Adelabu ṣèpàdé pẹ̀lú IBEDC lórí ìdákúrekú iná mọ̀nàmọ́ná ní UCH

Adelabu lásìkò ìpádé tó ṣe pẹ̀lú àwọn aláṣẹ UCH àti IBEDC
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Minisita fun ohun amuṣagbara ni Naijiria, Adebayọ Adelabu ti ṣe ipade pẹlu ileeṣẹ to n pin ina mọnamọna, Ibadan Electricity Distribution Company, IBEDC, lori awọn ipenija to n koju ipese ina ọba nile iwosan ijọba apapọ, UCH to n bẹ niluu Ibadan.

Ipade idakọkọ kan ti kọkọ waye fun wakati kan ni ọfisi alaskoso ile iwosan naa, Ọjọgbọn Jesse Abiodun Otegbayo, ko to di pe wọn jade sinu gbọngan igbalejo ile iwosan naa, ni ibi ti awọn oniroyin wa.

Ninu ọrọ ti o sọ ni ibi ipejọpọ naa, ọga agba ile iwosan UCH, Otegbayo dupẹ lọwọ Adelabu fun ifarahan rẹ lati wa ojutu si iṣoro ina ọba to bẹrẹ ni ile iwosan naa l'ọdun to kọja.

O ni gbogbo ipa ni awọn n sa lati wa ọna abayọ si iṣoro naa ipa wiwa ọna mii lati maa tan ina nile iwosan naa, ṣugbọn pabo ni igbiyanju wọn ja si nitori aisi owo lati gbọ bukata ọna mii ti wọn le gba pese ina.

Otegbayo tẹsiwaju pe ile iwosan naa tun gbiyanju lati pese ina nipa lilo agbara orun, iyẹn Solar lati pese ina ni awọn igun kọọkan nile iwosan naa bii, South West 1-4, North West 1-3, C1-4th, C1-2nd ati bẹẹbẹẹ lọ.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe ko si ohun amuṣagbara ti o rọju ti owo rẹ ko si wọn bii ina ọba.

Ọga ile iwosan UCH tẹsiwaju wi pe gbese igba le mẹtalelọgọrin Milliọnu Naira, #283Million ni ile iwosan naa jẹ ileeṣẹ to n pin ina ọba, IBEDC.

Njnu gbese yii, Milliọnu mẹtalelọgọta, #63Million ni ile ẹkọ giga nipa imọ iṣegun Oyinbo, 'College of Medicine' jẹ ninu owo naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ tiẹ, alakoso ileeṣẹ IBEDC, Onimọẹrọ Francis Agoha ṣe alaye wi pe itẹsiwaju ti ba ọrọ naa lẹyin ti Minsita fun ohun amuṣagbara pe ipade lati wa ojutuu sii.

O ni onibara ọwọn ni ile iwosan UCH jẹ si awọn, ṣugbọn gbese ti wọn jẹ lo da rogbodiyan silẹ, gẹgẹ b gbogbo eeyan ṣe mọ pe ilu le fun awọn olokoowo.

Lara awọn nnkan ti wọn fi ohun ṣe ọkan le lori ni pe UCH ti gba lati maa san gbese naa pada diẹdiẹ, ayẹwo finifini yoo si wa fun gbogbo awọn ileeṣẹ ati ileigbe to n lo ara ina UCH ki wọn le mọ awọn nnkan to ṣokunfa gbese gọbọi to n bẹ lọrun ile iwosan naa. Lẹyin eleyii ni ina UCH yoo jẹ titan pada laarin wakati mẹrinlelogun si wakati mejidinlaadọta.

Ninu ọrọ ti sọ ni ibi ipade naa, Adelabu ni inu oun dun wi pe ipade naa waye nitori pe aisi ina ọba ni UCH ti di nnkan iwọsi fun ijọba apapọ.

O ni wọn ti gbe igbesẹ kan sẹyin, ṣugbọn ko fi bẹẹ so ero rere.

Minisita fun ohun amuṣagbara tẹsiwaju wi pe iru ipenija to niiṣe pelu ina ọba ti waye ni awọn ile ẹkọ giga bii fasiti Benin, Fasiti ilu Eko, ti Abuja ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti ijọba apapọ si wa ojutuu sii.

Oni ọna abayọ naa yoo waye fun ile iwosan UCH lẹyin ipade oni.

Ki lo ti ṣẹlẹ saaju asiko yii?

O ti to bii oṣu meloo kan sẹyin bayii ti ọkanojọkan awuyewuye ti rọ mọ ipese ina ọba ni UCH.

Ọpọlọpọ igba sini awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ eleto ilera ti da iṣẹ silẹ ninu ọgba ile iwosan naa nitori aisi ina mọnamọna to ja geere.

Bakan naa ni awọn ipade kan ti waye laarin awọn aṣoju ile iwosan naa ati awọn alakoso ileeṣẹ IBEDC, ṣugbọn ipade naa ko so eso rere titi di asikoyii.

Awọn alakoso UCH tiẹ pariwo sita lati beere iranwọ lọwọ ijọba ati awọn ẹlẹyinju aanu lọdun to kọja, ṣugbọn bakan naa ni ọmọ ṣori.

