Uganda FGM: 'Ìdí tí mo fi lọ d'ábẹ́ lòdì sí òfin'

Abẹ dida fun obirin paapa fun ẹni to ba ti gbọnju dagba a ma mu ẹru wa.
Ṣugbọn lọdọ arabirin kan lorileede Uganda, ifẹhonu han si ijọba lo sọ wi pe o mu ki oun jọwọ ara rẹ fun abẹ dida.
Sylvia Yeko pinu funra rẹ lati da abẹ eyi ti awọn oloyinbo n pe ni Female Genital Mutilation ni ọsẹ mẹta sẹyin nigba to pe ọmọọdun mẹrindinlọgbọn.
Aṣa yii ti wọn maa n ṣe e fun awọn ọdọ langba to jẹ ọmọbinrin lorileede Uganda ṣugbọn wọn ti fi ofin de lati ọdun 2010.
Nita gbangba ni wọn ti ṣe ayẹyẹ abẹ dida rẹ ti o si fi fọnran fidio ti wọn ya nipa rẹ han wa.
Ninu fọnran naa, awọn eeyan n daraya ti wọn si rọ yika Yeko ati obinrin miiran.
Wọn fi iyẹfun ra awọn mejeeji loju. Lori koriko nita lawọn mejeeji dubulẹ si ti obirin kan si ya ẹsẹ wọn ki o to ge ẹran ara ibi nkan ọmọbinrin wọn kuro.
Ko si ẹni to kigbe ninu wọn nitori pe ẹkun kike lodi si aṣa wọn nipa eto ti obirin gbọdọ ṣe ki o to lọ ile ọkọ lagbegbe yii to wa ni ariwa Uganda.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Abilekọ Yeko sọ fun BBC bi o ti ṣe n tun fọnran fidio naa wo pe"niṣe ni inu mi kan n dun lọjọ naa''
"Oju ọmọde ni wọn fi n wo mi ki n to dabẹ amọ bayi ti mo ti ṣee, mo ti di ẹni apọnle''
Ipinu lati gba ki wọn da abẹ fun un
Yeko mọ wi pe oun le ṣẹwọn to to ọdun marun un fun abẹ dida ṣugbọn o ni oun ko bikita bi awọn agbofinro ba mọ.
Awọn ti wọn jijọ ṣiṣẹ abẹ naa le fẹwọn ọdun mẹwa jura bakan naa.

Lati ọṣu kejila ọdun to kọja, irufẹ ayẹyẹ abẹ dida bayii ti waye lagbegbe Sebei lariwa Uganda-pupọ waye ni adugbo Kween eleyi to sunmọ ibode ilu Kenya.
Awọn eeyan mẹta kan ti fẹwọn gbara fun aṣa abẹ dida yii to fi mọ ọmọbirin ọdun mẹẹdogun kan ati obirin mii. Eeyan mọkandilogun lo wa ni atimọle ti wọn n reti idajọ lori pe wọn kopa ninu aṣa yii.
Abẹ dida a ma da ẹmi legbodo. Ewu to wa nibẹ a maa ṣẹlẹ ti ẹjẹ ba kọ lati da latara abẹ dida.
Kokoro a tun maa wọ inu egbo naa. Ninu fọnran fidio ti a wo, iyẹfun lasan ni wọn gbọn si oju ara awọn ti wọn dabẹ fun ko si daju wi pe wọn lo abẹ ọtọọtọ fi d'abẹ fun wọn.
Aburu ti o ma n sẹlẹ ni ki apa oju abẹ naa ko inira ba ẹni ti wọn dabẹ fun tabi ki o ko inira ba wọn ti wọn ba fẹ bimọ.
Toun ti gbogbo nnkan ti a ka silẹ wọnyii, Yeko ti di ilumọọka ni Sebei-nigba ti a bi leere pe kini ero rẹ nipa awọn ọmọbirin kekeeke ti wọn wo awokọṣe rẹ, o ni ohun ko ri nnkan to buru ninu abẹ dida.

