Russia and Ukraine Nigerians update: ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní Ukraine yarí pé àwọn kò fẹ́ wálé mọ́

Oríṣun àwòrán, Twitter/NIDCOM
Awon omo Naijiria ti n de lati orile ede Ukraine bayii.
Lara awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria to wa ni Ukraine ti gunlẹ sorilẹ ede Naijiria lowurọ yii

Abike Dabiri to n dari ajo to n risi ọ̀rọ̀ awọn ọmọ Naijiria to ngbe ilẹ̀ okeere, Abike Dabiri sọ pe awon to ti de naa ti so pe wọ́n ti de sile Naijiria layo ati alaafia.
ọmọ Naijiria to ngbe ilẹ̀ okere, Abike Dabiri sọ pe
Dabiri salaye pe lati orilẹ̀ ede Romania ni àwọn eniyan naa ti de
Ati pe, ni nnkan bi aago meje owro kọja iṣẹju mẹ́waa ni wọn balẹ̀ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe, Abuja.
Bakan naa lo so pe wọn si n reti ikọ̀ meji omiran lati de sile baba wọn lonii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
- Àjọ̀dún Lisabi Agbongbo Akala tọdún 2022 ti bẹ̀rẹ̀ ní Abeokuta
- Ibá Lassa fojú hàn ní ìpínlẹ̀ Oyo, ó ti mú ẹ̀mí Dókítà méjì lọ
- Bàbá Adesola Adedeji, ọ̀kan lára àwọn afurasí méje ń fẹ́ rọ́pò ọmọ rẹ̀ nínú ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke
- Ibá Lassa fojú hàn ní ìpínlẹ̀ Oyo, ó ti mú ẹ̀mí Dókítà méjì lọ
- Kíni àjọ ECOWAS ilẹ̀ Adúláwọ̀ ń sọ báyìí lórí ìjà Russia àti Ukraine?
- Òní ní Baba Ijesha tún fojú ba iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn bíbá ọmọdé lòpọ̀
- Ìdí tí mo ṣe fẹ́ yọ ayédèrú ìdí ńlá tí mo ní- Sophie
- Ọmọ ọdún 15 tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó bá ọmọ ọdún mẹ́jọ lòpọ̀ fojú balé ẹjọ́ l'Eko

Oríṣun àwòrán, Punch
Àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní Ukraine yóò máa dé láti òní lọ- Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè
Ìjọba àpapọ̀ ti ní àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó há sí orílẹ̀ èdè Ukraine yóò máa wọ orílẹ̀ èdè yìí láti ọ̀la lọ bí àwọn ọkọ̀ òfurufú tí yóò máa gbé wọn ṣe ti ń gbéra láti òní.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ akọ̀wé àgbà ilé iṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè, Gabriel Aduda lórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter ní àwọn ti ní àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó ti sá sí àwọn orílẹ̀ èdè bíi Romania, Hungary, Poland àti Slovakia.
Aduda ní àwọn ọkọ̀ òfurufú Max Air tí yóò máa kó àwọn ènìyàn 560 kúrò ní Romania, Airpeace yóò lọ Poland lati kó àwọn ènìyàn 364 àti àwọn 360 ènìyàn ní Hungary.
- Wo àwọn àtúnṣe tí àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lù sí ìwé òfin Nàìjíríà
- Ṣé lóòtọ́ ni pé Russia yóò kógun ja Naijiria àti pé ọmodébìnrin Ukraine gbéná wojú ọmọ ogun Russia?
- Ìwà àìlajú ní Russia hù bó ṣe kọlu ọ̀wọ̀n ìràntí ìṣekúpani - Ukraine
- Wo àwọn àtúnṣe tí àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lù sí ìwé òfin Nàìjíríà
- Ọkùnrin kan dágbére fáyé lẹ́yìn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀
- Wo àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ṣàtìlẹyìn fún Russia àti àwọn tó wà lẹ́yìn Ukraine
- Wo àwòràn ohun tó sẹlẹ̀ ní UKraine
- Kí ló dé tí Esabod àti Lizzy Anjorin fi ń ṣépè fúnra wọn?
Àtẹ̀jáde ọ̀hún fi kun pé ní ọ̀la ni ìrètí wà pé àwọn ènìyàn náà yóò balẹ̀ sí Nàìjíríà.
Bẹ́ẹ̀ náà ló tẹ̀síwájú pé àwọn yóò sa gbogbo ipá àwọn láti ri dájú pé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà padà sílé láyọ̀.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Àwọn ọmọ Nàìjíríà kò fẹ́ padà sílé:
Ẹ̀wẹ̀, Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, Geoffrey Onyema ti ni àwọn ọmọ Nàìjíríà kan tó wà ní orílẹ̀ èdè Ukraine tí Russia ń gbógun kọlù kò fẹ́ kúrò ní orílẹ̀ èdè náà padà wálé.
Onyema sọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń bá Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin, Femi Gbajabiamila ṣe ìpàdé.
Ó ní lónìí ni àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ síní kò àwọn ènìyàn tó ṣetán láti padà sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Bakan náà ló fi kun pé gbogbo jíjẹ àti ibùgbé àwọn tó ti sá kúrò ní Ukraine bọ́ sí àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ni àwọn ń gbọ́ títí àwọn yóò fi kó wọn wálé.















