Èèyàn mẹ́jọ kú, ọ̀pọ̀ farapa, bí ọkọ̀ wọn ṣe kọlù àdó olóró ní òpópónà márosẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Èèyàn mẹ́jọ ti pàdánù ẹ̀mí wọn, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mìíràn sì farapa nígbà tí ọkọ̀ akérò kan ṣàdédé já lu àdó olóró ní òpópónà Maiduguri sí Damboa ní ìpínlẹ̀ Borno.
Àwọn tó farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n ti ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn Maiduguri Specialist Hospital báyìí.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìlá ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé tí ìròyìn sì ní ọkọ̀ tí wọ́n wà nínú rẹ̀ náà bàjẹ́ kọjá ohun tí wọ́n le tún ṣe rárá.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, Babagana Zulum ń fura pé àwọn agbéṣùmọ̀mí Boko Haram ló ń kó àwọn àdó olóró sí òpópónà tó so Domboa mọ́ olú ìpínlẹ̀ náà, Maiduguri.
Ṣáájú ni iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà ti òpópónà náà pa nítorí ètò ààbò kí gómìnà Zulum tó ṣí ọ̀nà ọ̀hún padà fáwọn arìnrìnàjò, tó sì ní káwọn ológun máa ṣọ́ ọ̀nà náà.
Gómìnà Zulum ní àwọn máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé lílọ bíbọ̀ ṣì ń tẹ̀síwájú ní òpópónà náà, pé àwọn kò ní jẹ́ kí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí mú àwọn láti pa lílo ọ̀nà ọ̀hún tì.
Níṣe ni àwọn agbéṣùmọ̀mí ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbin àdó olóró sáwọn òpópónà márosẹ̀ lẹ́yìn táwọn ológun ti ń lé wọn kúrò láwọn agbègbè tí wọ́n ń ṣàkóso rẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Ìròyìn ní ẹkùn mẹ́ta ni wọ́n ti rí gbà padà kúrò lọ́wọ́ àwọn agbéṣùmọ̀mí lẹ́kùn Lake Chad.
Irúfẹ́ ìkọlù báyìí ṣekúpa àwọn ọmọ ogun méje nígbà tí ọkọ̀ wọn lọ kọlú àdó olóró táwọn agbéṣùmọ̀mí gbìn sí ojú ọ̀nà báyìí.
Lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni ìkọlù Boko Haram tún ń wáyé léraléra tí Gómìnà Zulum sì ń kọminú nípa rẹ̀.















