ká fáwọn iṣẹ́ ìyanu tó máa ń ṣe lórí àwọn aláìsàn nípa fífi ọwọ́ sí èèyàn lórí tí onítọ̀hún yóò sì gbádùn.

Ilé ìjọsìn rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Glory and Wisdom – èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé ìjọsìn aládàni tó tóbi ní Punjab – ní ọ̀pọ̀ àwọn ìlúmọ̀ọ́ká lágbo òṣèré tíátà ní India ń lọ síbẹ̀.

Ilé ìjọsìn náà ní àwọn ní ẹ̀ka káàkiri àgbáyé àti pé àwọn ní ẹ̀ka ní US, UK àti Canada gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà lórí ìtàkùn ayélujára ilé ìjọsìn náà.

Singh tún ní ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó ń tẹ̀le lórí ayélujára, èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta ló wà lórí ìkànnì Youtube ilé ìjọsìn ọ̀hún.

Lọ́pọ̀ ìgbà nínú àwọn ìwáàsù rẹ̀ ló máa ń sọ pé òun le sọ àwọn èèyàn di ọlọ́rọ̀ àti pé kò sí àìsàn tí òun kò le fi iṣẹ́ ìyanu wò.

Ọ̀pọ̀ nínú àwọn fídíò rẹ̀ ló ṣàfihàn bó ṣe ń fọwọ́ sáwọn ọmọ ìjọ lórí, tí wọ́n yóò sì máa gbọ̀n, kí wọ́n tó sọ pé ara àwọn ti dá lọ́wọ́ àìsàn tó ń ṣe àwọn.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ilé ẹjọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí wọ́n sì ní kí Singh lọ máa fi aṣọ péńpé roko ọba fún gbogbo ọdún tó kù tó máa lò láyé.

Agbẹjọ́rò obìnrin náà, Anil Sagar ní ìdájọ́ náà dára tó yóò sì jẹ́ àwòkọ́ṣe ìdájọ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn.

"Tí ilé ẹjọ́ bá filè bá fi ojú àánú wo irú ìdájọ́ àwọn èèkàn ìlú tó ń lo ipò wọn láti fi bá àwọn èèyàn lòpọ̀ ní tipátipá yóò túnbọ̀ máa fún wọn ní agbára láti hùwà ìbàjẹ́."

Agbẹjọ́rò Singh kò ì tíì sọ ohunkóhun lọrí ìdájọ́ náà. Ìrètí wà pé wọ́n máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní ilé ẹjọ́ gíga.

Àwọn obìnrin méjì mìíràn ló tún fẹ̀sùn kan àlùfáà náà pé ó báwọn ní ìbálòpọ̀ lọ́nà àìtọ́. Ní oṣù Kejì, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn náà.

Àmọ́ ó jiyàn àwọn ẹ̀sùn tuntun yìí.

Àwọn ilé ìjọsìn rẹ̀ ni wọ́n tún ń kojú ẹ̀sùn tó nííṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ owó. Ní oṣù Kìíní, ọdún tó kọjá, àjọ tó ń rí sí owó orí ní India ṣe ìwádìí àwọn ilé ìjọsìn náà.

Ta ni Bajinder Singh?

Ìpínlẹ̀ Haryana ní orílẹ̀ èdè India ni wọ́n bí Bajinder Singh.

Ìdílé ẹlẹ́sìn Hindu ni wọ́n bi sí. Ìròyìn ní ó gba ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ ní nǹkan bíi ọdún mẹ́ẹ̀dógún sẹ́yìn nígbà tó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn kan sọ pé ọ̀rọ̀ ìpànìyàn ló gbe dé ẹ̀wọ̀n nígbà náà àmọ́ Singh kò fìgbà kankan sọ̀rọ̀ ní ìta gbangba lórí rẹ̀ rí.

Lórí ìkànnì ayélujára rẹ̀, Singh ní àwọn ẹ̀mí òkùnkùn ti jẹ́ kí òun wu àwọn ìwà ibi sẹ́yìn kí ẹnìkan tó gbé Bíbélì lé òun lọ́wọ, tí òun sì tara bẹ́ẹ̀ mọ Ọlọ́run.

Ó máa ń pe ara rẹ̀ ní òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti pé òun máa ń lo omi àti òróró ṣe ṣe ìwòsàn fáwọn èèyàn.

Nítorí àwọn ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tó wà lọ́rùn rẹ̀, Singh ní àwọn àlùfáà tó jẹ́ alátakò òun ni wọ́n ń gbé àwọn ìròyìn tí kò tọ́ nípa òun.