'Ẹ̀wọ̀n àti owó ìtanràn ń dúró dè ọ́ tó o bá fi ẹnu já wáyà lórí ayélujára'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Latigba ti ikọ ẹgbẹ agbabọọlu orileede Naijiria, Super Eagles ti padanu ife ẹyẹ ilẹ Afrika sọwọ akẹgbẹ wọn lati orileede Ivory Coast ti wọn ṣagbatẹru idije to wa s’opin lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii ni awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ sii sọrọ alufanṣa si ikọ ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ wa.
Ko si ohun meji to fa a, bi ko ṣe bi Super Eagles ko ṣe fakọyọ lasiko ifẹsẹwọnsẹ ọhun, ti wọn si jẹ ki Ivory Coast gba ife ẹyẹ naa mọ wọn lọwọ.
Ko sẹni meji ti awọn ọmọ Naijiria sọrọ alufanṣa si to kọja Alex Iwobi to wọ aṣọ nọmba ikẹtadinlogun, ẹni to n di aarin Super Eagles mu.
Awọn eeyan naa ni latigba ti idije ọhun ti bẹrẹ ni Iwobi ko ti ta biọbiọ, ti wọn si ni o n ba ifẹsẹwọnsẹ ti ikọ naa ti n gba lati ibẹrẹ pẹpẹ jẹ titi de aṣekagba.
Orileede Ivory Coast lo ṣe ipo kini, ipo keji ni Nigeria ṣe nibi ifẹsẹwọnsẹ ọhun, nigba ti orileede South Afrika ṣe ipo kẹta.
Bi awọn eeyan ṣe n sọrọ buruku sii Iwobi lori ayelujara lo mu ko lọ yọ gbogbo awọn aworan rẹ kuro lori ikanni Instagram, to si kede pe oun yoo fi ayelujara silẹ fun igba diẹ.
Pupọ ọmọ Naijiria ni wọn n sọ pe Iwobi lo fa ijakulẹ Super Eagles.
Mo wa pẹlu ẹ - Minisita fọrọ ere idaraya ni Naijiria fọkan Iwobi balẹ

Oríṣun àwòrán, Alex Iwobi/Facebook
Ṣugbọn minisita fọrọ ere idaraya lorileede Naijiria, Sẹnetọ John Owan Enoh ti wa gba agbabọọlu naa ni imọran lati ma ṣe jẹ ki awọn ọrọ abuku ti awọn araalu n sọ sii wọ ọ lara.
O ni oun nigbagbọ pe gbogbo ikọ Super Eagles ni wọn sa ipa wọn lati de ipele ti wọn de nibi idije naa, ati pe fun anfaani orileede wọn ni.
Bakan naa lo sọ pe ọpọ ni ko mọ pe iwa ọdaran ni lati maa sọrọ alufanṣa si awọn eeyan lori ikanni ayelujara, ti ofin si tako.
Ki ni ofin sọ nipa iwa ọdaran ori ayelujara ti a mọ si 'Cybercrime' ọdun 2015?
Awọn nnkan wọnyi lẹ ni lati mọ tabi kiyesara ko to di pe ẹ sọrọ tabi kọ ọrọ sori awọn ikanni ayelujara kaakiri.
Ofin iwa ọdaran ori ayelujara ti Naijiria tọdun 2015 (Nigerian Cybercrime Act 2015) fun Aarẹ orileede ni agbara lati lo ipo rẹ lati ṣe agbekalẹ awọn ẹrọ kọmputa, itakun ati oniruuru ohun elo lati fi daabo bo orileede tabi eto ọrọ aje, ati igbayegbadun araalu.
Ofin iwa ọdaran ori ayelujara ti Naijiria tọdun 2015 (Nigerian Cybercrime Act 2015) gbe idajọ iku kalẹ fun ẹni to ba tapa si ilana ati ofin tabi agbekalẹ, eyi to tako agbekalẹ idagbasoke orileede Naijiria, tabi to ja si iku eeyan.
Labẹ ofin iwa ọdaran ori ayelujara ti Naijiria tọdun 2015 (Nigerian Cybercrime Act 2015) awọn to n wọnu ẹrọ kọmputa ẹlomiran laitọ ti a mọ si Hackers yoo ni lati san miliọnu mẹwaa naira tabi lọ ṣẹwọn ọdun marun-un gbako.
Ijiya yii naa lo wa fun ẹni to ba lu jibiti ori ayelujara nipa fifi atẹjiṣẹ ori ayelujara ranṣẹ tabi lilo ẹrọ ẹlomiran.
