Sunday Igboho kò tíi gba ìtúsílẹ̀ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n Benin Republic - Yomi Alliyu

Oríṣun àwòrán, Igboho
Agbẹjọro oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti sọrọ lori iroyin to n lọ ni igboro pe ajijagbara naa ti gba itusillẹ.
Ọkan lara awọn agbẹjọro rẹ, Yomi Alliyu, SAN, ti sọ pe Igboho ṣi wa ni ahamọ orilẹ-ede Benin Republic tako ọrọ to n lọ ni igboro.
Ninu atẹjade kan lori ayelujara lo ti sọ ọrọ naa.
- Ilé ẹjọ́ fi Rahman Adedoyin pamọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe bẹ̀rẹ̀ l'Osun
- Ọmọ ọdún 15 tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó bá ọmọ ọdún mẹ́jọ lòpọ̀ fojú balé ẹjọ́ l'Eko
- Ìjọba àpapọ̀ fún Amẹ́ríkà láṣẹ láti gbé Abba Kyari fún ìgbẹ́jọ́
- Kíni ó wà nínú lẹ́tà tí ọkùnrin tí wọ́n bá òkú rẹ̀ pẹ̀lú obìnrin kan nínú mọ́tò kọ sí aya rẹ̀?
- Ìdí tí mi ò fi kópa níbi ìpàdé ìpẹ̀tùsááwọ̀ láàárín èmi àti Aregbesola nìyìí – Tinubu
- MC Oluomo, ilá rẹ fẹ́ máa ga ju onírè lọ - NURTW
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní Ukraine yóò máa dé láti òní lọ- Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè
- Wo iye èèyàn Ukraine àti àjòjì tó ti kú láti ìgbà tí Russia ti gbógun ti Ukriane
- kí ló ń fa rúgúdù láàrín ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo àti àjọ EFCC
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ko si ootọ kankan ni iroyin ti awọn kan ti n gbe kiri pe Igboho ti gba itusilẹ.
O ni "Lori ọrọ to n lọ laarin ilu pe wọn ti fi Igboho silẹ."

Oríṣun àwòrán, Anike Iyaniwura TV
"Ẹ jọwọ ẹ maṣẹ gba iroyin naa gbọ tabi pe o ti n tẹkọ leti lọ si orilẹ-ede Germany, ko si ohun to jọ bẹẹ."
"Lootọ ni iṣẹ ti n lọ lọwọ pẹlu ifọwọsowọpọ Ọjọgbọn Akintoye atawọn agbẹjọro mii bii Falola lori bii nnkan yoo ṣe rọ lọrun fun un, yatọ si inu ọgba ẹwọn to wa."
Agbẹjọro naa pari ọrọ rẹ pe ki awọn ololufẹ Igboho lọ fi ọkan wọn balẹ ki wọn si maa fi adura ṣọwọ si Igboho nibi to wa.

Oríṣun àwòrán, Anike Iyaniwura TV
Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ:
Ti ẹ ko ba gbabe, nnkan bii aago kan oru ni DSS kọlu ile Igboho to wa lagbegbe Soka, niluu Ibadan, iyẹn lọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun to kọja.
Ikọlu naa lagbara to bẹẹ ti ẹmi eeyan meji sọnu, nigba ti wọn fi ṣikun ofin mu awọn mejila miran, amọ Igboho moribọ.
Ẹwẹ, lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2021 kan naa ni Igboho ti wa lọgba lorilẹ-ede Cotonou, ti ijọba orilẹ-ede naa ko si fi ẹsun kankan kan an.














