Ọmọ ọdún 15 fojú balé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó bá ọmọ ọdún mẹ́jọ lòpọ̀

Rape

Oríṣun àwòrán, thesetimesmedia

Ọmọ ọdun marundinlogun kan ti kawọ pọn rojọ niwaju adajọ Majistreeti kan niluu Eko lori ẹsun pe o fọwọ kan ọmọ ọdun mẹjọ lọna ti ko tọ.

Ileeṣe ọlọpaa gbe ọmọ naa lọ sile ẹjọ lori ẹsun ibalopọ lọna aitọ.

Ọlọpaa to n ṣe ẹjọ ọhun, ASP Akpan Nko ṣalaye fun ile ẹjọ naa pe afurasi wu iwa ọdanran naa lọjọ kẹsan an, oṣu Keji, ọdun 2022 ni adugbo Oladejo, ni Araromi, Badagry, nipinlẹ Eko.

Nko ni afurasi naa ba ọmọ ọdun mẹjọ ọhun ni ibalopọ.

O ṣalaye pe iya ọmọ ọdun mẹjọ naa lo fi ọrọ ọhun sun ni agọ awọn.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, iwa ti afurasi na wu lodi si abala 137, 170 ati 261 ninu iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko ti wọn gbe kalẹ lọdun 2015.

Àkọlé fídíò, Láti sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine

Adajọ ile ẹjọ naa, Patrick Adekomiya, gba beeli afurasi naa pẹlu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ati oniduro meji.

O ni ọkan lara awọ oniduro naa gbọdọ jẹ baba to bi afurasi ọhun.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2022, ki igbẹjọ naa le bẹrẹ ni pẹrẹwu.

Àkọlé fídíò, Bíbọ Ajé máaa ń mú kí ènìyàn gbèrú lẹ́nu iṣẹ́ àti okoòwò