Bakan naa, ofin iwa ọdaran ori ayelujara ti Naijiria tọdun 2015 (Nigerian Cybercrime Act 2015) tako jibiti lilo orukọ olorukọ lori ayelujara ti wọn n pe ni theft, toun naa si ni ijiya ẹwọn ọdun mẹta ninu tabi ki ẹlẹṣẹ naa san miliọnu meje Naira.
Apẹẹrẹ eyi ni ti ẹni to lo orukọ Oloye Bọla Ahmẹd Tinubu lori ikanni Facebook, ti ọwọ ọlọpaa si tẹ.
Ẹṣẹ nla tun ni gbigbe aworan ibalopọ awọn ọmọde sori ayelujara, to ni ijiya ẹwọn ọdun mẹwaa ninu tabi ki ẹlẹṣẹ naa san ogun miliọnu naira, tabi ko san owo, ko si tun ṣẹwọn papọ.
Bi ẹṣẹ ti iru ẹni bẹẹ ba ṣẹ ba ṣe to ni yoo sọ iru idajọ ti yoo gba. Awọn ẹṣẹ miran to fara pẹ ẹ tun ni: ṣiṣe, gbigba ati pinpin tabi nini fọnran tabi fọto ibalopọ ọmọde.
Eyi ti wọn pe ni Cyber-stalking, iyẹn gbigba ohun to pamọ eeyan lati maa fi tako ẹni naa tabi Cyber-bullying toun jẹ sisọ tabi kọ ọrọ alufanṣa nipa eeyan kan ni idajọ ẹwọn ọdun kan ninu tabi ki ẹlẹṣẹ lọ san miliọnu meji naira.
Ẹlẹṣẹ le san owo itanran miliọnu meji Naira, ko si tun ṣẹwọn pẹlu rẹ. Lati ori miliọnu meji Naira titi de miliọnu marundinlọgbọn Naira ati ẹwọn ọdun kan si ẹwọn ọdun mẹwaa ni idajọ naa fi wa.
Iru ẹsun ti wọn ba ka si ẹlẹṣẹ lọrun ni yoo sọ iru idajọ ti yoo gba.
Ofin iwa ọdaran ori ayelujara ti Naijiria tọdun 2015 (Nigerian Cybercrime Act 2015) tako lilo orukọ ileeṣẹ tabi ṣiṣi ikanni ayelujara to jọ ti ileeṣẹ kan lati maa fi lu jibiti, eyi ti wọn n pe ni cybersquatting, to si ni ijiya ẹwọn ọdun meji gbako ninu tabi ki ẹlẹṣẹ san miliọnu marun-un naira.
Yatọ si pe ẹlẹṣẹ san owo itanran, o tun ṣee ṣe ki iru ẹlẹṣẹ bẹẹ san owo, ko si tun ṣẹwọn.
Ofin yii tun tako pinpin ọrọ abuku nipa ẹya tabi iran kan, eyi ti wọn n pe ni racist and xenophobic material sori ikanni ayelujara bii Facebook ati Twitter.
Bakan naa lo tun tako biba ẹsin, awọ tabi iṣẹda awọn ẹya kan jẹ.
Ẹni ti ọwọ ba tẹ yoo ṣẹwọn ọdun marun-un gbako, tabi ko san miliọnu mẹwaa naira gẹgẹ bi owo itanran. O si tun le san owo, ko si tun lọ sẹwọn.
Igbesẹ lilo ofin yoo bẹrẹ - Ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ
Ju gbogbo rẹ lọ, ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria ti wa sọ pe awọn yoo bẹrẹ sii gbe igbesẹ akikanju lari mọ awọn to n pin ayederu iroyin ka lori ayelujara ati awọn to n sọrọ alufanṣa ori ayelujara si awọn ẹlomiran.
Ninu atẹjade ti agbẹsọ ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejọbi gbe jade lọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun 2024, o ni ki awọn araalu dẹkun gbigbe awọn iroyin ẹlẹjẹ ti ko fẹsẹ mulẹ kaakiri ori ayelura.
Bẹẹ lo ni ki wọn dẹkun sisọ ọrọ alufanṣa si awọn eeyan lori ikanni ayelujara, ati pe ẹni ti ọwọ ba tẹ yoo foju winna ofin to de sisọ tabi kikọ ọrọ alufanṣa lori ayelujara.















