Kà nípa oríṣi àìsàn jẹjẹrẹ méje tí ọtí mímu lè fún ọ

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ọti m'ọrọ gunlẹ, agbo ọlọti kiki faaji.
Ṣugbọn ṣe o mọ pe awọn nnkan kan wa ninu ọti ti ki i ṣe ọrẹ ara .
Eyi lo fa a ti ikilọ fi maa n wa setigbọọ awọn ọmuti lati ọdun gbọgbọrọ wa.
Ṣugbọn ni bayii, iwadii dokita agba kan l'America, ti fidi ẹ mulẹ, pe oriṣi aisan jẹjẹrẹ meje( Cancer) ni awọn to ba n mu ọti n kọwe si, to si ṣee ṣe ki wọn lugbadi ẹ.
Dokita oniṣẹabẹ Vivek Murthy lati America, sọ pe:
"Ọpọ eeyan l'America ko mọ pe ọti ti fa kansa fun eeyan to to ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan (100,000).''
O ni ewu inu ọti naa n pa eeyan ẹgbẹrun lọna ogun, (20,000) lọdun nilẹ America.
Dokita Vivek sọ pe ijokoo apero yoo ni lati waye ki wọn too le paarọ akọle ikilọ to ti wa lara awọn ọti lati ọdun 1988.
Bakan naa lo pe fun bi wọn yoo ṣe da awọn to n mu ọti lẹkọọ, lori odiwọn to yẹ ki wọn mu.
O ni o yẹ ki idanilẹkọọ wa lori ajọṣepọ to wa laaarin ọti mimu ati kansa.
Irú àwọn ọtí wo gan-an ló ń fa jẹjẹrẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty image
Gẹgẹ bi Dokita Vivek Murthy ṣe ṣalaye, o ni ọti mimu ni nnkan kẹta to n fa jẹjẹrẹ fun awọn eeyan.
Bẹẹ, jẹjẹrẹ ọlọti yii ṣee dena, bawọn eeyan ba fiyesi i gẹgẹ bo ṣe sọ.
Awọn meji akọkọ to darukọ ni siga mimu ati ara asanju.
Nipa iru ọti to n fa jẹjẹrẹ pato, Dokita Muthy sọ pe:
" Ajọṣepọ to wa laaarin ọti mimu ati arun kansa ko kan iru ọti kan pato. Ko baa jẹ ọti bia (beer), waini tabi ọti lile (spirits), ọti lọti n jẹ to ba ti ni eroja alcohol ninu.
Jẹjẹrẹ apá ibo ni ọtí mímu máa ń fà nínú ara?

Oríṣun àwòrán, Irish Whiskey Association
Dokita Vivek ṣalaye pe awọn apa ibi ti jẹjẹrẹ ti ṣee ṣe ko mu awọn to ba n mu ọti ni *Ọyan, fun obinrin.
*Ọna ọfun
*Ẹdọ
*Gogongo
* Ẹnu
*Apoti ohun (larynx)
*Ifun nla (large intestine)
Abajade iwadii tuntun yii rọ awọn eleto ilera lati maa yẹ ọti wo ko too di mimu.
Wọn fi kun un pe ikilọ to wa lara akọle ọti bayii ko ju ti eyi to ni ki alaboyun ma mu ọti, ki wọn ma baa ni iṣoro ilera pẹlu ọmọ inu wọn.
Ikilọ keji ni ti awọn ọlọkọ tabi ẹni to ba n fi ẹrọ ṣiṣẹ, ki wọn ma lọọ ko si ijamba latari pe wọn ti mu ọti ki wọn too bẹrẹ si i wa ọkọ tabi lo maṣinni kankan.
Akọsilẹ Ajọ Ilera Agbaye, (World Health Organization Global Status Report on Alcohol and Health), ni 2018, sọ pe orilẹede 47 ti fi dandan le e, pe awọn to n ṣe ọti gbọdọ maa kọ awọn ikilọ yii si i lara.
Eyi le kun si i, yatọ si orilẹede mẹtalelọgbọn (31) to wa ni 2014.
Ireland ni orilẹede akọkọ to fi dandan le e, pe awọn ọlọti gbọdọ kọ ọ si i lara pe ọti le fa kansa.
Bi wọn ṣe wi, yoo di dandan lati 2026 fun gbogbo igo ọti ni Ireland lati kọ ọ si i lara pe ọti mimu le fa jẹjẹrẹ.
Àwọn orílẹ̀èdè kan ti gbé òdiwọ̀n lé ọtí tó yẹ kí wọ́n mu lójúmọ́
Lẹyin iwadii tuntun yii, Canada rọ awọn eeyan rẹ lati din igo meji lojumọ ku si igo meji lọsẹ kan. Ọdun to kỌja ni wỌn ṣe eyi.
America sọ pe ko ma ju meji lọ lojumọ fun ọkunrin, igo kan fun obinrin.
Orilẹede UK ni tiẹ sọ pe ko ma ju yuniiti mọkanla lọ lojumọ (14 units).
Eyi jẹ bii kọọbu mẹfa waini, tabi igo bia kan lọsẹ kan.
Àwọn kansa mi-in tó tún ṣeé ṣe kí èèyàn ní láti ara ọtí mímu

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ibudo to wa fun idena arun (Center for Disease Control and Prevention), ṣalaye pe ọti mimu le fa kansa to maa n ṣe awọn ọkunrin nibi ẹpọn, ti a mọ si prostate cancer.
Awọn iwadii kan sọ pe bi o ba mu ọti lile mẹta tabi ju bẹẹ lọ lojumọ, o le mu ki o sunmọ bebe jẹjẹrẹ inu.
Gbogbo ọti to ba ti ni eroja alcohol ninu ni wọn ni o le fa kansa.
Bi ọti ba gunlẹ lara eeyan tan, awọn kẹmika to le ṣe ijamba fun ara lo maa n pọ sinu ara eeyan.
Awọn dokita ṣo pe o tun ṣee ṣe ko da oju iṣẹ ti ara n ṣe ru, ti jẹjẹrẹ yoo fi rọna gba wọnu ara.














