Circumcision: Àwọn ọ̀dọ́ kán lugbó nítorí ìbẹ̀rù kí wọ́n má dá abẹ́ fún wọn

Bukusu circumcision ceremony in Kenya

Ṣaaju ayẹyẹ dida abẹ f'ọkunrin ni awọn ọkunrin kan ni Kenya ti bẹrẹ si n kan lu igbo bayii lẹyin ti awọn kan n fi ipa dá abẹ́ fun wọn eyi ti Yoruba tun maa n pe ni kikọ ni ni ila.

Awọn ọkunrin naa gbe igbesẹ yii lẹyin ti awọn ọdọ kan lati ẹya Bukusu fi tipatikuuku dá abẹ́ fun okunrin mẹjọ.

Gbogbo inu oṣu Kẹjọ ọdun ni awọn ẹya naa maa ṣe ayajọ ọdun ila kikọ.

Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe gbogbo ẹya to wa ni Kenya lo n kọ ila tabi dá abẹ́ fun awọn ọkunrin, amọ ila kikọ fun awọn okunrin jẹ ọna ti wọn fi n sami si pe wọn ti n kuro ni ọmọde si okunrin.

Akọroyin BBC to ṣabẹwo si agbegbe Moi's Bridge ti iṣẹlẹ naa ti waye, Odeo Sirari sọ pe awọn ẹya Bukusu ati Kalenji lo pọju nibẹ ti wọn si gbagbọ ninu dá abẹ́, amọ awọn ẹya miran wa nibẹ pẹlu.

Lati nnkan bii ọdun mẹwaa sẹyin ni awọn ọdọ Bukusu ti n fi agidi kọ ila fun awọn ọdọkunri lati awọn agbegbe bii Turkana, Teso ati Luo.

Lọpọ igba, ni ṣe ni wọn maa n ki awọn ọdọ naa mọle lẹba ọna, ti wọn a si dá wọn l'ábẹ́.

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

Inu igbo ni ọpọ wọn n sun

Ọkan lara awọn ti wọn dá abẹ́ fun, Peter Loituktuk, to jẹ ọmọ ẹya Turkana sọ pe pẹlu ibẹrubojo ni oun n gbe bayii nitori ila naa.

Ẹlomiran to ba BBC sọrọ ni "Mọ n lọ si igboro lọjọ kan ni mo dede ri awọn eeyan kan ti wọn ki mi mọlẹ"

"Wọn gba kẹkẹ mi, wọn si fi agidi dá abẹ́ fun mi."

Peter Loituktuk

Peter Loituktuk ṣalaye fun BBC pe ọpọ awọn ọdọkunrin lo n sun ninu igbo bayii lọna ati yẹba fun awọn Bukusu to ndá abẹ́ ọhun.

Amọ akọroyin BBC jabọ pe awọn adari awọn eeyan Bukusu naa ti sọ pe irọ patata ni iroyin naa, ati pe awọn ko fi agidi kọ ẹnikẹni ni ila.

Wọn ni "A ko fi agidi dá abẹ́ fun ẹnikẹni, ti awọn kan ba n ṣe bẹẹ , ko bojumu."