Wo àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe tó o bá n gbé lágbègbè tí omíyalé ti le wáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni Ọjọbọ , ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin ọdun 2025 ni ijọba Naijiria kede pe, ojo nla nla yoo rọ, ti omiyale yoo si ṣẹlẹ ni ipinlẹ ọgbọn, to fi mọ ilu Abuja, lọdun 2025.
Ikede yii lo jade lati ẹnu Minisita fun awọn nnkan alumọni inu omi ati imọtoto, Joseph Utsev.
Awọn ipinlẹ naa ni: Eko, Ogun, Abia, Ondo, Adamawa, Akwa Ibom, Anambra, Bauchi, Bayelsa, Benue, Borno, Cross-River, Delta, Ebonyi, Edo, Gombe, Imo, Jigawa, Kebbi, Kogi, Kwara, Nasarawa, Niger, Osun, Oyo, Rivers, Sokoto, Taraba, Yobe, Zamfara ati ilu Abuja.
BBC ṣe akojọ awọn nnkan ti yoo ran ọpọ lọwọ lati ma jẹ ki omiyale ba dukia wọn jẹ tabi gba ẹmi wọn.
Iṣẹlẹ omiyale le waye ni pajawiri, ti a si ti ri ọpọ to ti sẹlẹ ni ayika wa ṣugbọn o ṣe koko ki awọn eeyan to n gbe ni agbegbe ti omiyale ti wọpọ mura, ki wọn si ma gbe igbesẹ ti yoo doola ẹmi awọn ati idile wọn saaju ki omiyale to waye.
Ki ni awọn nnkan to ni lati ṣe saaju omiyale?
Ti o ba n gbe ni agbegbe ti omiyale ba ti wọpọ, o ṣe koko ko gbaradi fun omiyale.
Ohun akọkọ to ṣe pataki ni ki o kuro ni agbegbe naa ti o ba ti kẹfin pe omiyale yoo ṣẹlẹ ṣugbọn ti ko ba si aaye, wa aṣọ nla to le pese aabo fun ẹ lasiko omiyale silẹ.
Wa apo nla silẹ ti o le ko awọn nnkan ti o nilo lasiko omiyale bi;
Omi to mọ, asọ, ounjẹ, oogun ati awọn nnkan mii to ṣe pataki.
Bakan naa lo tun ṣe koko ko mọ agbegbe rẹ daadaa , ko si mọ ibi ti aabo yoo wa fun ẹ lasiko ti iṣẹlẹ omiyale ba waye.
Nnkan to yẹ ko ṣe lasiko omiyale
Gẹgẹ bi a ti ṣe sọ saaju, ṣadeede ni iṣẹlẹ yii ma n waye ṣugbọn bi eeyan ba ti gbaradi, o ṣeeṣe ki eeyan doola ẹmi ati dukia.
Lasiko yii, igbiyanju ki o ma saare lati ma ko ẹru kankan kọ ni igbesẹ akọkọ.
Ẹmi rẹ ṣe koko lasiko omiyale, ma fi ọwọ kan nnkan ti o le ṣe ijamba miiran fun ẹ.
To ba rọrun fun ẹ, ran awọn yooku lọwọ
Oyo, Ogun, Osun, Eko, àti àwọn ìpínlẹ̀ 26 míì tí omíyalé yóò ti ṣẹlẹ̀ ní 2025

Ijọba Naijiria ti sọ pe, ojo nlanla yoo rọ, omiyale yoo si ṣẹlẹ ni ipinlẹ ọgbọn, to fi mọ ilu Abuja, lọdun 2025.
Minisita fun awọn nnkan alumọni inu omi ati imọtoto, Joseph Utsev, lo fi iroyin naa sita l'Ọjọbọ.
Eyi waye nibi eto iwoye bi omiyale yoo ṣe ri lọdun 2025, ti ajọ Nigeria Hydrological Services Agency (NIHSA) ṣe niluu Abuja.
Awọn ipinlẹ naa ni: Eko, Ogun, Abia, Ondo, Adamawa, Akwa Ibom, Anambra, Bauchi, Bayelsa, Benue, Borno, Cross-River, Delta, Ebonyi, Edo, Gombe, Imo, Jigawa, Kebbi, Kogi, Kwara, Nasarawa, Niger, Osun, Oyo, Rivers, Sokoto, Taraba, Yobe, Zamfara ati ilu Abuja.
Utsev sọ pe awọn ipinlẹ to wa ni ẹkun idibo Gusu-Gusu, yoo koju iṣẹlẹ ẹkun omi, nitori bi òkun yoo se kún fun omi.
Awọn ipinlẹ ti ọrọ kan ni Bayelsa, Cross River, Delta, ati Rivers. Ni ti ipinlẹ Akwa-Ibom ati Edo, ẹkun omi to lagbara lo ṣe e ṣe ko waye nibẹ.
Gẹgẹ bi minisita naa ṣe sọ, omiyale jẹ ọkan pataki lara awọn ajalu to ma n waye ni Naijiria, ti ayipada oju ọjọ si n ṣokunfa bo ṣe n waye leralera, ati bo ṣe n lagbara si.
O ṣalaye pe, ilu to le ni ẹgbẹfa, 1,249, ni ijọba ibilẹ 176 to wa ni ọgbọn ipinlẹ, ati ilu Abuja, lo wa ninu ewu omiyale lọdun yii.
O fi kun ọrọ rẹ pe, ilu 2,187 to wa ni ipinlẹ 293 yoo koju omiyale diẹ.
Awọn ipinlẹ ti ọrọ kan ni Abia, Benue, Lagos, Bayelsa, Rivers,Jigawa, ati awọn mii.
Ijọba ni, oun fi ikede naa sita, ki gbogbo awọn agbegbe ti ọrọ kan, le gbaradi, ki wọn o si ṣe amojuto to yẹ.
Ninu ọrọ ti ẹ, Akọwe Agba nileesẹ fun alumọni inu omi, Richard Pheelangwah, rọ awọn alamojuto, lati gbájúmọ́ idoola pajawiri.
"Iwoye yii ṣe nipa onka nikan, ṣugbọn o nii ṣe pẹlu aabo ẹmi ati ọrọ aje awọn eeyan.
Omiyale ba nnkan jẹ lọdun 2024 ni Maiduguri
Lọdun 2024, ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA kede pe eeyan mẹtadinlogoji to ti padanu ẹmi wọn lasiko ẹkun omi to waye ni daamu kan to fa omiyale nipinlẹ Borno.
NEMA tun ṣalape pe o le ni eeyan 400,000 to padanu ile wọn lasiko ajalu naa.
Ẹkun omi daamu Alau lo ṣokunfa iṣẹlẹ omiyale naa.
Bakan naa, nipinlẹ Ondo ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2024, ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye, ninu eyi ti awọn ọkọ ati ile wa, ni wọn bajẹ leyin ojo arọrọda kan to rọ lọjọ kẹrin, ni ijọba ibilẹ iwọ-orun Ondo nipinlẹ Ondo.
Ojo naa bẹrẹ ni ago mẹta ọsan, ti o si ṣe kẹrẹkẹrẹ bẹrẹ si ni i ṣarajọ debi pe gbogbo oju odo, oju agbara ati oju popo bẹrẹ si ni i kun.
Awọn agbegbe ti iṣẹlẹ naa kan lawọn agbegbe bii Opopna Ita-Nla, Oke Odunwo, Oke-Idera, Iluyemi, Oluwabamikole, Odojomu, Bethlehem, Gani Fawehinmi, Iranlowo, Ife garage, St. Andrews ati Ife Road.












