Mo máa fi àwọn ẹ̀rí ìfìbálòpọ̀lọni sílẹ̀ nípa Akpabio tó bá tó àsìkò - Natasha Akpoti-Uduaghan

Natasha Akpoti-Uduaghan àti Godswill Akpabio

Oríṣun àwòrán, Natasha Akpoti-Uduaghan/Godswill Akpabio/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Sẹ́nétọ̀ Natasha Akpoti-Uduaghan tó ń ṣojú ẹkùn ààrin gbùngbùn ìpínlẹ̀ Kogi nílé aṣòfin àgbà tí wọ́n ní kó lọ rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà tin í òun máa fi àwọn ẹ̀rí tí òun ní tako ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Godswill Akpabio léde láìpẹ́.

Aṣòfin náà sọ̀rọ̀ nígbà tó kópa níbi ètò iléeṣẹ́ Channels Television lọ́jọ́bọ̀ sọ pé òun máa fi àwọn ẹ̀rí náà léde tí àsìkò tó yẹ àti ní ibi tó yẹ.

Ó kan sáárá sí ìgbésẹ̀ àjọ tọ ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC fún bí wọ́n ṣe da ìpè àwọn kan láti pe òun padà kúrò nílé aṣòfin nù.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìgbésẹ̀ náà ló ti yẹ kí wọ́n da ìpè ọ̀hún nù, síbẹ̀ ó ní òun gbóríyìn fún INEC fún ìgbésẹ̀ náà.

"Agbẹjọ́rò ni mí, aṣòfin ni mí, mo sì mọ bí Nàìjíríà ṣe ń ṣiṣẹ́. Ohun tó ṣe pàtàkì sí mi pé ìgbésẹ̀ náà ti dúró."

Èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP sọ pé púpọ̀ nínú àwọn àdírẹ́sì tó wà nínú ìwé ẹ̀sùn náà ló jẹ́ irọ́.

"Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé INEC ka ìbuwọ́lù 208,000, ó dámi lójú pé tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí ní tọpinpin, àwọn tó máa jáde pé àwọn buwọ́lu ìwé ìpèpadà náà kò ní tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500).

Ìgbésẹ̀ láti pe Natasha Akpoti padà láti ilé aṣòfin àgbà kùnà lábẹ́ òfin - INEC

Natasha Akpoti-Uduaghan, Sẹnetọ to n ṣoju Aarin Gbungbun Kogi ki wọn too da a duro

Oríṣun àwòrán, Others

Igbiyanju awọn to n fẹ ki wọn pe Sẹnetọ Natasha Akpoti Uduaghan pada lati maa ṣoju Aarin gbungbun ipinlẹ Kogi lọ ti fori ṣanpọn bayii.

Ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, lo sọ eyi di mimọ loju opi X rẹ l'Ọjọbọ, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin ọdun 2025.

Alaye INEC lori ọrọ naa ni pe igbesẹ yii kuna labala kọkandinlaadọrin (69) ofin orilẹede Naijiria ti wọn gbe kalẹ ni 1999.

Sam Olumekun, Kọmiṣanna ijọba apapọ ati Alaga to n ri si ilanilọye lori eto ibo, lo buwọ lu ikede to ni Natasha ko ṣee pe pada .

Atẹjade naa ka pe: "Iwe ifisun to n pe fun ipadabọ sẹnetọ to n ṣojuu Aarin Gbungbun Kogi, kuna lati ba abala 69, ofin orilẹ ede Naijiria ti wọn ṣe ni 1999 mu."

Kí ló dé tí ìgbésẹ̀ náà kùnà lábẹ́ òfin?

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti wọn n ṣalaye kikun lori idi ti Natasha Akpoti ko ṣe le pada sile igbimọ lati maa ba iṣẹ rẹ lọ, ajọ INEC sọ pe awọn to n gbe igbesẹ naa ko tẹle awọn ilana kan.

Wọn ni iye ibuwọlu to yẹ ki ifisun naa ni ko pe, bẹẹ ni awọn to yẹ ko tẹka ko to pẹlu.

INEC sọ pe awọn nnkan wọnyi ni yoo duro bii aṣoju fun eeyan to le ni idaji awọn oludibo ni Aarin gbungbun Kogi.

" Fun alaye kikun, iwe ifisun lati pe sẹnetọ pada gbọdọ wa ni ibamu pẹlu abala 69 ofin Naijiria ti ọdun 1999.

"Eyi to n beere ibuwọlu idaji iye eeyan to forukọ silẹ lati dibo ni ẹkun naa.

"Apapọ iye awọn ondibo to forukọ silẹ ni Aarin Gbungbun Kogi jẹ 474,554. Iye to ju idaji rẹ lọ jẹ (50%+1), jẹ 237,277+1, eyi to kere tan, to gbọdọ jẹ 237,278 oludibo"

INEC lo ṣe atupalẹ bẹẹ.

Ajọ naa ṣalaye pe onka awọn to forukọsilẹ lati dibo nibẹ jẹ 474,554, to tumọ si pe o kere tan, awọn gbọdọ ri ibuwọlu 237,278.

O ni ṣugbọn 208,132 ibuwọlu pere ni INEC ri. O din 29,146.

" Fun idi eyi, ifisun naa ko lọ ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin Naijiria. Fun idi eyi, ko si igbesẹ kankan ta a maa gbe mọ lori ipepada Sẹnetọ naa."

Bẹẹ ni INEC kede.

Ẹ o ranti pe ọrọ olori ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja, Godswill Akpabio, lo fa wahala, ẹni ti Natasha Akpoti fẹsun kan pe o n fi ifẹ lọ oun lọna aitọ.

Ọrọ naa pada fẹju tantan, ti wọn ni ki aṣofin to n ṣoju Aarin Gbungbun Kogi tẹlẹ naa lọọ sinmi apapandodo fun oṣu mẹfa, ti Natasha si tig be igbesẹ ọlọkan-o-jọkan.