Portable sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí bàbá rẹ̀, ka ọ̀pọ̀ ẹ̀sùn sí i lọ́rùn pé bàbá burúkú ni

Aworan Portable ati Baba rẹ

Oríṣun àwòrán, @Thrends/ RemiOlawale

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Habib Okikiola, ẹni ti ọpọ mọ si Portable tun gbe ohun tuntun sita eyi to tun ya ọpọ lẹnu bi o se tun na ika abuku si Baba to bi lọmọ.

Portable bọ sori ikanni ayelujara Instagram rẹ lati fẹsun kan Baba to bi lọmọ pe o lu oun ni jibiti, to si fi silẹ lasiko to n koju iṣoro.

Gẹgẹ bii Portbale ṣe sọ, o ni oun n fun Baba oun lowo pe ko ma mojuto awọn ile to n kọ ṣugbọn baba rẹ kuna lati lọ ba awọn ọlọpaa sọrọ, to si jẹ pe oun lo ko si wahala bayii.

Portable ni o yẹ ki Baba oun le lọ si agọ ileeṣẹ ọlọpaa lati lọ ba wọn sọrọ lori ọrọ rẹ.

O pe baba naa ni baba buruku, to si sọ pe bi oun ti n fun ni owo to, o si tun lu oun ni jibiti.

"Ṣugbọn ki lo de ti Baba mi ko le lọ si agọ ọlọpaa?

Oun ni mo n fun ni owo pe ko ba mi kọ ile. To ba jẹ pe o ti ba awọn ọlọpaa sọrọ, n ko ni wahala pẹlu awọn eeyan yii.

"Ki lo de ti baba mi o lọ si ileeṣẹ ọlọpaa? Ile to jẹ pe emi ni mo n fun yin lowo pe ki ẹ ma kọ.

Gbogbo ile lo jẹ ti idile Badmus"

Aworan oro ti Portable gbe sori ayelujara

Oríṣun àwòrán, Instagram

Àkọlé fídíò, Kí ni pàtàkì orí òrìṣà Oshoosi tí Ooni má bọ lọ́dọdún?

Ìdí rèé tí àbúrò mi fi ń ṣe wére-wère, ẹ má pa á, bí ẹ ṣe pa ìyá wa - Ẹ̀gbọ́n Portable figbe ta

Portable ati ẹgbọn rẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Awuyewuye lori ọrọ Portable ọmọ Olalomi torukọ rẹ n gan-an n jẹ Habeeb Okikiola ati ijọba ipinlẹ Ogun lori ẹsun pe oun ati awọn ọmọ ẹyin rẹ fiya jẹ awọn oṣiṣẹ ijọba kan to n ṣiṣẹ wọn, tun ti ba ibomiran yọ.

Awọn oṣiṣẹ ijọba lati ileeṣẹ to n ri si aato ilu lati Ota, (Ota Zonal Planning Office) ni a gbọ pe Portable ati awọn ọmọ ẹyin rẹ kọju ija si l'Ọjọru, ọjọ karun-un, oṣu Keji ọsẹ to kọja.

Portable ti ke gbajare pe nnkan ìbànújẹ lo jẹ fun oun pe ninu ọkan lara ile oun ti ijọba ipinlẹ Ogun gbe tipa ni iboji iya oun wa.

Ninu ile mi ti ijọba tipa ni mo sin iya mi si - Portable

Portable ti pariwo wi pe ninu ọkan lara ile oun ti ijọba ipinlẹ Ogun tipa ni oun sin iya oun si.

Portable to sọrọ yii ninu fọ́nrán kan loro itakun ayelujara Instagram sọ pe eyi jẹ nnkan to maa gba omije loju oun.

Portable tun sọ ninu fidio ọhun wi pe oun ko b'awọn oṣiṣẹ ijọba naa ja, koda, o ni oun n sun lọwọ ni nigba ti wọn de.

Ọmọ Olalomi sọ pe awọn oṣiṣẹ ijọba ọhun gbe okowo oun tipa, bẹẹ ni wọn tun ba ile ọti oun jẹ.

Portable ni k'awọn oṣiṣẹ ijọba naa ẹri to daju wa lati fi idi ẹsun ti wọn fi kan oun mulẹ ti o ba dawọn loju bẹẹ.

