Ebola tún ṣẹ́yọ ní Uganda, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ abẹ́rẹ́ àjẹsára

Oríṣun àwòrán, Reuters
Orilẹede Uganda ti bẹrẹ eto abẹrẹ ajẹsara lati dena arun Ebola to tun ṣẹyọ nibẹ, lẹyin ti arun naa pa ẹnikan ti awọn meji mi-in si tun fara ko o.
Ẹni akọkọ to fara ko aisan naa ku lọsẹ to kọja, nọọsi ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn ni.
Lọjọ Aje ni awọn ìṣí akọkọ to gba abẹrẹ ajẹsara naa gba a, lẹyin ti wọn ti ṣe wọn lọjọ si ibudo iyasọtọ ( Isolation centre).
Abẹrẹ naa ni a gbọ pe ajọ 'International Aids Vaccine Initiative', to wa fun aanu lo gbe e kalẹ.
Lọwọ yii, ko ti i si eto abẹrẹ ajẹsara kankan tijọba buwọlu lati tọju oriṣi Ebola ti wọn pe ni Sudan Ebola Virus yii.
Eyi ti a gbọ pe o wa, jẹ ti ilẹ Olominira Congo.
Àwọn àpẹẹrẹ àrùn Ebola
Lara awọn apẹẹrẹ ti eeyan yoo fi mọ pe oun ti lugbadi arun Ebola ni:
* Iba.
* Ko maa rẹ eeyan.
* Ara riro.
*Ori fifọ.
* Ki ọna ọfun maa dun eeyan.
*Ki eeyan maa bì.
*Igbẹ gbuuru.
*Kuruna lara.
Ki ẹjẹ maa jade lara eeyan, ki ẹjẹ mi-in si maa jade ninu ara lai foju han lode. (External and internal bleeding).
Bó ṣe ń lọ ní Uganda báyìí
Oriṣi Ebola ti a mọ si 'Sudan Ebola virus' yii lagbara pupọ.
O ti pa to ida ogoji ninu awọn to kọlu, gẹgẹ bi ajọ eleto Ilera Agbaye; World Health Organization (WHO), ṣe sọ.
Ni Uganda, igba kẹfa ree ti wọn yoo maa koju ikọlu arun Ebola.
Eeyan to le ni igba (234) ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe wọn yoo maa ṣọ bayii, ko ma jẹ pe wọn ti ni arun naa.
Ajọ eleto ilera lorilẹede Uganda lo fidi eyi mulẹ bẹẹ lọjọ Aje.
Bakan naa ni wọn ṣalaye pe wọn yoo fun ogoji eeyan to ti ni nnkan kan lati ṣe pẹlu ẹni to kọkọ kọlu, ni abẹrẹ yii.
Ajọ WHO, UN ati awọn alaṣẹ Uganda ni wọn yoo jọ ri si eyi, bi atẹjade naa ṣe sọ.
Oṣu Kẹsan-an ọdun 2022 ni wọn kede Ebola ni Uganda gbẹyin.
Eeyan to le aadọrin (70) lo si ba arun naa lọ.
Oṣu Kin-in-ni ọdun 2023 ni wọn kede pe o ti kasẹ nilẹ.
Lopin ọsẹ to kọja, abẹrẹ ajẹsara akọkọ to le ni ẹgbẹrun meji (2,160) lo de si olu ilu Uganda ti i ṣe Kampala.













