Ìyapa wáyé láàrin àwọn gómìnà PDP àti Atiku lórí ète láti darapọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú míràn fétò ìdìbò 2027

Igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà, tó tún jẹ́ èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP tin í kò sí bí àwọn ṣe lè yẹ àga nídìí Ààrẹ Bola Tinubu níbi ètò ìdìbò lọ́dún 2027 tí àwọn kò bá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn.
Ọ̀rọ̀ Atiku yìí ló ń wáyé lẹ́yìn táwọn gómínà ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe ní ìlú Ibadan lọ́jọ́ Ajé, sọ pé PDP kò ní parapọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú kankan lórí ètò ìdìbò ọdún 2027.
Àwọn gómìnà náà sọ pé àǹfàní wà fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ àmọ́ àwọn kò ní parapọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ mìíràn.
Tí ẹ ò bá gbàgbé, ní ogúnjọ́, oṣù Kẹta, ọdún 2025 ni Atiku, Peter Obi ti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party àti gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai tó ṣẹ̀ṣẹ̀ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú SDP kéde pé àwọn ń gbèrò láti parapọ̀ lójúnà àti ṣí Tinubu nídìí kúrò ní ilé ìjọba lọ́dún 2027.
Láti ìgbà tí wọ́n ti kéde ìpinnu wọn ni àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ lórí ètò òṣèlú ti ń sọ àríwísí wọn lórí èròńgbà náà.
Atiku, tí ọ̀pọ̀ gbàgbọ́ pé ó ní èròńgbà láti díje dupò ààrẹ lọ́dún 2027, ló ti ń pè fún ìṣọ̀kan láàárín àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, tó sì ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti kó pawọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò papọ̀.
Ó wòye pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èèkàn ẹgbẹ́ ni àwọn gómìnà jẹ́, ó ní ìpè fún píparapọ̀ àwọn ẹgbẹ́ alátakò kọjá ọ̀rọ̀ àwọn gómìnà nìkan bíkòṣe ọ̀rọ̀ àwọn aráàlú Nàìjíríà.
Agbẹnusọ Atiku, Paul Ibe sọ pé ó pọn dandan láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn tí wọ́n bá fẹ́ ní ìlọsíwájú.
Ó fi kun pé àwọn ṣe ìwádìí kí àwọn tó bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti darapọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú àti pé ọ̀rọ̀ tí àwọn gómìnà náà sọ jẹ́ kó yé àwọn pé àwọn ṣì nílò láti ṣe ìtàkurọ̀sọ pẹ̀lú àwọn gómìnà náà láti jẹ́ kí wọ́n rí ìnílò láti jẹ́ kí píparapọ̀ náà wáyé.
"Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn gómìnà kò ṣe pàtàkì, wọ́n ṣe pàtàkì gan. Àmọ́ ọmọ Nàìjíríà náà ṣe kókó, tí ìgbésẹ̀ yìí sì túmọ̀ sí pé ó jẹ́ ọ̀nà láti gba orílẹ̀ èdè yìí kalẹ̀ lọ́wọ́ ewu tó wà."
A ṣetan lati tẹwọ gba ẹni to ba fẹ wọ ẹgbẹ oṣelu wa, awa ko ni darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu miiran - Awọn gomina PDP
Ṣaaju ni ẹgbẹ awọn Gomina ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọgile erongba to n ja kiri pe wọn fẹ darapọ mọ awọn ẹgbẹ oṣelu yooku tabi ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu kankan.
Eyi lo wa ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi lede lẹyin ipade kan to waye niluu Ibadan, lọjọ Kẹdogun oṣu kẹrin ọdun 2025.
Ipade naa ti Gomina Bala Mohammed ti ipinlẹ Bauchi jẹ alaga fun ni gbogbo awọn Gomina ẹgbẹ oṣelu PDP darapọ pẹlu lati jiroro nipa ọrọ ẹgbẹ oṣelu naa ati orilẹede Naijiria.
Nipa ọrọ to so mọ ṣiṣẹ papọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu yooku saaju eto idibo ọdun 2027, PDP ni awọn setan lati tẹwọ gba ẹnikẹni, ẹgbẹ to ba fẹ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa sugbọn ko si ninu erongba wọn lati ṣiṣẹ pẹlu ẹgbẹ oṣelu kankan.
Bákan naa ni ẹgbẹ sọ ẹdun ọkan lori ikede ìlu o fararọ nipinlẹ Rivers, tí wọn kede atilẹyin wọn fun Gomina Sim Fubara
"O da bi títẹ ẹtọ ọmọ nìyẹn mọlẹ, a si setan lati ṣe gbogbo atilẹyin fun Gomina Sim Fubara lasiko yii.
"Lati daa bobo ijọba awarawa, a setan lati mo rí ile ẹjọ gíga lati tako igbesẹ ìjọba apapọ lori ipinlẹ Rivers."
Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo gba alejo awọn Gomina ẹgbẹ oṣelu PDP.
Awọn to wa ni Ijoko ipade naa: Dauda Lawal(Zamfara); Caleb Mutfwang(Plateau)); Umaru Fintiri(Adamawa), Ademola Adeleke (Osun) ati Douye Diri(Bayelsa).
Gomina Sheriff Oborevwori(Delta) ati Gomina Umo Eno(Akwa Ibom) ni o jẹ pe igbakeji wọn lo soju fun nibi ipade naa.
Wo bí nǹkan ṣe ń lọ níbi ìpàdé àwọn Gómìnà ẹgbẹ́ PDP tó ń lọ lọ́wọ́ n'Ibadan

Ipade laarin awọn Gomina mejila to n bẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n lọ lọwọ ni ọfisi Gomina ipinlẹ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde.
Lati ọjọ Aiku ni awọn Gomina naa ti gunlẹ si ilu Ibadan ti wọn si kopa nibi eto igbalejo ati wẹjẹwẹmu to waye ni gbọngan nla igbalejo ICC to n bẹ ni fasiti ilẹ Ibadan.
Lara awọn koko ọrọ ti iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe awọn Gomina naa yoo sọ asọyepọ le lori ni ọrọ Gomina ipinlẹ Rivers, Siminalayi Fubara ti Aarẹ Tinubu ni ki o fi ipo silẹ fun oṣu mẹfa lẹyin ti wọn kede ilu ko fararọ n'ipinlẹ naa, eto idibo si ipo aarẹ orilẹede Naijiria lọdun 2027 naa ko bẹyin ninu awọn nnkan ti wọn o sọ asọyepọ le lori.
Awọn Gomina naa to pejupesẹ naa ni, Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun, Siminalayi Fubara ipinlẹ Rivers, Peter Ndubuisi Mbah lati ipinlẹ Enugu, Francis Orohwedor Oborevwori to ipinlẹ Delta, Caleb Manasseh Mutfwang ti ipinlẹ Plateau, Douye Diri lati ipinlẹ Bayelsa, Bala Mohammed ti ipinlẹ Bauchi, Uno Eno lati ipinlẹ Akwa Ibom, Ahmadu Umaru Fintiri ti ipinlẹ Adamawa, Agbu Kefas ti ipinlẹ Taraba ati Dauda Lawal lati ipinlẹ Zamfara.
Gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ ni olugbalejo nibi ipade naa.

