"Irọ ni wọn pa mọ mi at'awọn ọmọ ẹyìn mi,

ohun to n dun mi ni pe ninu ile ti wọn tipa ni mo sin iya mi si nigba ti mo wa lọmọ ọdun mẹtala.

Wọn tun ti ile ti mo ti maa n ran ọpọ eeyan bii kafinta, telọ at'awọn eeyan mii lọwọ, yatọ si awọn olorin nìkan," Portable lo sọ bẹẹ.

Ẹ ma jẹ ki n pa ara mi, ẹ tu awọn ọmọ ẹyin mi silẹ - Portable

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Portable ti rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Ogun lati tu awọn ọmọlẹyin rẹ ti wọn fọwọ ofin mu silẹ, bi bẹẹ kọọ oun le pa ara oun.

Ẹsun ti wọn fi kan awọn ọmọlẹyin Portable mẹsan an ti wọn mu naa ati Portable funra ẹ ni pe wọn jọ fiya jẹ Abidemi Onabanjo, Ramon Lateef, ati Akinpelumi Oyero ti wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba lati ileeṣẹ OGPDPA to n ri si aato ilu.

Wọn ni Portable ati awọn ọmọ ẹyin rẹ fẹẹ pa awọn oṣiṣẹ ijọba naa ni, pẹlu bi wọn ṣe kojuu wọn ti wọn si tun di wọn lọwọ iṣẹ wọn.

Ọjọ keji iṣẹlẹ naa ti i ṣe Ọjọbọ ni wọn si fi oju wọn bale ẹjọ, ṣugbọn Portable funra rẹ ti na papa bora.

Lẹyin naa ni Portable sọ pe ṣadeedee l'awọn oṣiṣẹ ajọ OGPDPA yabo ile ọti oun, ti wọn si ko awọn olorin, awọn onibaara oun at'awọn dukia oun mii lọ to fi mọ awọn ọkọ oun kan.

Gbajugbaja olorin Zaa zoo fikun ọrọ rẹ pe awọn to n kọṣẹ lọdọ oun ni awọn ti wọn ko lọ, wọn kii ṣe onijagidijagan.

Amọ, Kọmiṣọnna ileeṣẹ to n si aato ilu nipinlẹ Ogun, Họnarebu Ọlatunji Odunlami sọ pe irọ to jina si ootọ ni Portable n pa.

Ẹgbọn Portable obinrin bẹbẹ lori ọrọ Ọmọ Olalomi

Ẹwẹ, ẹgbọn Portable obinrin ti rawọ ẹbẹ si gbogbo ọmọ Naijiria wi pe ki wọn ran oun lọwọ lori ọrọ to n lọ laarin rẹ ati ijọba ipinlẹ Ogun.

Obìnrin naa to sọrọ ninu fọnran lori ayelujara sọ pe oun loun mu Portable wa siluu Eko.

"Emi ni ẹgbọn Portable, ọmọ mẹta naa ni iya bi, emi si ni akọbi.

Portable dẹ n gbiyanju, o n kọ orin rẹ, ko jale ri.

Ko si ẹni to ri wa tẹlẹ, amọ, nigba ti Ọlọrun bukun Portable, o n ṣe fun ẹbi, o n ṣe fun ara," ẹgbọn Portable lo sọ bẹẹ.

Obìnrin yii ti sọrọ ko ṣẹyin ọkùnrin kan ti orukọ rẹ n Akeem to pe ara rẹ ni ẹgbọn Portable to n ṣepe ninu fidio kan to ti sọ wi pe Portable ko ni bọ ninu wahala to wa tori ko fi owo rẹ mọ ẹbi.

O ni ọmọ aburo iya awọn ni Akeem jẹ, o si maa n ro ẹjọ Portable kiri pe ko foun lowo.

Ẹgbọn Portable ni ọrọ ko ri bi Akeem ṣe sọ tori Portable lo tọju oun nigba toun fi ẹsẹ gun nkan.

Obìnrin naa gbajare sawọn ọmọ Naijiria pe ki ba oun pe Akeem si idajọ tori o ni oun lo nidi ẹsẹ to n dun oun.

Bakan naa lo tun sọ pe Akeem lo tun jẹ ki Portable ṣe ijọba.