"Àwọn ajínigbé jí àádọ́ta èèyàn gbé, méjì dèrò ọ̀run, wọ́n ń bèèrè N100m owó itúsílẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan"

Oríṣun àwòrán, DEFENCEHQ
Nnkan ko fararọ fun awọn olugbe agbegbe Banga ati Gidan Giji, nipinlẹ Zamfara, pẹlu bi awọn ajinigbe-agbebọn ṣe n ji wọn gbe logun-logun, lọgbọn-lọgbọn.
Nibẹrẹ ọsẹ yii, o kere tan, awọn ajinigbe ji eeyan aadọta (50) gbe wọgbo lọ, wọn si pa eeyan meji ni Zamfara.
Awọn ilu meji yii nikan kọ ni ikọlu naa n kan, gẹgẹ bi awọn olugbe Zamfara ṣe wi.
Wọn ni bakan naa lo ri lawọn agbegbe mi-in nijọba ibilẹ Namoda.
Ọpọ eeyan la gbọ pe wọn ti n sa kuro ni awọn agbegbe ti wọn ti n ṣọṣẹ yii, ti wọn n fi ilu abinibi wọn silẹ lọ sibi ti wọn ba ri.
Ninu alaye awọn olugbe Banga ati Gidan Giji, wọn ni awọn to kọlu awọn n ko takọ-tabo wọgbo lọ ni.
Wọn ni wọn ko mọ ọmọde pẹlu, bẹẹ ni wọn si n beere owo itusilẹ ki wọn too le fi wọn yọnda wọn.
'Àwọn ajínigbé ti yí wa po, wọ́n ti gba ilẹ̀ ẹ wa'
Awọn olugbe Banga ati Gidan Giji ṣalaye, pe awọn ajinigbe ti gba ilẹ awọn ati awọn ilẹ mi-in to wa nitosi.
Wọn ni wọn ti yi awọn po to bẹẹ to jẹ pe awọn n sa kiri ki ibọn wọn ma baa pa awọn ni.
Wọn fi kun un pe ọkada ni pupọ awọn agbebọn naa maa n gun kọja pẹlu nnkan ija lọwọ, ti awọn yoo maa ri wọn kedere.
Wọn ni bi wọn ba ti de, iku de ni, wọn yoo si tun ko awọn lẹru lọ pẹlu.
"Wọn ti n kọlu wa lagbegbe wa tipẹ, ikọlu kan wa ta a koju ẹ ni Banga, niṣe ni wọn n ji awọn ọmọ wa ti wọn ba lẹnu ọna gbe.
Aadọta eeyan ni wọn ji gbe lọ, wọn si tun pa awọn mi-in.
"Awọn fijilante wa gbiyanju iwọn ti wọn le ṣe, bi ko ba si tiwọn ni, awọn ti wọn ko ba ji gbe ko ba pọ ju bayii lọ."
Bẹẹ ni olugbe agbegbe naa kan ṣalaye.
O fi kun pe miliọnu lọna ọgọrun-un kan naira ni awọn ajinigbe naa n beere ki wọn too le fi awọn ti wọn ji gbe silẹ.
Kí ni ìjọba Zamfara wi?
Ijọba ipinlẹ Zamfara ko ti i wi nnkan kan lori ọrọ yii.
Igbiyanju BBC lati ba agbẹnusọ gomina ipinlẹ naa, Suleiman Bala sọrọ, ko so eso rere pẹlu ipe ati atẹjiṣẹ ta a fi ranṣẹ si i.
Laipẹ yii ni iwadii kan jade lati ileeṣẹ Beacon Security Intelligence, atọpinpin kan ni Naijiria ati ni ẹkun-un Sahel.
Iwadii naa sọ pe loṣu Kẹta ọdun 2025 yii, ipinlẹ Zamfara lo wa nipo keji ninu awọn ibi ti jagidijagan ti waye ju.
Abọ iwadii naa sọ pe eeyan 179 ni wọn pa nibẹ loṣu Kẹta. Mejilelọọdunrun (302) lo ni wọn pa loṣu Keji.
Ipinlẹ Zamfara jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ to n koju ai si aabo ni Naijiria, pẹlu awọn alamuleti rẹ bii Kastina, Kaduna, Sokoto, ati Kebbi.
Ṣugbọn lọpọ igba, pẹlu bawọn olori agbegbe ṣe n sọ pe awọn n ṣẹgun iṣoro aabo yii to, ati pe awọn tilẹ tun n pa ninu awọn olorii wọn, sibẹ, awọn ajinigbe agbebọn ṣi n pa awọn eeyan, wọn si n ji wọn gbe wọgbo lọ.














