Baba Ijesha: Adájọ́ sún ìgbẹ́jọ́ síwájú lẹ́yìn tí Baba Ijesha ro tẹnu rẹ̀

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, @BolanleCole

Adájọ́ ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìfìyàjẹni àti ìbálòpọ̀ tó wà ní Ikeja nílùú Eko, Toyin Taiwo tún ti sún ìgbẹ́jọ́ òṣèré tíátà James Olanrewaju tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Baba Ijesha sí ọjọ́ kọkànlá, oṣù tí a wà yìí.

Níbi ìgbẹ́jọ́ naa tó wáyé lónìí, ilé ẹjọ́ fún Baba Ijesha ní ànfààní láti ro tẹnu rẹ̀ lórí ẹ̀sùn ìfipábá ọmọdé lò lọ́nà àìtọ́ tí wọn fi kàn án.

Lára àwọn ọ̀rọ̀ tó bá ilé ẹjọ́ sọ, Ijesha ṣàlàyé pé nǹkan tó wà nínú fọ́nrán CCTV tí àwọn èèyàn wò kìí ṣe bí àwọn èèyàn ṣe rò nítorí pé àwọn ń ṣe eré orí ìtàgé lásán ni.

O fi kun pe gbogbo nǹkan tí òun ṣe nínú fọ́nrán ọ̀hún kò ṣẹ̀yìn Princess tó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí adárí nínú eré tó ní kí òun wá kópa níbẹ̀.

Ijesha tún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ pé, ṣàdédé làwọn géndé okùnrin bíi mẹ́jọ yọ dé pẹ̀lú Princess lọ́jọ́ náà lọ́hùn tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí na òun kó tó dí pé wọ́n pé ọlọ́pàá.

Lẹ́yìn tó ro tẹnu rẹ̀ tàn, ọ̀kan lára àwọ̀n agbẹjọ́rò olùpẹ́jọ́ ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò 'Cross examination' pẹ̀lú Ijesha kó tó wá di pé adájọ́ sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ kọkànlá oṣù tí a wà yìí.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Òní ní Baba Ijesha tún fojú ba iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn bíbá ọmọdé lòpọ̀

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, @Others

Òní lòní ń jẹ́ ẹni abẹ̀ lọ́wẹ̀, ìgbẹ́jọ́ Gbajúgbajà òṣèré tíátà, James Olanrewaju tí gbogbo ènìyàn sí Bàbá Ijesha yóò tún tẹ̀síwájú lónìí ọjọ́ kẹrin oṣù kẹta, ọdun 2022.

Ní ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìfìyàjẹni àti ìbálòpọ̀ tó wà ní Ikeja, ìpínlẹ̀ Eko ni ìgbẹ́jọ́ náà ti ń wáyé.

Níbi ìgbẹ́jọ́ tó kọjá ní Adájọ́ Taiwo Taiwo ti sún ìgbẹ́jọ́ náà sónìí ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹta.

Kí ló ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Nínú oṣù kẹrin, ọdún 2021 ni gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú Princess fẹ̀sùn kan Baba Ijesha pé ó bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tó ń gbé lọ́dọ̀ òun sùn.

Oṣù méjì ni Baba Ijesha lò ní àtìmọ́lé kí wọ́n tó gba ìdáǹdè rẹ̀ nínú oṣù kẹfà.

Àkọlé fídíò, Láti sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine

Ẹ̀sùn bíbá ọmọdé ní ìbálòpọ̀ àti ẹ̀sùn márùn-ún mìíràn tó jọ mọ́ bíbá ọmọdé lájọṣèpọ̀ ni Bàbá Ijesha ń kojú ní ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìfìyàjẹni àti ìbálòpọ̀ tó wà ní Ikeja, ìpínlẹ̀ Eko.

Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Baba Ijesha yìí fa awuyewuye lágbolé tíátà.

Àkọlé fídíò, A lè pe Oluwo ní Ọba ìgbàlódé kìí ṣe Ọba ìtalẹ̀mu

Kíló ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ nibi igbejo tó kọjá?

Ajẹ́rìí Bàbá Ijesha sọ fún ilé ẹjọ́ pé òun ò gbà pé fọ́nrán tí wọ́n fi léde kìí ṣe èyí tí wọ́n ti tọwọ́ bọ̀.

Gbajúgbajà òṣèré tíátà, James Olanrewaju tí gbogbo ènìyàn sí Bàbá Ijesha ti ní òun kò gba pé àkóónú tó wà nínú fọ́nrán CCTV tí wọ́n gbé wá sílé ẹjọ́ tako òun jẹ́ òótọ́.

Àkọlé fídíò, Àwọn òbí mi rò pé ẹ̀jẹ́ ti ta sí ọpọlọ mi nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ba ẹranko igbó ṣọ̀rẹ́

Elẹ́rii Bàbá Ijesha tó jẹ́ onímọ̀ nípa ṣíṣe àtúnṣe àti fífi ẹ̀rọ CCTV sílé, Adeleke Lawrence sọ èyí nílé ẹjọ́ lánàá nígbà tó ń fèsì sí ìbéèrè tí agbẹjọ́rò Bàbá Ijesha, Babatunde Ogala (SAN) bèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

Fọ́nrán mẹ́rin tó ṣàfihàn ohun tó ṣẹlẹ̀ lórí ẹ̀sùn bíbá ọmọdé lòpọ̀ tí wọ́n fi kan Bàbá Ijesha ni Ogala bèrè fún láti wò.

Àkọlé fídíò, Uber Lady: Bùkátà pọ̀ lọ́rùn mi ní mo ṣe ń wa taxi akérò

Nínú oṣù kẹrin, ọdún 2021 ni gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú Princess fẹ̀sùn kan Baba Ijesha pé ó bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tó ń gbé lọ́dọ̀ òun sùn, tó sì fi àwọn fọ́nrán mẹ́rẹ́ẹ̀rin náà lédé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí.

Àkọlé fídíò, Láti sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn fọ́nrán náà, ajẹ́rìí Baba Ijesha ní Adeleke ní kí ènìyàn tó le kó fọ́nrán tó wà lórí CCTV sí ibòmíràn, èèyàn nílò ẹ̀rọ kọ̀mpútà àti ẹ̀rọ ìkóǹkanpamọ́sí.

Adeleke ṣàlàyé pé lásìkò tí ènìyàn bá ń ṣe èyí àṣìṣe le wáyé , tí ènìyàn sì tún le ṣe àyípadà sí àwọn àkóónú inú rẹ̀.

Ó ní ó dá òun lójú pé wọ́n ti ṣe àyípadà sí àwọn àkóónú inú fọ́nrán náà èyí ló fà á tó fi ń sáré ju bó ti yẹ lọ.

Bákan náà ló fi kun pé àmì "ins" tó wà lábẹ́ fọ́nrán náà ni àmì ìdánimọ̀ "In Shot" áàpù kan tó wà fún ṣíṣe àtúnṣe àti àyípadà fọ́nrán.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní ẹ̀rọ alágbéká fóònù tàbí camcoder ni wọ́n ló láti fi ya fọ́nrán ifọrọwanilẹnuwo ni ago olopaa kìí ṣe CCTV nítorí bí àwòrán fọ́nrán náà daa ju ti foonu lọ.

Ṣùgbọ́n ó gbà pé àkóónú CCTV kò ṣé ṣe àyípadà sí tí wọ́n bá lò ó papọ̀ mọ́ Network Video Recording (NVR) àti (IP) gẹ́gẹ́ bí Dókítà Jide Martins tó peja ṣe sọ.