Ohun tá a mọ̀ nípa òrìṣà Agemo tí wọ́n ló pa eni tó fẹ́ẹ́ jí i gbé n'Ijebu-Ode

Aworan oriṣa

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lọjọ Abamẹta, ọjọ kejila oṣu Kẹrin ọdun 2025 yii ni iroyin jade, pe ọkunrin kan pade iku ojiji, nibi to ti n gbiyanju lati ji oriṣa Agemo gbe n'Ijebu-Ode, ipinlẹ Ogun.

Olobiripo Itoro, n'Ijebu-Ode ni oriṣa Agemo yii ti wa lati nnkan bii ọdun mọkanlelogun ti wọn ti fidi rẹ sọlẹ sibẹ.

Ṣugbọn lọjọ Abamẹta, awọn ara adugbo naa ri i pe ẹnikan ti fi ọwọ kan oriṣa alawọ wura naa, ko duro nibi to wa mọ, bẹẹ ni wọn ni awọn ba oku ọkunrin kan lẹgbẹẹ rẹ

Ko pẹ sigba naa ti fidio iṣẹlẹ yii fi gba ori ayelujara kan.

Fidio naa ṣafihan ọkunrin kan to wọ ẹwu alawọ aro, to dubulẹ gbalaja si ẹgbẹ oriṣa naa.

Gẹgẹ bi awọn to tu ara ọkunrin naa wo ṣe wi, wọn ni kaadi idanimọ ti wọn kọ Jeremiah Kosesochi Nwoke si ni awọn ba lara rẹ.

Igbagbọ awọn eeyan agbegbe naa lori iṣẹlẹ yii ni pe ọkunrin naa tapa si alalẹ, o gbiyanju lati ji oriṣa gbe, o si ba onile nile lo fi dero ọrun.

A ti mú afurasí tọ́wọ́ bà pamọ́ -Ọlọ́pàá Ogun

CSP Omolola Odutola, Alukoro ọlọpaa Ogun

Oríṣun àwòrán, CSP Omolola Odutola/Facebook

Lọjọ keji iṣẹlẹ naa ti i ṣe ọjọ Aiku ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi atẹjade sita lori oriṣa Agemọ to di iroyin n'Ijebu-Ode naa.

Lodi si iroyin to ni ẹnikan ku nibi to ti fẹẹ ji oriṣa naa, Alukoro ọlọpaa Ogun, CSP Omolola Odutola, sọ pe awọn ti mu afurasi kan si ahamọ lori iṣẹlẹ naa.

Atẹjade ọlọpaa ṣalaye pe:

''Iroyin sọ pe wọn ba ere Agemo to wa ni Olobiripo Itoro, n'Ijebu Ode jẹ lọjọ kejila, oṣu Kẹrin ọdun 2025.

Agbalagba ọkunrin kan, Jeremiah Nwoke, huwa ẹgbin si oriṣa Agemo tawọn eeyan bọwọ fun nipa yiyọ ade ori rẹ kuro. A ti gba ade naa pada, o si ti wa nibi aabo ni teṣan Obalende.

''Awọn ọlọpaa tete de ibi iṣẹlẹ naa, wọn si pana rogbodiyan to ṣee ṣe ko waye lati ọwọ awọn oniṣẹṣe.

A ti n ṣe ayẹwo afurasi tọwọ ba naa, nitori o jọ pe ilera ọpọló rẹ ko pe.''

Odutola sọ pe ko si rogbodiyan n'Ijebu-Ode nitori iṣẹlẹ yii, o ni aabo to peye wa fun awọn olugbe ibẹ.

Bẹẹ ni iwadii n tẹsiwaju.