ASUU Strike 2022: Aàrẹ ASUU, Emmanuel Osodeke ti ní ASUU kò ní kópa nínú ṣíṣe ìdúnàádúrà pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ kankan mọ́ lórí àdéhùn ọdún 2009

Oríṣun àwòrán, Others
Egbẹ́ olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, ASUU si wa lenu iyanselodi olosu kan ti wọ́n fi n se ikilo fun ijoba Naijiria.
Lójúnà àti wá ojútùú sí ìyanṣẹ́lódì tí àwọn ẹgbẹ́ olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, ASUU ń fi gbogbo ìgbà gúnlè, ìjọba àpapọ̀ ti gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méje kan dìde láti jíròrò pẹ̀lú ASUU lórí àdéhùn ọdún 2009.
Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́, Mallam Adamu Adamu tó ṣàgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ yìí ní ó jẹ́ ọ̀nà láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín ASUU àti ìjọba àpapọ̀.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Emeritus Nimi Briggs ni yóò jẹ́ alága ìgbìmọ̀ náà.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde láti ilé iṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́, ọjọ́ Ajé ọjọ́ keje, oṣù kẹta ni wọn yóò ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ náà.
Lẹ́yìn ọdún mẹ́tàlá ìjọba àpapọ̀ yan ìgbímọ̀ ẹlẹ́ni méje láti jíròrò pẹ̀lú ASUU lórí àdéhùn 2009
- Ìdí tí mi ò fi kópa níbi ìpàdé ìpẹ̀tùsááwọ̀ láàárín èmi àti Aregbesola nìyìí – Tinubu
- Ìjọba àpapọ̀ fún Amẹ́ríkà láṣẹ láti gbé Abba Kyari fún ìgbẹ́jọ́
- Ilé ẹjọ́ fi Rahman Adedoyin pamọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe bẹ̀rẹ̀ l'Osun
- Ṣé lóòtọ́ ni Sunday Igboho ti gba ìtúsílẹ̀ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n Benin Republic?
ASUU ti fọnmu fun ijoba Naijiria:
Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, ASUU ti ní àwọn kò ní kópa nínú ṣíṣe ìdúnàádúrà pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ kankan mọ́ lórí àdéhùn ọdún 2009.
Ààrẹ ASUU Ọ̀jọ̀gbọ́n Emmanuel Osodeke ní àwọn ti parí ìjíròrò lórí àdéhùn náà, fún ìdí èyí àwọn kò ní nǹkan tí àwọn fẹ́ bá ìjọba sọ lórí rẹ̀ mọ́.
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?
Ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ilẹ̀ Nàìjíríà, ASUU, tún kọ̀ láti forí ìkòkò sọ̀ọ́dún bí ìpàdé wọn í wọ́n ṣe ní ìrọ̀lẹ́ àná ṣe forí sọ́pọ́n.
Ikọ̀ aṣojú ìjọba àpapọ̀ tí Mínísítà fọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́, Chris Ngige darí níbi ìpàdé náà kò ríbi pẹ̀tù sí àwọn olùkọ́ náà láti ṣéwélé ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n gùnlé.
Ngige ní òun ní ìrètí pé ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín àwọn àti ASUU yóò wá sópin láìpẹ́.
Ìpàdé kejì rèé tí ẹgbẹ́ ASUU àti ìjọba àpapọ̀ yóò ṣe láti ìgbà tí ASUU ti bẹ̀rẹ̀ ìyansẹ́lódì oníkìlọ̀ oṣù kan ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì, ọdún 2022.

Oríṣun àwòrán, others
Àwọn aṣojú ASUU ní àwọn kò ṣetán láti buwọ́lu ìwé àdéhùn kankan pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ mọ́ àfi kí ìjọba ṣ gbogbo ohun tí àwọn ti jọ ṣàdéhùn lé lórí tẹ́lẹ̀.
- Wo àwọn àtúnṣe tí àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lù sí ìwé òfin Nàìjíríà
- Àwọn agbébọn yabo ibi ètò ìgbéyàwó, jí ìyàwó gbé lọ
- Wo àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ṣàtìlẹyìn fún Russia àti àwọn tó wà lẹ́yìn Ukraine
- Kíní ìtumọ̀ àyájọ́ Ọ̀jọ ''Ash Wednesday' tó wáyé lóní?
- Ṣé lóòtọ́ ni pé Russia yóò kógun ja Naijiria àti pé ọmodébìnrin Ukraine gbéná wojú ọmọ ogun Russia?
- Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà míì ti jáde láyé
- Ìlù ti yí, orin ti séńjì! Ẹni tí yóò jẹ Olubadan yóò ní àmúyẹ tuntun - Ìgbìmọ̀ Olubadan
- Omoyeni rí ẹ̀wọ̀n he fẹ́sùn fífi abẹ ya ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lára
Ijoba Naijiria ati egbẹ́ awọn Oluko Fasiti yoo se ipade loni lori ọ̀rọ̀ iyanselodi wọ́n
Lónìí, ọjọ́ kìíní, oṣù kẹta, ọdún 2022 ni ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ASUU yóò tún ṣèpàdé láti jíròrò láti wá ojútùú sí ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín àwọn méjéèjì lórí ìyanṣẹ́lódì tí ASUU gùnlé.
Ìpàdé tòní ni ó jẹ́ ìtẹ̀síwájú lórí gbogbo àwọn ìfẹnùkò wọn níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́sẹ̀ tó kọjá.
Ààrẹ ẹgbẹ́ ASUU, Ọ̀jọ̀gbọ́n Emmanuel Osodeke ní òun gba ìpè ìjọba àpapọ̀ lánàá láti tún pàdé fún ìjíròrò lónìí.
Osodeke ní òun kò rò wí pé àwọn ń tẹ̀síwájú bó ṣe jẹ́ pé gbogbo ìjíròrò àwọn kò ì tíì so èso rere láti ìgbà tí àwọn ti gùnlé ìyanṣẹ́lódì.
- Ta ni Ajé tí àwọn ọmọ Yorùbá lágbáyé ń ṣọdún rẹ̀ ní Ile Ife lónìí?
- Àwọn agbébọn rọ́jò ìbọn fún Ọba aládé l'Ekiti, ó dèrò ilé ìwòsàn
- Ilé ẹjọ́ ju Mínísítà sẹ́wọ̀n ogún ọdún fún ìwà àjẹbánu
- Àwọn agbébọn yabo ibi ètò ìgbéyàwó, jí ìyàwó gbé lọ
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Ọmọ ọdún méjìdínlógún jí ènìyàn gbé
- Kí ló wáyé níbi ìpàdé NANS àti ìjọba àpapọ̀? àlàyé rèé
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ tí Mínísítà fọ́rọ̀ òṣìṣẹ́, Chris Ngige sọ wí pé ìjọba ò le ṣe ẹ̀kúnwó owó olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ fásitì lásìkò yìí, Osodeke ní ìjọba àpapọ̀ kò ṣe òótọ́ pẹ̀lú àwọn.
Ó ní bí Ààrẹ bá le buwọ́lu ẹ̀kúnwó àwọn ọlọ́pàá àti ti àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama, tí àlékún tún bá owó ìrìnà àwọn ìjọba kò sí ohun tó ní kí ìjọba má lè ṣe àlékún owó oṣù àwọn náà.
Bákan náà ló fi ìkọnilóminú hàn pé ìjọba kò buwọ́lu àbá owó oṣù wọn tuntun.
Wo iye igba ti ASUU ti da ise sile ni Naijiria:
BBC se akojopo odiwon iye igba ti egbe Oluko Fasiti ASUU ti se iyanselodi pe:



