Iroyin mii tun lu sita ni bii ọjọ meji sẹyin pe awọn mọlẹbi alaisan lo n gbe ẹrọ amunawa si ile iwosan naa funra wọn, bẹẹ sini ni awọn ti ko ni agbara ẹrọ amunawa n fi abẹbẹ fẹ ara wọn, ṣugbọn awọn alakoso UCH ni irọ to jina si otitọ ni iroyin naa.

Ṣé lóòótọ́ ni àwọn aláìsàn ń fa gẹnẹrátọ̀ lọ UCH fún ìpèsè iná lásìkò ìtọ́jú?

Ile iwosan UCH

Iroyin kan tó n ja ran-an lórí ayelujara nipa aisan ina ọba nile iwosan UCH nilu Ibadan, ti da awuyewuye silẹ.

Iroyin náà lo ni ọpọlọpọ àwọn alaisan to n gba itọju nile iwosan UCH lo n la isoro alagbara koja tori àìsí ina ọba.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii la mu iroyin wa fun yin pe ajọ to n pese ina ọba nilu Ibadan, IBDEC, ti ja waya ina ọba to wọnú ile iwosan naa nítorí pé ó jẹ gbese miliọnu lọ́nà ẹẹdẹgbẹta Naira o din marun.

O si ti tó osu mẹ́rin sẹyin ti igbesẹ jija ina ọba naa ti waye, eyi to mu ko nira fáwọn ẹ̀ka isegun pàtàkì láti ṣiṣẹ.

"Àwọn alaisan nílé iwosan UCH mú abẹ̀bẹ̀ lọwọ láti fẹ ara wọn tori ooru amuju, nigba tàwọn miran gbé faanu to n ló battery wá"

Iroyin náà ni ṣe ni àwọn alaisan nílé iwosan UCH mú abẹ̀bẹ̀ lọwọ láti fẹ ara wọn tori ooru amuju, nigba tàwọn miran gbé faanu to n ló battery wá.

Iroyin naa ni ọpọlọpọ wọọdu lo wa ninu okunkun, ti ewu nla si n bẹ fáwọn alaisan to nilo ẹ̀rọ láti gbé èmi wọn ró.

Iroyin naa fi kun pé àwọn aláìsàn yìí ló n da owó jọ láti ra epo sínú ẹ̀rọ amunawa, ti oníṣòwò kan sì bun ilé wòsàn náà ni ẹ̀rọ amunawa.

Àmọ́ ọwọ isẹ abẹ ati ìtọ́jú àìsàn pajawiri nìkan ni ìròyìn ọhun sọ pe wọn n lo ẹ̀rọ gẹnẹrátọ̀ náà fún.

Iroyin náà tún ṣàlàyé pé ọpọlọpọ aláìsàn lo n fi ile iwosan UCH silẹ, gba ilé wòsàn miran lọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé UCH ni ẹ̀rọ amunawa tó ń lo agbára oòrùn láti pèsè iná, síbẹ̀ èyí kò tó fún isẹ wọn.

Irọ́ ni pé aláìsàn ń fa gẹnẹrátọ̀ wà sí UCH, ìròyìn òfegè ni, ètò ìṣègùn kò yinjẹ - UCH

Wàyí o, àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn UCH tí fèsì lórí ìròyìn tó gbà ilẹ̀ kan náà, nípa ìṣòro tó ń koju àwọn aláìsàn nílé ìwòsàn UCH torí àìsí ìpèsè iná ọba.

Atẹjade kan tí alukoro ile iwosan UCH , Arábìnrin Funmi Adetuyibi fọwọsi ṣàlàyé pé irọ́ tó jìnnà sootọ ni iroyin náà, ofuutu fẹẹtẹ àti ẹbu ìròyìn sì ni.

Atẹjade náà ni ile iwosan kii lo àwọn ẹ̀rọ amunawa kekeke tí ìròyìn náà ni awọn alaisan ń gbé wa sílè ìwòsàn ọhun lásìkò itoju.

"Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lóòótọ́ nile isẹ amunawa tí ja iná ọba to wọ inú ọgbà UCH, àmọ́ a ń ṣe gbogbo ipa lati ri dájú pe eto isegun ko yinjẹ pẹlu isẹ ìwádìí àti idanilekọ.

Àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn UCH sì ń ṣíṣẹ́ takuntakun láti rí dájú pé a wá ọna àbáyọ miran sì ipese ina ọba, pàápàá láti ipasẹ ẹ̀rọ Sòlà tó ń lọ oòrùn fún ìpèsè iná àti àmúlò ẹ̀rọ gẹnẹrátọ̀.

Lára àwọn ibùdó tó sì ń gbádùn ìpèsè iná yìí julọ ni àwọn wọọdu, ibùdó itọju àwọn aláìsàn ni pajawiri, yàrá igbẹbi ati yàrá isẹ abẹ."

Atẹjade náà ni UCH tí n sanna láti wá ojútùú láéláé si ìṣòro àìsí iná ọba nípa fífi ikùn lu ikùn pẹlu awọn alẹnulọrọ labẹle àti lókè òkun, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ti ń gbé owó tuulu kalẹ láti tí ilé ìwòsàn náà leyin.