Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàwárí ilé ọmọ aláìníyàá tí wọ́n ti ń ta ọmọdé ní ìlú Abuja

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ni àwọn ti gba àwọn ọmọdé mẹ́tàlélógún kalẹ̀ kúrò ní ilé ọmọ aláìníyàá kan tó wà ní agbègbè Unguwar Kubwa ní ìlú Abuja, olú ìlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Wọ́n ní ilé ọmọ aláìníyàá ni àwọn gbọ́ pé wọ́n ń kó àwọn ọmọ náà lọ sí ilẹ̀ òkèrè láti lọ fi singbà.
Lára àwọn ọmọdé náà ni ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n ti lò tó ọdún mẹ́ta ní ilé náà.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá Kaduna, Mansir Hassan sọ pé ìpínlẹ̀ méje ni àwọn ti gbọ̀n yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ báyìí lójúnà àti tú àṣírí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ibi yìí àti láti nawọ́ gán àwọn tó lọ́wọ́ nínú jíjí àwọn ọmọdé gbé, tí wọ́n sì ń fi wọ́n ṣọfà.
Lára àwọn tí orí tún kó yọ yàtọ̀ sí àwọn ọmọdé náà ni àgbàlagbà ọkùnrin méjì àti obìnrin márùn-ún.
Mansur ní lára àwọn ọmọdé náà ni wọ́n jígbé lábẹ́ àwọn òbí wọn, tí wọ́n sì jí àwọn mìíràn gbé ní ibòmíràn.
Ó ní èèyàn mẹ́jọ ni àwọn ti nawọ́ gán lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ibi náà, táwọn sì gba àwọn ọmọ méjì tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún méjì sílẹ̀ àtàwọn méje mìíràn.
Ó fi kun pé àwọn òbí àwọn ọmọ ọ̀hún ni wọ́n ti ń yọjú láti gba ọmọ wọn tó fi mọ́ Debora, tí wọ́n ti ń wá láti ọdún mẹ́ta sẹ́yìn.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà sọ pé ilé ọmọ aláìníyàá kan tó wà ní agbègbè Kubwa, Abuja, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ "Debora Orphanage Home" ni àwọn ti ṣàwárí àwọn ọmọ náà.
Ó ní àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn rí gbà lẹ́nu àwọn èèyàn tí àwọn nawọ́ gán ni àwọn fi ṣàwárí ọmọ́ mẹ́tàlélógún.
"A ti kó mẹ́tàdínlógún nínú àwọn ọmọ náà fún ìjọba ìlú Abuja, tí a sì ti fa àwọn ọmọ yóò kú lé àwọn òbí wọn lọ́wọ́.
Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ yìí ni wọ́n máa ń kó láti ẹkùn gúúsù Nàìjíríà, tí wọ́n sì máa ń tà wọ́n lọ́pọ̀ ìgbà fáwọn tó máa fi wọ́n ṣe ẹrú.
"Wọ́n ta ọmọ kan ní mílíọ̀nù náírà, tí wọ́n sì ta òmíràn ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin náírà."
Mansir Hassan ní àwọn ti gbé lára àwọn afurasí náà lọ sí ilé ẹjọ́, tí ìwádìí sì ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn mìíràn tí wọ́n ṣì wà ní àgọ́ ọlọ́pàá.
Ìwà jíjí àwọn ọmọ gbé kìí ṣe ohun tuntun ní Nàìjíríà. Láìpẹ́ yìí ni irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí wáyé ní Kano níbi táwọn òbí kan ti fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ń jí àwọn ọmọ àwọn gbé tí wọ́n sì ń tà wọ́n sí ìpínlẹ̀ Anambra.
Lẹ́yìn ìwádìí, wọ́n ṣàwárí àwọn ọmọ náà, wọ́n sì dáwọn padà fáwọn òbí wọn.















