Kí ló dé tí jẹjẹrẹ ń pọ̀ sí i láàárín àwọn èèyàn tí kò tí ì dàgbà púpọ̀ lásìkò yìí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iyalẹnu nla lo jẹ fun obinrin kan, Luisa Toscano, nigba to mọ pe oun ti ni arun jẹjẹrẹ ọmu.
Ọmọ orilẹede Brazil, ẹni ọdun mejidinlogoji (38) to ti bimọ meji naa sọ pe:
"Mi o tiẹ ro pe o le ṣẹlẹ si mi rara, mo ṣi kere lọjọ ori, ara mi si le daadaa, mi o si ni apẹẹrẹ kankan tabi idi kan to fi yẹ ki kinni yii ṣẹlẹ si mi. Mi o le gbagbọ rara, jẹjẹrẹ ko tiẹ si ninu nnkan ti mo le ronu pe yoo ṣẹlẹ si mi laye mi."
Oṣu kẹta ọdun 2024 ni dokita fidi ẹ mulẹ fun Luisa, pe jẹjẹrẹ ọmu wa lara rẹ, koda, o ti wa ni ipele kẹta (stage three).
Luisa gbera, o lọọ gbatọju ti wọn n pe ni 'Chemotherapy' fun oṣu mẹrin aabọ.
O ṣe iṣẹ abẹ lati ge apa kan ọyan naa kuro, lẹyin naa lo tun lọọ ṣe omiran ti a mọ si 'Radiotherapy.'
Loootọ ni obinrin yii pari itọju rẹ loṣu Kẹjọ, ṣugbọn o ṣi nilo lati maa lo oogun rẹ ki jẹjẹrẹ naa ma baa pada wa.
"Chemotherapy buru pupọ, ṣugbọn ara mi gba a daadaa, idi si ni pe mo jafafa, mo ṣi kere lọjọ ori, ara mi si ribi ti yoo gba itọju lile naa si" Luisa lo ṣalaye bẹẹ.
Lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ

Oríṣun àwòrán, Luisa Toscano
Luisa ṣalaye irin ajo rẹ nipa jẹjẹrẹ ọmu siwaju. O ni:
"Inu mi dun pe wọn ko ge gbogbo ọyan mi.
"Ibi to nira fun mi ninu ẹ ju ni irun mi to re danu. Gbogbo ẹ kan n ṣẹlẹ kiakia ni, o si lagbara gan-an.
Ti mo ba wo ara mi ninu jigi, ẹru aa ba mi, iṣẹlẹ yii kan awọn ọmọ mi naa, inu wọn o dun."
Lẹyin ti wọn tọju Luisa tan, o ni
"Ẹkọ pataki ti mo kọ ni lati gba ohunkohun to ṣẹlẹ pẹlu ọkan akin.
"Ti irẹwẹsi ba de, mo gba, to ba si di asiko ayọ, ma a dunnu."
Imọran mi fun awọn eeyan ni pe ki wọn maa ṣe pẹlẹ.
" Teti si ohun ti ara rẹ ba n sọ. To ba rẹ ọ, sinmi, o le ṣe ohun ti o fẹẹ ṣe yẹn nigba mi-in lẹyin isinmi.
"Oju apa ki i jọ oju ara fun kansa loootọ, ṣugbọn ma ṣe jẹ ko nipa lorii rẹ, ohun gbogbo lo nitumọ ati idi to fi n waye."
Jẹjẹrẹ ń pọ̀ sí i

Iṣẹ iwadii kan ti ẹka BMJ to n ri si jẹjẹrẹ, fi sita, ṣalaye pe bi jẹjẹrẹ ṣe n mu awọn eeyan ti ọjọ ori wọn ko ti i pe aadọta (50), n pọ si i pẹlu ida mọkandinlọgọrin (79%).
Wọn ni eyi waye laaarin ọdun 1990 si 2019.
Bẹẹ ni wọn ni awọn ti kansa pa laaarin ọjọ ori yii tun lekun pẹlu ida mejidinlọgbọn (28%).
Iwadii naa ka oriṣi jẹjẹrẹ mọkandinlọgbọn (29) kaakiri orilẹede mẹrinlenigba (204 countries).
Bakan naa ni abọ iwadii kan lati Lancet Public Health, sọ pe oriṣi jẹjẹrẹ mẹtadinlogun lo ti pọ si lati iran de iran lorilẹede America, paapaa laaarin awọn ti wọn pe ni Gen X, ati awọn ti wọn bi laaarin ọdun 1965 si 1996.
Iwadii kan sọ pe jẹjẹrẹ ọmu lo n pọ si i ju.
Àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó fa jẹjẹrẹ fún èèyàn
Awọn oluwadii n gbiyanju lati mọ awọn nnkan to le ṣokunfa aisan jẹjẹrẹ, nitori iwadii Lancet kilọ, pe bi aisan yii ba n tẹsiwaju lati maa pọ si i, yoo ṣakoba fun aṣeyọri tawọn tiẹ ti ṣe tẹlẹ lori idena kansa.
Lọwọ yii na, awọn ounjẹ bii ẹran pupa, ọti mimu, siga mimu, wa lara awọn ohun ti wọn sọ pe o n fa aisan jẹjẹrẹ, gẹgẹ bi abọ iwadi Lancet ti wi.
Bakan naa ni wọn ka ara asanju mọ idi kan ti jẹjẹrẹ fi le mu eeyan, nitori ara asanju yoo ṣakoba fun iṣẹ awọn ẹya ara kan. Ajọ eleto ilera agbaye, (World Health Organization), lo sọ eyi.
Abọ iwadii Lancet sọ pe mẹwaa ninu jẹjẹrẹ mẹtadinlogun lo ti pọ si i laaarin awọn eeyan ti ko dagba pupọ l'America.
Wọn ni jẹjẹrẹ to kọlu wọn naa ni i ṣe pẹlu ara asanju.
Oriṣi jẹjẹrẹ ti Lancet ka pe o n ṣe wọn ni ti kindirin, ti oju ara obinrin, jẹjẹrẹ ẹdọ, ti ifun ati ti oronro.
Ṣugbọn o, awọn idi mi-in tun wa to n fa jẹjẹrẹ wọnyi.
Awọn onimọ ijinlẹ ko duro ninu iwadii lati mọ awọn nnkan mi-in to tun n fa jẹjẹrẹ.
Awọn kan sọ pe bi eeyan ba n fi ara gba awọn ina to n jade lati ara awọn nnkan eelo ti a fi n ṣiṣẹ, le fa a.
Wọn ni awọn ina oju u popo naa le fa ki eeyan wa ninu ewu jẹjẹrẹ ọyan, ti ifun, ti oju ara ọkunrin ati obinrin.
Koda, awọn kan sọ pe bi eeyan ba n ṣiṣẹ ti asiko rẹ maa n yipada (shift work), to si n fara gba awọn ina to n ti ara ẹrọ to n lo wa, wọn ni eyi le din eroja melatonin ara rẹ ku, ko si dohun ti kansa yoo maa gberu ninu ara .














