Christian Chukwu, akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles tẹ́lẹ̀, jáde láyé

Oloogbe Christian Chukwu, akọnimọọgba Super Eagles tẹlẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Christian Chukwu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹni to ti figba kan jẹ akọnimọọgba fun ikọ agbabọọlu Super Eagles ilẹ Naijiria, Christian Chukwu Okoro, ti jade laye.

Gbajumọ agbabọọlu tẹlẹ ni Naijiria, Segun Odegbami, kede ipapoda Christian Chukwu lonii, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin ọdun 2025.

Gẹgẹ bi Odegbami ṣe fi iroyin naa lede loju opo X rẹ, o ni owurọ ọjọ naa ni Chukwu jade laye.

Bo tilẹ jẹ pe Odegbami ko sọ pato ohun to fa iku naa, o fidi rẹ mulẹ, pe Chrisian Chukwu, ẹni to pe ni ọrẹ imulẹ rẹ ti jade laye.

Iroyin sọ pe ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin (74) ni Oloogbe Christian Chukwu ko too papoda.

Ṣaaju asiko yii ni iroyin iku akọnimọọgba tẹlẹ naa ti kọkọ jade.

Ni 2021 ni iroyin kan gbode, pe Christian Chukwu ti ku.

Nigba to n tako iroyin naa lasiko ọjọọbi aadọrin ọdun rẹ, iyẹn lọjọ kẹrin, oṣu Kin-in-ni ọdun 2021, Chukwu sọ pe iroyin naa ba oun loju jẹ gidi.

O loun ṣi n wadii awọn eeyan to wa nidii ibajẹ, ti wọn n kede iku oun lai ti i ku.

Ta a ni Olóógbé Christian Chukwu?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

'Chairman', ni ọpọ eeyan mọ Oloogbe Christian Chukwu si lagboole ere bọọlu alafẹsẹgba lorilẹede Naijiria.

Ọjọ kẹrin, oṣu Kin-in-ni ọdun 1951 ni wọn bi i.

O ti kopa pataki gẹgẹ bii agbabọọlu ri, ṣaaju ko too di akọnimọọgba fun Super Eagles.

Ipo awọn to n maa n da aabo bo ile (Defender) ni Oloogbe Christian Chukwu maa n dimu nigba to n gba bọọlu fun Naijiria.

Christian Chukwu lo ṣaaju ikọ agbabọọlu Naijiria ti wọn fi kọkọ gbà ifẹ ẹyẹ ilẹ Africa ta a mọ si Africa Cup of Nations

Oun ni akọnimọọgba ikọ naa laaarin 2003 si 2006.

Ṣaaju lo ti ṣe akọnimọọgba ikọ Green Eagles laaarin 1974 si 1980.

Ni 2019, ojojo ṣe Chukwu, ajọ Nigeria Football Federation, kede pe awọn yoo ran an lọwọ lati sanwo itọju rẹ lorilẹede America.

Bakan naa ni baba olowo, Femi Otedola, loun yoo ran an lọwọ pẹlu.

Wọn pada kede pe yoo lọọ gba itọju naa loṣu karun-un, lẹyin ti owo ti wọn nilo ti pe.

Oloogbe Christian Chukwu gba itọju nigba naa o si gbadun.

Ṣugbọn ọlọjọ de laaarọ ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, 2025.