Ash Wednesday 2024: Wo ìtumọ̀ àyájọ́ 'Ash Wednesday' tó wáyé lónìí àti pàtàkì rẹ̀ fún àwọn krìstíẹ́nì?

Ash
Àkọlé àwòrán, Obinrin miran to n gba eeru lati fi sori ara rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oni, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2024, ni ayajọ ọjọ eeru ''Ash Wednesday'' ti awọn onigbagbọ, ọmọ lẹyin Kristi n parapọ lati ṣe ayajọ ọjọ naa.

Ayajọ ọjọ ti awọn ọmọlẹyin Kristi ka si ọjọ mimọ, ti wọn yoo fi eeru si iwaju ori wọn, ti wọn yoo si tẹsiwaju lati jẹ ẹran.

Eyti jẹ ami fun ibẹrẹ awẹ Lent, ti awọn kristiẹni ma n gba ni ọdọọdun.

Archbishop ijọ Canterbury, Justin Welby ni gbigba eeru naa si iwaju ori ṣe afihan igbagbọ awọn Kristẹni lori oore ọfẹ ti wọn ri gba lọwọ Ọlọrun.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ki ni pataki Ọjọ Eeru ninu Igbeaye awọn Onigbagbọ?

Ọjọ eeru to wọpọ laaarin awọn onigbagbọ ti Ijọ Aguda, Ijọ Anglican, Methodist ati awọn Ijọ igbalode miran.

Ni ọpọlọpọ awọn ijọ onigbagbọ, wọn ma n lo eeru ti wọn jo ku lara imọ ọpe ti wọn lo fun ọdun Ọjọ imọọpe (Palm Sunday), to waye ni ọdun to kọja.

Ọjọ mimọ ni ayajọ ọjọ eeru jẹ lagbaye fun awọn Kristẹni gẹgẹ bi ọjọ ti wọn n pe ni akoko Lẹnti eyi tii ṣe akoko awẹ ati adura.

O jẹ akoko ironupiwada fun ọsẹ mẹfa ṣaaju ọdun ajinde. Aawẹ yii maa n waye fun ogoji ọjọ gẹgẹ bi Jesu Kristi ti gba a ninu bibeli.

Lasiko yii lọdun ti a wa yii, awọn ọmọ ijọ Katoliki ni Naijiria n lo ọjọ eeru lati fi ṣ'ọfọ awọn to fara gba ninu gbogbo iwa ipa to damu orilẹede yii.

Ash

Ọpọlọpọ awọn oluso agutan ati pasito ma n lo ọjọ naa lati fi se iwaasu to ba asiko naa mu.

Eeru ti ayajọ ọjọ yii se apejuwe iku ati ironupiwada eleyii ti awọn adari ijọ ma n fi si awọn ara ilu lori, pẹlu ọrọ wi pe' éeru fun eeru, iyẹpẹ ni wa, ati wi pe ilẹ la o padasi.

Bakan naa ni wọn gbagbọ wi pe ti awọn onigbagbọ ba se n gba ami agbelebu yii sori, wọn n jẹwọ ẹsẹ wọn fun Ọlọrun.

Asiko yii lo n ṣaaju ọdun Ajinde

Ọdun Ajinde lo ṣafihan iku ati ijinde Jesu Olugbala kuro ni ipo oku lọjọ kẹta leyin to ku lori igi agbelebu

Ash
Àkọlé àwòrán, ọmọbinrin kan ti oun naa n sami agbelebu fi ṣe Ọjọ́rùú eérú tọdún 2021
Odomokunrin kan
Àkọlé àwòrán, Odomokunrin kan n gba eeru tirẹ lọwọ Adari isin lonii nile ijọsin Aguda kan

Wo bí wọ́n ṣe sàmì Ọjọ́rùú eérú '''Ash Wednesday' tọdún 2023 ni àwon ibìkan

Wo bi awọn kan ṣe ti sami ayẹyẹ ọjọru eeru to jẹ ibẹrẹ awẹ Lenti ninu ijọ Aguda Mimo.

Ash
Àkọlé àwòrán, Ọpọ ero ni ko wa sile ijọsin nitori ajakalẹ arun Coronavirus to fofin de apejọpọ ero pupọ ju kaakiri
Ash
Àkọlé àwòrán, Ile ijosin Aguda kan ree pẹlu iwọnba ero perete yatọ si ti ọpọlọpọ ọdun sẹyin nitori ajakalẹ arun Covid 19
Ash
Àkọlé àwòrán, Obinrin miran to n gba eeru lati fi sori ara rẹ
Ash
Àkọlé àwòrán, Wo eeru ti wọn n gba si ori lati sami ayajọ ibẹrẹ awẹ Lenti naa