Mọ̀ nípa Bolaji Agbede ti Access Bank fi rọ́pò olóògbé Herbert Wigwe gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà tuntun

Aworan Bolaji Agbede

Oríṣun àwòrán, ACCESS BANK/WEB

Ileeṣe Access Holdings Plc ti kede alakoso ati oludasilẹ agba tuntun fun ileeṣẹ naa lẹyin iku Herbert Wigwe to padanu ẹmi rẹ siluu Amẹrika.

Ọjọ Aje, ọsẹ yii ni igbimọ awọn alakoso ileeṣẹ naa gbe ikede yii sita - ọjọ keji lẹyin iku Herbert Wigwe to jẹ alakoso tẹlẹ.

Arabinrin Bọlaji Agbẹdẹ ni orukọ ẹni naa ti wọn sọ pe oun ni yoo ṣi maa tẹsiwaju.

Wigwe ati awọn marun-un miran ni wọn ku sinu ijamba ọkọ baluu ẹlikọpita ni alẹ ọjọ Ẹti to kọja.

Ijamba naa gba ẹmi Wigwe, iyawo ati ọmọ rẹ kan, to fi mọ awọn miran ti wọn jọ wa ninu rẹ.

Awọn alakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ aabo irin-ajo, National Transport Safety Board (NTSB) nigba ti wọn n sọrọ nipa iṣẹlẹ naa lọjọ Aiku to kọja yii jẹ ko di mimọ pe ọkọ baluu agberapa Airbus Helicopters EC-130 lo jabọ lule niluu California to wa nitosi ẹnubode Nevada.

Ọkan lara awọn alakoso NTSB, Michael Graham ati oluwadi kan, Aaron Sours, sọ pe iwadii fihan pe lara nnkan to ṣokunfa ijamba naa ni pe ojo n rọ lọwọ lasiko ti ijamba naa waye.

“Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe bi oju ọjọ ṣe ri lasiko naa, ati pe ojo to n rọ ati iji to n ja lo fa ohun to ṣẹlẹ.”

Nigba ti awọn eeyan ṣi n kẹdun lẹyin ti awọn igbimọ alakoso fidi rẹ mulẹ pe Herbert Wigwe ti jade laye, ni wọn tun kede Arabinrin Agbẹdẹ gẹgẹ bi adele.

Wọn sọ ninu atẹjade ti akọwe ileeṣẹ naa, Sunday Ekwochi, fi sita, pe “Ifidimulẹ iyansipo rẹ yoo da lori ontẹ ati aṣẹ lati ọwọ banki apapọ Naijiria, CBN,.”

Taa ni Bolaji Agbede

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Arabinrin Bolaji Agbẹdẹ lo wa ni ipo to ga ju ninu awọn alakoso agba to wa ni ẹka idagbasoke okoowo fun ileeṣẹ Access Holdings Plc.

Yoo si gbakoso lẹyin ti CBN ba buwọlu u.

Igba akọkọ ree ti ileeṣẹ Access yoo yan obinrin sipo alakoso agba lati igba ti wọn ti bẹrẹ iṣẹ.

Agbẹdẹ ni iriri to to ọgbọn ọdun ninu iṣẹ ifowopamọ ati okoowo.

Ọdun 1992 ni Agbẹdẹ bẹrẹ iṣẹ lẹkunrẹrẹ pẹlu Guaranty Trust Bank, to si ṣiṣẹ ni oriṣiriṣi ẹka, to fi mọ ọga agba to n risi ibaṣepọ pẹlu awọn onibaara, ati amojuto ibi ti banki naa n ko owo pamọ si.

O gba igbega si ipo mọnija ẹka banki naa kan lọdun 2002.

Lọdun 2003 ni Agbẹdẹ tun di alakoso agba fun ileeṣẹ ‘JKG Limited’.

Ọdun 2003 bakan naa, ni Arabinrin Bolaji Agbede darapọ mọ banki Access gẹgẹ bi igbakeji alakoso, eyi ti wọn yan an lati maa ṣakoso bi nnkan ṣe n wọle-jade pẹlu awọn ileeṣẹ to n ṣe kẹmika.

Siwaju sii, Agbẹdẹ di alakoso ẹka to n mojuto ọrọ awọn oṣiṣẹ fun banki naa lọdun 201. Nibẹ lo si wa to n ṣakoso ẹtọ idagbasoke ọmọniyan.

Lẹyin eyi lo tun gun oke si ipo oludari agba fun ẹka idagbasoke okoowo, ni Access Holdings , nibi to ti ko ipa ribiribi lẹka eto okoowo ati ayipada rere to ti de ba ileeṣẹ naa.

Bọlaji Agbẹdẹ kẹkọọ gboye Bachelor’s Degree ninu ẹkọ iṣiro (Mathematics and Statistics) ni fasiti ipinlẹ Eko lọdun 1990.

Bakan naa lo tun tẹsiwaju pẹlu ẹkọ rẹ, to si kẹkọọ gboye imọ ijinlẹ keji, Master’s Degree lori amojuto okoowo, lati fasiti Cranfield to wa nilẹ Amẹrika lọdun 2002.

Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Chartered Institute of Management nilẹ Amẹrika ati ọmọ ẹgbẹ Chartered Institute of Personnel Management lorileede Naijiria ni Agbẹdẹ jẹ.

Ọpọlọpọ imọ ati ikẹkọọ nipa oludari ati akọṣẹmọṣẹ ni Agbẹdẹ ti la kọja to si ṣe daadaa pupọ.

Lara wọn ni ti High-Performance Leadership Programme awọn alakoso Strategic Talent Management Programme niluu London gbe kalẹ.