Láì náání ìkéde kóníléógbélé, tìlù-tìfọn láwọn aráàlú Natasha Akpoti fi kí i káàbọ̀, ó ní ilé baba ọmọ, kìí ba ọmọ lẹ́rùn

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Natasha Akpoti-Uduaghan, Aṣofin to n ṣoju aringbungbun ipinlẹ Kogi ti wọn da duro l'Abuja, balẹ si ipinlẹ Kogi pẹlu baalu ẹlikopita.
Pẹlu orin ati ilu lawọn ololufẹ Natasha fi pade rẹ lasiko to balẹ sipinlẹ naa lọjọ Iṣẹgun.
Ayẹyẹ ipadabọ naa lo waye bo tilẹ jẹ pẹ ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe ki wọn wọgile latari eto abo to ṣeeṣe ko mẹhẹ ni gbagede eto naa.
Yatọ si ikilọ ọlọpaa, ijoba ipinlẹ ọhun tun ti paṣẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ korajọ, o tun kede konileogble ni wakati diẹ si asiko ti Natasha yoo wọ ilu.
Fidio ti awọn oluranlọwọ sẹnetọ naa fi lede lori ayelujara ṣafihan bi awọn ololufẹ rẹ ṣe n jo, ti wọn si n yọ pẹlu oniruru orin ati ilu.
Awọn ololufẹ re ọhun tun gbe oniruru akọle lọwọ ti wọn kọ nnkan bii "Kaabọ ojulowo ọmọ ilẹ Ebira, awọn eeyan Okene wa lẹyin rẹ digbi, "Kaabọ Natasha, awọn eeyan Adavi duro ti ọ," atawọn akọle mii si lara.
Nigba to n ba awọn eeyan naa sọro, Natasha sọ pe inu oun dun lati pada wale, ati pe ko si ẹnikẹni to le sọ pe ki oun ma ṣe bẹẹ nitori ile baba ọmọ kii ba ọmọ lẹru.
O ni "Ko si ẹni to le ni ki n ma pada wale, ọmọ Ebira ni mi, ilẹ mi ree, mi o ki n ṣe ọmọ ale, mi o bẹru ẹnikẹni, emi ni ọmọ ọmọwe Jimoh Akpoti."

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ohun ti Natasha sọ nipa ipada wale rẹ
Natasha sọ fun awọn eeyan rẹ pe ohun ti oun woye ni bi ajọ eleto idibo, INEC, yoo ṣe ran awọn to n gba ọna eburu lati yọ oun nipo aṣofin lọwọ.
O ni "Nigba ti wọn kọkọ kọ iwe lọ si ọdọ INEC pe awọn ko fẹ mi mọ nipo aṣofin, wọn ko fi nọmba ojule wọn sibẹ, to fi mọ ẹrọ ilewọ wọn ati bi INEC ṣe le kan si wọn.
"INEC funra rẹ lo ṣẹsẹ tun n ṣalaye ohun to yẹ ki wọn ṣe ati bi wọn yoo ṣe ṣe e."
Aṣofin naa fi kun pe ko si akọsilẹ pe wọn fi orukọ ojule to wa lori lẹta wọn silẹ lọdọ ijoba, bẹẹ INEC ko si ṣe nnkankan nipa rẹ.
Lori ẹsun to fi kan olori ile aṣofin, Godswill Akpabio, Natasha sọ pe oun sọrọ soke lẹyin ti oun gbe ọrọ naa yẹwo daadaa.
O ni nnkan ti oun la kọja jẹ ohun kan naa ti ọpọ obinrin n la kọja nile ẹkọ atawọn ileeṣẹ kaakiri nibi ti ọga wọn yoo ti maa fi ibalopọ lọ wọn.
Natasha sọ pe "Mo ti sọrọ soke nipa iya to n jẹ awọn obinrin ni ikọkọ, inu mi si dun lati ṣe bẹẹ nitori ni bayii, yoo rọrun fun obinrin mii lati sọrọ soke.
"Mo si gbagbọ pe to ba ya, ofin yoo wa, eyii ti yoo daabo bo ẹtọ awọn obinrin yala wọn ti wa nile ọkọ ni tabi bẹẹ kọ.















