NERC ni kí iléeṣẹ́ amúnáwá mẹ́jọ san 628m nítorí iye tí wọ́n gbà lọ́wọ́ oníbàárà

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n mojuto ina mọnamọna lorilẹede Naijiria, NERC ti fi kele ofin gbe ileeṣẹ to n pin ina mọnamọna mẹjọ fun bi wọn ṣe tapa si ofin owo ina onibiili.

Awọn ileeṣẹ yii ni NERC sọ pe wọn kọ lati tẹle ofin, ti wọn si fowo kun iye owo to yẹ ki awọn onibaara wọn ti ko lo mita o maa san loṣooṣu.

Awọn ileeṣẹ mọnamọna naa Abuja Electricity Distribution Company, Ikeja Electric Distribution Company, Eko Electricity Distribution Company, Enugu Electricity Distribution Company, Jos Electricity Distribution Company, Kaduna Electric, Kano Electricity Distribution Company, ati Yola Electricity Distribution Company.

Awọn ileeṣẹ yii ni wọn fẹsun kan pe wọn fowo kun owo ina awọn onibaara wọn ti ko lo mita laarin oṣu keje si oṣu kẹsan an ọdun 2024.

Eyi lo wa ninu atẹjade kan ti ajo naa fi lede loju opo ayelujara rẹ, ti wọn si kede pe ki awọn ileeṣẹ yii san owo toto N628m owo itanran.

Yatọ si owo itanran yii, NERC tun palaṣẹ fun awọn ileeṣẹ yii pe, ki wọn da owo pada fun awọn onibaara ti ọrọ kan titi ọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun un, ọdun 2025.

"Gẹgẹ bi o ṣe wa ninu iwe ofin ti ọdun 2023, ajọ NERC kede fifofin de ileeṣẹ to n pese ina mọnamọna mẹjọ- Abuja, Eko, Ikeja, Jos, Kaduna, Kano ati Yobe fun bi wọn ṣe tapa sofin.

"Fun bi wọn se tapa si ofin naa, awọn onibaara awọn ileeṣẹ ni wọn san ju iye owo to yẹ ki wọn san loṣu.

"Iwadii fihan pe awọn ileeṣẹ yii tapa si ofin gbigba owo ti ko tọ lọwọ onibaara wọn."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post