Kini itumọ abẹ dida fun awọn obirin?
- Abẹ dida ni ṣe pẹlu gige diẹ tabi gbogbo oju ara obinrin fun idi ti ko ni ṣe pẹlu ilera rẹ
- O to orileede ọgbọn nilẹ lafrika ti aṣa yi ti gbode ati ni awọn orileede miran ni ilẹ Asia ati ilẹ larubawa
- O to miliọnu mẹta ọmọdebinrin ati obinrin to wa ninu ewu aṣa yi lagbaye lọdọọdun
- Wọn a ma saba da abẹ fun awọn ọdọbirin lati igba ti wọn wa ni ikoko titi di ọdun mẹẹdogun
- Aṣa ati iṣẹṣe to ri abẹ dida gẹgẹ bi ohun to yẹ lati ma jẹ ki obinrin ṣe iṣekuṣe lo ma n mu kiawọn eeyan kopa ninu abẹ dida
- Ninu ewu to so mọ abẹ dida la ti ri kiẹjẹ ma da loju ara,inira lati tọ, kiko kokoro aifoju ri,airọmọbi ati isiro nipa ọmọ bibi ati iku ikoko.
Orisun: Ajọ isọkan agbaye

Lọdọ Yeko, aṣa abẹ dida kii ṣe aṣa nikan bi kii ṣe ọna tirẹ lati koju ijọba ti o ni wọn kọ lati mu ileri ti wọn ṣe pe awọn yoo ṣe idanilẹkọ fun awọn obinrin ati mimu agbega ba awọn obinrin lẹyin ti wọn fofin de aṣa abẹ dida.
Awọn ti wọn wa ni awọn agbegbe ti oṣi pọ si wọnyii ti ireti wa wi pe ijọba yẹ ki wọn pese ohun amayederun fun ti wọn ba jawọ kuro ninu abẹ dida.

Ki ọrọ naa ba le yewa daada, abilekọ Yeko mu wa lọ si ile iwe girama fun awọn obinrin Kwosir Girl's Boarding Secondary School nibi ti a ti ri patako kan ti wọn kọ ileri aarẹ orileede lati mu opin ba abẹ dida.
O ni toun ti bi wọn ti ṣe kọ ileewe naa lẹyin ti wọn fi ofin de abẹ dida, kii ṣe gbogbo ọmọbirin lo laanfaani lati kẹkọ nibẹ ti iye owo ile ẹkọ naa gunpa fun ọpọ lagbegbe naa.
Yeko so pe "Ki wọn fọwọ di ileewe wọn mu nitori ko si anfaani kankan ti a n ri nibẹ''

Agbegbe Kween wa lara awọn agbegbe ti ko ṣe daada to nipa eto ẹkọ.
Gẹgẹ bi ohun ti a ri ka ninu iroyin ti ijọba ko jọ, nnkan bi ẹgbẹrun mẹfa akẹkọ ni wọn maa n forukọsilẹ nile ẹkọ alakọbẹrẹ ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi de ile ẹkọ girama, wọn kii ju igba lọ ti o ma n ṣẹku ni kilasi.
Abilekọ Yeko ni oun gbiyanju lati kawe pari amọ bi awọn eeyan pupọ lorileede Uganda,ko ti ri iṣẹ.

O tẹsiwaju pe nnkan to mu oun kopa ninu abẹ dida naa ko ju wi pe oun fẹ fi ẹhonu han si bi ijọba ko ṣe kọbi ara si ọrọ ara ilu.
Koda o kọ iwe si ọga ọlọpaa saaju ayẹyẹ idabẹ rẹ ki wọn baa le mọ nipa igbesẹ rẹ.
'Wọn n foju ọmọde wo wa'
Obinrin miiran kan to ba BBC sọrọ ni ohun nikan loun le salaye ipinu to mu ki oun gba ki wọn dabẹ fun oun.
Obinrin naa ti ko fẹ ki wọn darukọ rẹ ni laarin awọn eya Sabiny ti oun ti wa, wọn n dẹyẹ si oun ti wọn ko si gba oun laaye lati ṣe awọn nkankan nitori pe oun ko tii dabẹ.

"Ni Sebei, obinrin ti ko ba ti d'abẹ ko le bawọn ṣiṣẹ ajumọṣe tabi ko ba wọn ko bọtọ''
Isẹ fifi bọtọ kun ile jẹ iṣẹ ti wọn ya sọtọ fun awọn obinrin.
O ni "Okunrin le fẹ iyawo mii ti oun ti da'bẹ ti wọn a si maa fi eleyi bu ẹni ti ko tii da'bẹ pe ọmọde ṣi ni''
Amọ ṣa obinrin naa to ti bi ọmọ mẹta ni ohun ko lero lati da abẹ fun awn ọmọ rẹ ti o si ni igbagbo wi pe wọn yoo kawe lọjọ iwaju.














