Ìjọba Tinubu kó fi ẹ̀yà tàbí ojúṣàájú pín ipó-Iléeṣẹ́ Ààrẹ

Oríṣun àwòrán, President Bola Tinubu/ Facebook
Latari ọrọ kan ti Sẹnetọ Ali Ndume to n ṣoju Guusu Borno, sọ pe ijọba Tinubu n fi ẹlẹyamẹya pin ipo, ileeṣẹ aarẹ ti fesi pe ko sohun to jọ bẹẹ.
Sẹnetọ Ali Ndume lo fi ẹsun kan ijọba Tinubu, pe o tako ilana pinpin ipo ati nnkan amayedẹrun dọgba-dọgba ta a mọ si Federal Character.
Lori ileeṣan tẹlifiṣan kan ti Sẹnetọ Ndume ti sọrọ lo ti ni pinpin ipo ninu ijọba Tinubu fi sibi kan.
Nigba to n tako eyi lọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla oṣu Kẹrin, ọdun 2025, Oludari ẹka iroyin ati Akọwe lọfiisi ijọba apapọ Naijiria, Segun Imohiosen, sọ pe ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ to si le ṣi eeyan lọna ni Ndume fi kan ijọba Tinubu.
'Àkóyawọ́, ìṣọ̀kan àti ìlànà òfin la fi ń pín ipò''
Ninu atẹjade to ti ileeṣẹ Akọwe Aarẹ Tinubu wa naa ni wọn ti ṣalaye, pe ilana Federal character, abala kẹrinla ofin Naijiria ti 1999 ni ijọba Tinubu fi n pin ipo ati nnkan amayedẹrun.
Atẹjade naa sọ pe Aarẹ Tinubu ti da oju ijọba rẹ kọ igbega iṣọkan Naijiria, akoyawọ ati aisi ojuṣaaju.
"Ileeṣẹ Akọwe ijọba orilẹede yii, n fi eyi lodi si ohun to n lọ lori ayelujara nipa ilana ipo pinpin lọdọ ijọba apapọ.
" A n jẹ ko di mimọ, pe ko sohun to jọ pe pinpin ipo fi sibi kan, a si n kede awọn ohun ti a gbagbọ ti i ṣe akoyawọ, dọgba-n-dọgba ati iṣọkan orilẹede.
''A n yan awọn eeyan sipo ni ibamu pẹlu ilana Federal character, bo ṣe wa ni abala kẹrinla ofin orilẹede Naijiria ti 1999.''
Atẹjade naa rọ awọn eeyan lati ma ṣe gba iroyin ofege gbọ.
O ni ki wọn kan si ọfiisi Akọwe ijọba Naijiria fun akọsilẹ ati otitọ to wa nidii ipo pinpin .












