Ǹjẹ́ ó tọ́ fún àgbàlagbà láti máa mu omi ọyàn èyí tí ọ̀pọ̀ ń pè ní wúrà inú ìgò?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Sofia Bettiza
- Role, Global Health Reporter, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Awọn kan n pe e ni wura inu igo, bẹẹ lawọn onimọ kan n sọ pe o ni agbara.
Imọ ijinlẹ sayẹnsi ti fi han pe omi ọmu ṣe pataki fun idagbasoke awọn ọmọde amọ awọn agbalagba kan ti n mu u bayii latari anfani inu rẹ.
Ẹni ọdun mọkandinlogoji ni Jameson Ritenour, o ti si bi ọmọ mẹta.
Jameson mu omi ọmu gẹgẹ bii agbalagba fun igba akọkọ lasiko ti ololufẹ rẹ n fun ọmọ lọmu.
O sọ fun BBC pe "Mo fi sinu ẹlẹrindodo mi, mo si mu bo tilẹ jẹ pe ololufẹ mi ri bii ohun ajoji."
Ifẹ Jameson si ati maa mu omi ọmu lẹyin to wo fidio kan lori YouTube, nibi ti ọkunrin alagbara kan ti sọrọ lori anfani to wa ninu rẹ.
Jameson ni "Ọkunrin lagbara, o si ni iṣan lara."

Oríṣun àwòrán, Jameson Ritenour
Lẹyin naa ni Jameson bẹrẹ si n mu omi ọmu ololufẹ rẹ lojojumọ.
Nnkan bii ife meji lo n mu lojumọ.
Lẹyin to bẹrẹ si n ṣe eyii lo ni ara oun mokun ju ti atijọ lọ.
O ni "O ranmi lọwọ lati le lagbara si, o tun jẹ ki iṣan mi maa jade sita si.
"Bi mo ṣe n mu omi ọmu ti mo si n ṣere idaraya ni ọra ara mi n dinku ti awọn iṣan mi si n pọ si."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ko ṣe aisan kankan bẹẹ ni otutu ko lagbara lori rẹ lasiko to n mu omi ọmu naa.
Jameson sọ pe "Mo fẹ maa dagba bii ọmọde, bẹẹ ni mo si fẹ maa sun bii ọmọde lo jẹ ki n maa jẹ ounjẹ ọmọde."
"O lewu lati ra omi ọmu lori ayelujara"
Awọn onimọ sayẹnsi ti sọ pe ko si ẹri kankan to fi han pe omi ọmu n ṣe anfani kankan fun ara agbalagba.
Amọ ṣa, awọn kan ti sọ pe o ni awọn anfani diẹdiẹ to le ṣe fun eeyan.
Ọmọwe Lars Bode, ni fasiti California, to w ani San Diego lorilẹde Amẹrika sọ pe ọpọ eroja 'protein' lo wa ninu omi ọmu to n jẹ ki ọmọ dagba, eroja naa si lawọn to n gbe irin ki iṣan ara wọn le jade n wa kiri.
Bode wa kilọ fun awọn to n gbe irin ti wọn si n wa eroja protein kiri lati ṣọra fun rira rẹ lori ayelujara lawọn ọja bii Facebook, Craigslist ati Reddit.
O ni rira omi ọmu lori awọn ikanni naa lewu nitori ko si ẹni to ṣe ayẹwo rẹ, awọn eeyan si le ko awọn aisan bii HIV tabi hepatitis lati ibẹ.
Onimọ naa tẹsiwaju pe bi ilera ẹni to ni omi ọmu ṣe ri naa ni ilera omi ọhun yoo ṣe ri pẹlu.
O ṣalaye pe niwọn igba ti pupọ obinrin kii ṣe imọtoto omi ọmu wọn, o ṣeeṣe ki kokoro aifojuri wọ inu omi ọmu naa.

Oríṣun àwòrán, Jameson Ritenour
Lẹyin ti ipinya de ba Jameson ati ololufẹ rẹ, Melissa, ko ri omu ọmu ọfẹ mu mọ, o si bẹrẹ si n ra omi ọmu naa lori ayelujara.
O ni oun ko mọ boya ewu kankan wa ninu rira rẹ lori ayelujara ati pe boya kororo aifojuri le wọ inu rẹ.
Ọkunrin naa ṣalaye pe "Ọdọ ẹnikan ti mi o mọ ri ni mo ti ra a lori ayelujara amọ mo kọkọ ṣe iwadii ẹni naa loju opo Facebook… lẹyin naa ni mo ra a."
Jameson ni awọn ohun ti awọn onimọ sayẹnsi n sọ nipa rẹ ko kan oun, nitori omi ọmu naa ṣiṣẹ fun oun daadaa.
Nipa irufẹ oju ti awọn eeyan fi n wo iwa bẹẹ Jameson sọ pe ko kan oun.
O ni "Ọpọ eeyan lo n woye pe ọmọde nikan ni omi ọmu wa fun, ti wọn si n fi oju ara meeriri wo mi amọ ko tu irun kankan lara mi."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ọmọ to nilo omi ọmu?
Oluwadii nipa omi ọmu, Meghan Azad, sọ pe oun ko le gba awọn agbalagba nimọran lati maa mu omi ọmu lailai.
O ni "Mi o lero pe o maa ṣe ipalara kankan fun awọn agbalagba naa amọ o lewu fun awọn ọmọ kekere to nilo rẹ julọ bii awọn ọmọ ti wọn ko tii gbo ti wọn ko si ni anfani si omi ọmu.
O ni awọn ọmọde to nilo omi ọmu lo yẹ ki awọn eeyan maa da omi ọmu jọ fun, kii ṣe awọn agbalagba ti ko nilo rẹ.
Ẹwẹ, Jameson so pẹ oun gbagbọ pe oun n ṣe ohun ti ko daa nipa mimu omi ọmi, o sọ pe nnkan bii ọgọrun obinrin lo ti kan si oun lati ta omi ọmu fun oun.
Awọn anfani inu omi ọmu
Ọpọ iwadii lo yẹ ko waye lori omi ọmu amọ ti awọn oluwadii ko tii bẹrẹ iṣẹ lori rẹ.
Azad ni "Fun igba pipẹ ni awọn eeyan to n ṣe iwadi ti kọ lati naani iwadii nipa omi ọmu latari pe wọn ri bii ọrọ awọn obinrin ti ko ṣe pataki."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, iha ti wọn kọ si ọrọ naa ti n yipada bayii.
Yato si mimu rẹ fun awọn agbalagba, awọn onimọ ijinlẹ ti n wadii awọn anfani to le ṣe fun awọn agbalagba.
Lara awọn nnkan ti wọn n gbiyanju lati mọ boya omi ọmu le gbọ ni aisan aromọleegun, aisan ọkan, aisan jẹjẹrẹ ati inu rerun.















