Ondo killing: Ilé ẹ̀jọ́ ni Akure ti ni ki afurasi Victor Akinwa sì wà ní àhámọ́ títí ìwádìí lórí ikú bàbá rẹ̀ á fi parí

Oga olopaa Ondo

Oríṣun àwòrán, @Ondo Police

Victor Akinwa, afurasi tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé o gún orí bàbá rẹ̀ nínú odó ti kó sí gbaga ọ́lọ́pàá ní Ondo

Olorun ma fun eda ni ọmọ to maa gbẹ̀mi rẹ̀ ni adura ti ọ́pọ́ n gba lẹ́yin ti iroyin iku Justus jade.

Ile ejo majisireeti kan ni ilu Akure ni ipinle Ondo to wa ni guusu iwo oorun Naijiria ti pase pe ki wọ́n fi Victor Akinwa si ahamọ́.

Victor Akinwa ni eni odun metalelogun to n se ise gẹrigẹri fun awọn eeyan ni agbegbe Basic Road ni Idanre.

Ogbeni Obadasa Ajiboye to je agbejoro fun ileese olopaa lori esun naa ni pe Victor la ọmọ odo mọ́ baba rẹ̀ Justus lori ni ojo kokanlelogun, osu kokanla to koja ni eyi to si pada ja si iku fun Justus.

Àkọlé fídíò, Aáwọ̀ tó ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine ti mú àlékún bá iye owó epo rọ̀bì lágbàyé

Kini awọn agbofinro sọ lori isẹ̀lẹ̀ yii?

Agbejoro olopaa naa ni pe eyi se lodi si iwe ofin Naijiriia abala 36 ati 319 ninu ti Criminal Code, Cap. 37, Vol. 1 iwe ofin ipinle Ondo ni Naijiria ti odun 2006.

Àkọlé fídíò, Khadijat Okunnu:Olùdíje ipò ààrẹ Nàìjíríà tó sọ pé nkán gbódọ̀ dàrú ní Nàìjíríà kò

Bakan naa lo rọ ileejo lati fi Victor si ahamọ sii titi idajọ́ yoo fi waye.

Adajo Damilola Sekoni nile ẹjọ́ naa ni ilu Akure ti pasẹ pe ki Victor si wa ni ahamọ ni Olokuta Custodial Centre ni ipinle Ondo.

Adajo sun igbejo maa titi di ojọ́ kokanlelogbon, osu keta, odun yii.

Àkọlé fídíò, Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Mc Lively aderinposonu Naijiria