Ààrẹ àkọ́kọ́ ní Namibia, Sam Nujoma jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ààrẹ àkọ́kọ́ ní orílẹ̀ èdè Namibia, Sam Nujoma ti jáde láyé lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ́rùn-ún.
Ààrẹ Namibia, Nangolo Mbumba nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn ni òun fi kéde ikú Nujoma.
Mbumba ní láti bíi ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ni Nujoma ti wà ní ilé ìwòsàn tó ń gba ìtọ́jú àìsàn kan, tó sì jẹ́ pé àìsàn náà ló bá lọ.
Nujoma ló jà fún òmìnira Namibia lọ́wọ́ South Africa lọ́dún 1990 lẹ́yìn tó dá ẹgbẹ́ South West Peoples' Organisation (Swapo) lọ́dún 1960.
Lẹ́yìn tí orílẹ̀ èdè náà gba òmìnira, Nujoma di ààrẹ lọ́dún 1990 tó sì wà ní ipò náà títí di ọdún 2005.
Ààrẹ Mbumba ní Nujoma jẹ́ ìwúrí fáwọn láti dìde sí ojúṣe àwọn àti pé ó gbé ìgbé ayé tó rọrùn èyí tó fi sin àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè rẹ̀.
Nujoma, lẹ́yìn tó fi ipò ààrẹ sílẹ̀ lọ́dún 2005 tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí adarí ẹgbẹ́ Swapo títí di ọdún 2007.
Ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta ló lò lórí ipò adarí ẹgbẹ́ Swapo kó tó fi ipò náà sílẹ̀ lọ́dún 2007.
Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Keji, ọdún 2025 ni Nujoma jáde láyé.












