'Bàbá ọmọdé, bàbá àgbà, èèyàn nlá ni Jimi Solanke tó di olóògbé'

Oríṣun àwòrán, jimi Solanke
Ọjọ Aje, ọjọ karun-un, oṣu Keji, ọdun 2024, ni agba olukọtan, asọtan, olorin ibilẹ, akewi to tun jẹ agba oṣere, Alagba Jimi Solanke jade laye.
Ẹni dun mejilelọgọrin ni.
Lasiko abẹwo ti BBC ṣe si ile oloogbe to wa niluu Ipara, nipinlẹ Ogun, iyawo rẹ, Oluwatoyin Sename, sọ pe Ọmọ Ọlọrun ni oun ma n pe ọkọ oun, nitori pe inu rẹ mọ́, ẹni to bẹru Ọlọrun ni, ti kii fẹ sẹ nnkan ti ko tọ ọ.
“Mi o le sọ bi iku rẹ ṣe ri ni ara mi, nitori pe alajọro mi ni.
“Ọlọrun nikan ni mo n wo loju bayii, nitori pe Jimi ni ọlọrọ kan ṣoṣo ti mo.”
Bakan naa ọba ilu Iapara, Ọba Taiwo Taiwo sọ pe Baba Amuludun ilu Ipara lo jẹ.
Oba Taiwo sọ pe Baba to gbe ogo ilu naa ga ni Solange jẹ nigba aye rẹ.
O ni awọn nnkan ti oloogbe ṣe si ilu Ipara, ko ṣe e fi ẹnu sọ tan.
Ẹwẹ, ọkan lara awọn ọmọ oloogbe, Tioluwalope Atoyebi sọ fun BBC pe, baba to mọ iyi ọmọ titi di ọjọ iku ni.
“Lootọ ni mo ti lọ sile ọkọ, amọ baba mi ṣi ma n sẹ mi bi ẹni pe mo ṣi wa labẹ wọn.”
Awọn ẹbi oloogbe Jimi Solanke sọ pe ẹni ti orukọ rẹ ko le parun lailai ni, nitori pe ọpọ eeyan ni iran yii ati iran to n bọ ni yoo si lo awọn iṣẹ rẹ ninu iwadii imọ ijinlẹ wọn.
Ta ni Jimi Solanke?
Fun ọpọlọpọ to wo awọn ere ori itage bii Kurunmi ati Ovonramwen Nogbaisi ti Ola Rotimi kọ, Death and the King's Horseman ti Wole Soyinka kọ ati bẹẹ bẹẹ lọ, wọn mọ pe gbagada ni oju Jimi solanke wa ninu awọn ere naa tori oun ni o ko ipa to tobi julọ ninu wọn.
O ti le ni aadọta ọdun to ti lo ninu iṣẹ tiata nipa gbigbe aṣa ibilẹ Yoruba ati agbegbe rẹ ga.
Ilu Eko ni wọn bi Solanke si ni ọdun 1942.
Ni ẹka ti orin, ọpọlọpọ orin ati orin itan ni Baba Solanke ti kọ ati eyi ti ko tilẹ tii gbe jade rara rara.
Awọn orin ọmọde naa ko gbẹyin nibẹ gẹgẹ bi ohun baba Solanke ṣi ṣe n dan ninu orin yi



