Olubadan Coronation: Olubadan tuntun kéde pé oyè Ibadan kìí ṣe fún títà

Oríṣun àwòrán, oyoaffairs
Igbimọ afọbajẹ ilẹ Ibadan ti sọ pe ẹnikẹni ti yoo ba jẹ baale, mọgaji tabi jagun niluu Ibadan gbọdọ ni awọn amuyẹ kan.
Wọn tun fi kun pe irufẹ eeyan bẹẹ gbọdọ ni ipa ti wọn ti ko sẹyin ninu ilọsiwaju ilẹ Ibadan, ki wọn to fi irufẹ ẹni bẹẹ joye.
Igbimọ naa ni awọn yoo kede awọn ohun amuyẹ naa lẹyin ipade ti yoo waye nile Olubadan ti yoo gba ade laipẹ, Lekan Balogun.
- Ìwà àìlajú ní Russia hù bó ṣe kọlu ọ̀wọ̀n ìràntí ìṣekúpani - Ukraine
- Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà míì ti jáde láyé
- Alaafin, Ooni àtàwọn àgbà Yorùbá míì bẹ̀rẹ̀ ìdóòlà aáwọ̀ láàrin Tinubu àti Aregbesola
- Wo ìdí mẹ́ta tí Buhari fi ń rìnrìnàjò lónìí yàtọ́ sí pé ó ń lọ fún ìtọ́jú ara rẹ̀ ní London
- Ọkùnrin kan dágbére fáyé lẹ́yìn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀
- Wo àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ṣàtìlẹyìn fún Russia àti àwọn tó wà lẹ́yìn Ukraine
- ASUU Strike: ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ yóò ṣèpàdé lónìí
- Victor Akinwa, afurasi tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé o gún orí bàbá rẹ̀ nínú odó ti kó sí gbaga ọ́lọ́pàá ní Ondo
- Àwọn agbébọn yabo ibi ètò ìgbéyàwó, jí ìyàwó gbé lọ
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Ọtun Balogun Ilẹ Ibadan, Oloye Tajuden Ajibola sọ pe igbesẹ naa wa ni ibamu pẹlu ọrọ ti Olubadan tuntun sọ pe, oye nilẹ Ibadan kii ṣe fun tita lasiko ti oun ba gori oye.
Ajibola ni ẹnikẹni ko le jẹ oye ni Ibadan ayafi to ba kọkọ ni awọn amuyẹ kan, ki igbimọ afọbajẹ to buwọlu irufẹ ẹni bẹẹ fun oye jijẹ.
Awọn nnkan mii ti wọn tun mẹnuba nibi ipade ti wọn ṣe ni bi ifinijoye Olubadan tuntun yoo ṣe waye lọsẹ to n bọ.
Koko ohun ti igbimọ Olubadan fi ẹnu ko le lori ree:
Awọn igbimọ Olubadan tun sọrọ nipa bi wọn yoo ṣe fun awọn oloye ni igbega sii lẹyin ti Otun Olubadan ba gba ade tan.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn ti oye wọn yo gbe pẹẹli si ni oloye Lateef Adebimpe, Olubunmi Isioye, ati Abiodun Kola-Daisi.
Awọn yoku ni Hamidu Ajibade gẹgẹ bii Osi Balogun, Ekerin Balogun, Ekerin Olubadan ati Ekarun Olubadan.
Awọn ti yoo tun wa ninu igbimọ ti yoo ṣe iwuye naa ni Oniroko ti Iroko, Ismaila Abioye ati Baale Ajia Olorungbuji, Oladepo Suleiman.
Ajibola ni wọn yoo fi orukọ awọn eeyan naa ṣọwọ si gomina gẹgẹ bii ọmọ igbimọ ọhun lati buwọlu.
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni Balogun ilẹ Ibadan, oloye Owolabi Olakulehin ati Osi Balogun, oloye Gbadamosi Adebimpe.
Awọn yoku ni Ashipa Balogun, oloye Kola Adegbola; ati Ekerin Balogun, oloye Olubunmi Isioye.
Awọn mii to tu wa nibẹ ni Ashipa Olubadan, oloye Eddy Oyewole; Ekerin Olubadan, oloye Abiodun Kola-Daisi; ati Ekarun Olubadan, oloye Hamidu Ajibade.

















