Ilé-ẹjọ́ fagile ẹjọ̀ tó tako ìjáwé-olúborí Gómìnà Okpebholo l'Edo

Gomina ipinlẹ Edo, Monday Ighodalo ati alatako rẹ; Asue Ighodalo ti ẹgbẹ oṣelu PDP.

Oríṣun àwòrán, Monday Okpebholo/ Facebook/ BBC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gomina ipinlẹ Edo, Monday Okpebholo, ti yege bayii lori awọn ẹjọ to n tako iyansipo rẹ sipo gomina ipinlẹ naa, pẹlu bi ile ẹjọ ṣe fagile awọn ẹjọ to tako o.

Nibi igbẹjọ akọkọ to waye l'Ọjọruu, ọjọ keji, oṣu kẹrin ọdun 2025, ni kootu ti da ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu Action Alliance (AA) pe tako Okpebholo, nu.

Bakan naa ni wọn fagile ẹjọ ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Adekunle Rufai Omoaje, ti ẹgbẹ oṣelu AA, pe tako aṣeyọri Gomina Okpebholo.

Adajọ sọ pe Omoaje ko ni agbara lati pe ẹjọ yii.

Kootu sọ pe idi ni pe ẹjọ to pe ko ni nnkan kan lati ṣe pẹlu ọrọ oṣelu rara.

Bakan naa ni kootu fidi ẹ mulẹ, pe ẹjọ wọnyi ko lẹsẹ nilẹ, o si ku fun awuruju .

Wọn tun sọ pe Omoaje ko kopa ninu idibo naa, fun idi eyi, ko ni idi kankan lati tako aṣeyọri Okpebholo

Awọn ẹsun wo ni Omoaje fi kan Okpebholo?

Ṣaaju ni Omoaje ti rọ tribuna to n gbọ ẹjọ naa pe ki wọn fagile ijawe olubori Gomina Monday Okpebholo.

Ninu iwe to kọ lo ti ni ibo to gbe gomina naa wọle ko ba ofin mu.

Omoaje sọ pe magomago pọ ninu ibo naa.

Ati pe wọn ko tẹle ofin idibo ti INEC la kalẹ.

Bakan naa lo ni Okpebolo ko ni to iye ibo ti INEC kede pe o ni.

Ẹsun mi-in ti ondije ipo gomina l'Edo naa tun ka silẹ ni pe wọn ko jẹ ki ẹgbẹ oṣelu AA fa ondije kalẹ, nitori Awọn ko buwọ lu iwe ti wọn fi fa ondije kalẹ.

Monday Okpebholo, ti ẹgbẹ oṣelu APC ni ajọ INEC kede gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu idibo ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an ọdun 2024.

Ibo 291,667 ni INEC kede pe Okpebholo ni, to fi fidi alatako rẹ, Asue Ighodalo, ti ẹgbẹ oṣelu PDP janlẹ.

Ibo 247,655 ni Ighodalo ni ni tiẹ.