Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti ọjà mẹ́tàlá pa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe oun ti ti ọja mẹtala pa nipinlẹ naa lẹyin ti wọn tapa si ofin ayika.
Eyi lo wa ninu atẹjade kan ti Kọmisana fun ayika ati omi, Tokunbo Wahab, fi sita lọjọ Ẹti.
Wahab ni, igbesẹ naa ṣe koko, to si rọ wọn lati mojuto ayika wọn fun ilera to peye.
" A gbe igbesẹ naa ni ibamu pẹlu ofin imọtoto ti ipinlẹ Eko ti ọdun 2017, to ni ki awọn ọja ni ibi kan ti wọn yoo ma da idọti si."
Pupọ ninu awọn ọja naa lo wa ni agbegbe Ketu ati Mile 12.
Eyi ni awọn ọja ti wọ ti pa
Ọja Erukan ni Mile 12
Oja Oba ni Ketu
Ọja Owoseni Tundas
Ọja Oba Ogunjobi ni Mile 12
Awọn oni sọọbu ni ibudokọ BRT ni Mile 12
Ọja Bus stop ni Mile 12
Ọja Ketu Terminal
Ọja Ifesowapo ni Mile 12
Demurin St Plaza shopping complex niKetu
Ọja Occupant to wa ni Demurin Street, Ketu
Ọja Ifelodun ni Ketu
Ọja Ibadan Station
Ọja Tipper Garage ni Ketu
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















