Àwọn kókó ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa abẹ́ dídá fún ọmọbìnrin

Obinrin kan pẹlu abẹ idabẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ni ọdun 2012 ni ajọ iṣọkan agbaye kede ọjọ kẹfa oṣu keji gẹgẹbi ọjọ gbigbogun ti abẹ dida fun awọn obinrin (FGM).

Idi ti wọn fi gbe igbesẹ yii wa lati tubọ tẹmpẹlẹ mọ awọn igbesẹ lati dẹkun igbesẹ naa.

Abẹ dida ni gige awọn ẹya ara kan ni oju ara obinrin fun awọn idi ti ko niiṣe pẹlu itọju aisan kankan.

Lagbaye, wọn ti ka eyi kun ara awọn igbesẹ to tapa ẹtọ awọn ọmọbinrin ti wọn ba ṣe iru rẹ fun.

Ajọ iṣọkan agbaye sọ pe abẹ dida fun ọmọbinrin le ṣakoba fun oju-ara rẹ, koda o le yi pada.

Iwadi ajọ iṣọkan agbaye sọ pe awọn ọmọbinrin to le igba miliọnu ti wọn si wa laaye bayi ni wọn ti dabẹ fun.

Gẹgẹ bi Iwadi naa tun ṣe sọ, aṣa abẹ dida yii wọpọ ni bi ọgbọn lorilẹede, ṣugbọn kii ṣe ilẹ adulawọ ni gbogbo wọn wa.

Awọn koko ohun to yẹ ki o mọ nipa abẹ dida fun awọn obinrin niyi:

  • Lọdun 2025, miliọnu mẹrin o le ẹgbẹrun lọna irinwo lawọn ọmọbinrin ti o ṣeeṣe ki wọn dabẹ fun; eyi tum si ẹgbẹrun mejila o le igba mbinrin ti wọn le maa dabẹ fun lojumọ.
  • Laarin asiko yii ati ọdun 2030 tiiṣe ọdun marun un si asiko yii, iye awọn ọmọbinrin ti wọn yoo ti dabẹ fun yoo ti to ẹgbẹrun mẹtadinlọgbọn.
  • Iye owo ti wọn n na fun itju awọn ọmọbinrin ti wọn da abẹ fun lagbaye ti wọ biliọnu kan ati irinwo miliọnu dọla lọdun, U$1.4bn.
  • Igba o le ọgbọn miliọnu ọmọbinrin lo ti ko sọwọ abẹ dida lagbaye, to si ti n fa ọpọ inira fun wọn.
  • Ilẹ Afirika ni ọwọja ipenija abẹ dida fun ọmọbinrin pọ ju si lagbaye.
  • Miliọnu mẹrinlelogoje Ọmọbinrin ni wọn n dabẹ fun ni Afrika.
  • Ọgọrin miliọnu obinrin ni wọn ti dabẹ fun ni Aṣia.