Ọgọ́rùn-ún èèyàn pàdánù ẹ̀mí níbùdó ààbò

Aworan eruku to gba oju ọrun kan latari ado oloro

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko din ni ọgọrun-un eeyan, titi kan awọn ọmọde ati awọn oṣiṣe eto aabo ti wọn padanu ẹmi lọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin 2025, nibudo ti wọn sa si fun aabo lorilẹ-ede Sudan.

Ajọ UN fidi eyi yii mulẹ, pẹlu alaye pe ikọlu to pa awọn eeyan naa n ṣẹlẹ leralera nibudo aabo ti wọn sa si, lẹyin ti ebi ati ìyàn le wọn kuro nilee wọn.

Gẹgẹ bi UN ṣe wi, ẹkun Iwọ-Oorun Sudan, Darfur ni iṣẹlẹ naa ti bẹrẹ.

Ilu el Fasher ati awọn ibudo aabo meji mi-in ti awọn ogun-le-mi-de naa sa si ni ikọlu ọhun ti ba wọn.

Nipa awọn to wa nidii ikọlu yii, ẹka ologun RSF ti i ṣe Rapid Support Forces ni wọn pe e.

Ibudo aabo ti wọn kọlu la mọ si Zamzam ati Abu Shouk.

O le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin eeyan (700,000) ti wọn n fori pamọ sibẹ fun aabo, latigba ti ogun ati ìyàn ti le wọn nile.

"A ti pàdánù ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́, ìkọlù yìí le púpọ̀"

Aworan baba agbalagba to kun fun ibanujẹ pẹlu kẹtẹkẹtẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, AFP

Nigba to n ba BBC sọrọ laaarọ ọjọ Aiku, Mustafa, ọkan ninu awọn olugbe Zamzam to n ṣiṣẹ nile idana ti wọn ti n gbọ ounjẹ fun awọn alaini naa, sọ pe:

"Adanu nla ni ".

"A ti padanu ọpọlọpọ ọdọ, wọn ti pa awọn to n ṣiṣẹ nile idana agbegbe, ati awọn dokita to n gbiyanju bi wọn yoo ṣe ṣi awọn ileewosan pada, wọn ti pa gbogbo wọn.

"Wọn ti pa awọn ibatan mi. Awọn eeyan to tun farapa pọ, ko si si oogun tabi ileewosan to le gba wọn, wọn n ku latara ẹjẹ ti wọn n padanu ni.

"Wọn o ti i dawọ duro, a ṣi n reti ikọlu ti wọn yoo tun kọlu wa lọwọ aarọ."

Mustafa fi kun un pe gbogbo ọna to wọ ibudo aabo yii ni wọn ti di pa pata, bẹe ni wọn yi igun mẹrẹẹrin rẹ po.

Oludari to n ri si ọrọ ọmọniyan ni Sudan, Clementine Nkweta-Salami, to n ṣoju ajọ UN, sọ pe ijọniloju gbaa lo jẹ, pe iru ikọlu to n da oju sọ ileewosan ati ibi aabo bayii waye.

Mẹsan-an ninu awọn oṣiṣẹ alaabo, titi kan awọn dokita , dẹrẹba ati olori ikọ kan ni wọn ba ikọlu Zamzam lọ, gẹgẹ bi 'Aid organisation Relief International'' ṣe ṣalaye.

Kí ló fa ogun?

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin ọdun 2023 ni ogun yii bẹrẹ, lẹyin ti awọn olori ogun ati awọn ikọ RSF kuna lati fi ẹnu ko lori ọjọ iwaju Sudan.

Ni bayii, o ti le ni miliọnu mejila eeyan ti wọn ti di alainile lori latari ogun, ebi ati iyan to le wọn nilee wọn.

El-Fasher ti ikọlu tun kan yii ni ilu to gbẹyin ninu awọn ilu nla to wa labẹ iṣakoso ologun, o si ti wa labẹ ikọlu wọn fun bii ọdun kan bayii.