Agbébọn jí pásítọ̀ gbé lásìkò ìwàásù nínú ṣọ́ọ̀ṣì

Josh Sullivan

Oríṣun àwòrán, Fellowship Baptist Church

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn agbebọn ti ji pasitọ ọmọ ilẹ Amẹrika kan gbe lọ ninu ile ijọsin lasiko ti isin n lọ lọwọ ni South Africa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Captain Andre Beetge sọ fun BBC pe asiko ti Josh Sullivan n ṣakoso isin lọwọ ninu ijọ Fellowship Baptist Church to wa ni Motherwell ni awọn ọkunrin mẹrin ti wọn lo iboju ṣadede yabo ile ijọsin naa pẹlu ibọn lọwọ wọn.

Ọlọpaa ni awọn mẹrin naa ji ẹrọ ilewọ meji ki wọn to salọ ninu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Fortuner to jẹ ti pasitọ ọhun.

Ọlọpaa ṣawari ọkọ naa nibi ti wọn gbe si amọ wọn ko kofiri Sullivan.

Agbẹnusọ kan lati ọọfisi ijọba Amẹrika sọ fun BBC pe awọn ti gbọ pe awọn kan ji ọmọ ilẹ Amẹrika gbe lọ ni South Africa.

Wọn ni afojusun awọn ni abo to peye fun ẹmi ati dukia awọn ọmọ ilẹ Amẹrika to n gbe ni South Africa.

Ninu alaye Beetge fun BBC, o ni wọn ti taari isẹlẹ naa si ẹka ọtẹlẹmuyẹ "Hawks" to n ṣewadii awọn ẹsun to nipọn.

Agbẹnusọ fun ẹka Hawks, ọgagun Avele Fumba ni "Ọlọpaa n ṣiṣẹ takuntakun lati lo gbogbo ọna to mọ lati ṣawari ọkunrin naa ki a si fi oju gbogbo awọn to lọwọ ninu ijinigbe rẹ wina ofin.

Jeremy Hall, to sọrọ lorukọ mọlẹbi Sullivan ni iyawo atawọn ọmọ rẹ wa ninu ile ijọsin lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.

Hall sọ pe "wọn mọ orukọ rẹ."

Nigba ti iya ọkurin naa, Tonya Morton Rinker, n sọrọ loju opo Facebook rẹ, o ni iṣẹlẹ ọhun ba oun ninu jẹ gidi.

O fi kun pe aṣofin Amẹrika ati ijọba ilẹ naa ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣawari ọmọ oun.

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, awọn to ji ọkunrin naa gbe ko tii bere owo itusilẹ kankan.