Àwọn olè jí mi gbé, gba gbogbo owó tó wà ní àkáǹtì mi nílé ìtura nígbà tí mo wà lóko eré - Regina Chukwu

Oríṣun àwòrán, Regina Chukwu/Instagram
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Regina Chukwu ti ṣàlàyé àwọn nǹkan tí ó là kọjá lágbo òṣèré.
Regina sọ̀rọ̀ nípa ohun tó là kọjá nígbà tó sun ilé ìtura kan pẹ̀lú òṣèré mìíràn, Akin Lewis nígbà tó parí iṣẹ́ kan.
Nínú fídíò kan tó fi sórí YouTube, òṣèré náà ní àwọn olè yawọ ilé ìtura tí àwọn wà tí wọ́n sì jí òun gbé.
Ó ní wọ́n gbé òun lọ sí ibìkan tí wọ́n sì gba gbogbo owó tó wà ní àkáǹtì òun.
Ó ṣàlàyé pé wọ́n pe òun sí iṣẹ́ kan, tí wọ́n sì sọ fún òun pé ọjọ́ kan ni òun máa lò àmọ́ tí ẹni tó ni iṣẹ́ náà rọ òun láti dúró di ọjọ́ kejì nítorí Akin Lewis máa kúrò ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì àti pé àwọn aṣẹ́wó pọ̀ nílé ìtura náà.
Ó sọ pé Akin Lewis náà bá òun sọ̀rọ̀ láti dúró di ọjọ́ kejì ni òun ṣe gbà láti dúró.
Regina ṣàlàyé pé bí òun ṣe ṣetán láti bọ́ra sílẹ̀ láti pààrọ̀ aṣọ ni òun bẹ̀rẹ̀ sí ní gba ariwo láti ìta àmọ́ tí òun kọ̀ láti jáde.
"Kò pẹ́ tí mo ṣetán láti sùn ni àwọn ajínigbé fi ipá já ilẹ̀kùn, wọ́ mi jáde, tí wọ́n sì gbé mi lọ sí ibìkan tí mi ò mọ̀.
"Wọ́n lo ATM mi láti fi gba gbogbo owó tó wà ní àkáǹtì mi, wan sì fún mi ní ẹgbẹ̀rún kan náírà láti fi wọ ọkọ̀ padà sílé."
Bákan náà ló sọ̀rọ̀ lórí ìrìnàjò bó ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà.
Regina tún sọ nípa àwọn ìlàkàkà tó là kọjá nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ìgbésì ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí opó lẹ́yìn tí ọkọ̀ rẹ̀ kú lẹ́yìn àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́.
Òṣèré náà sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe ń wo ọmọ jòjòló lọ́wọ́, tó sì ń tọ́jú ọkọ rẹ̀ tó ń ṣe àárẹ̀ títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀.
Nǹkan tó sọ yìí ti ń fa awuyewuye láàárín àwọn èèyàn, tí ọ̀pọ̀ wọn sì ń sọ fún àwọn tó ń ṣe eré láti máa ṣe àrídájú ààbò tó péye wà fáwọn òṣèré níbi tí wọ́n bá ti ń ṣeré.
Ta ni Regina Chukwu?

Oríṣun àwòrán, Regina Chukwu/Instagram
Regina Chukwu jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tó bẹ̀rẹ̀ eré lọ́dún 2003 sí 2004 gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ.
Ó ní ìlú Eko ni wọ́n bí òun sí, tí òun sì gbé ní gbogbo ìgbé ayé.
Ọmọ bíbí ìlú Enugu ni wọ́n bi sí àmọ́ agbègbè Iyana Ipaja ní Eko ló gbé.
Ní ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kẹta, ọdún 1980 ni wọ́n bí Regina Chukwu.
Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Alimosho Primary àti Grammar School fún ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama kó tó lọ sí Lagos State Polytechnic àmọ́ tí kò parí níbẹ̀.
Regina ṣe ìgbéyàwó nígbà tó wà ní èwe tó sì ní ọmọ méjì.
Ọdún mẹ́rin tó ṣe ìgbéyàwò ni ọkọ̀ rẹ̀ jáde láyé látàrí àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́.















