Ṣé lóòótọ́ ni CBN fẹ́ tẹ owó bébà ₦5,000 ati ₦10,000 tuntun jáde?

Oríṣun àwòrán, CBN
Banki apapọ Naijiria, CBN, ti kede pe irọ ni iroyin to n lọ ni igboro pe oun fẹ tẹ owo ₦5,000 ati ₦10,000 tuntun.
O ni ki araalu maṣe naani irufẹ iroyin bẹẹ lasiko yii.
Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ n gba igboro pe CBN fẹ tẹ owo naira tuntun lọna ati mu ki karakata rọrun faraalu.
Ninu awọn iroyin naa ti CBN ni kii ṣe ootọ sọ pe igbesẹ ọhun waye ki iye beba owo ti araalu yoo maa gbe kiri le dinku.
Awọn iroyin miran tilẹ ni igbakeji gomina banki naa, Ọmọwe Ibrahim Tahir , lo wa nidi titẹ owo tuntun ọhun.
Gẹgẹ bi iroyin naa ṣe sọ, ọjọ kinni, oṣu Karun un, ọdun 2025 yii ni CBN yoo ko owo naa jade.

Oríṣun àwòrán, SR
Ko si ohun to jọ bẹẹ - CBN
Bi awọn kan ṣe n sọ pe ootọ maa n wa ninu iroyin ti ijọba ba pe ni irọ, lawọn mii n sọ pe ijọba gbọdọ pe gbogbo awọn to n pin iroyin ofege naa kiri lẹjọ
Ẹwẹ, ninu atẹjade kan loju opo X rẹ, CBN ti sọ pe oun ko tẹ owo naira tuntun ati pe ofege ni iroyin naa.
CBN ni "Atẹjade yii kii ṣe lati ọdọ banki apapọ Naijiria. A fẹ ki ẹ mọ pe oju opo kan ṣoṣo ti awọn alaṣẹ wa fọwọ si ni cbn.gov.ng."
Ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori atẹjade CBN ati iroyin nipa owo tuntun naa.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe ootọ maa n wa ninu iroyin ti ijọba ba pe ni irọ, lawọn mii n sọ pe ijọba gbọdọ pe gbogbo awọn to n pin iroyin ofege naa kiri lẹjọ.















