Òṣìṣẹ́ ìlera tí wọ́n pa sínú ọkọ̀ tó fi ń dóòlà ẹ̀mí ní Gaza
- Author, Ethar Shalaby
- Role, BBC Arabic

Oríṣun àwòrán, Feras Al Ajrami
Ìkìlọ̀: Ìròyìn ní àwòrán tó ṣàfihàn ikú àti ìfarapa
Ní nǹkan bíi aago méjì ọ̀sán ni ìròyìn náà tẹ̀ wá lọ́wọ́. Onímọ̀ ètò ìlera Mahmoud al-Masry àti àwọn ikọ̀ rẹ̀ wà ní ilé ìwòsàn al-Awda ní àríwá Gaza níbi tí wọ́n ti ń retí ìpè láti lọ ṣètọ́jú àwọn tó bá fara kásá ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn.
Kò pẹ́ sí ìgbà náà ni olùkéde kéde pé wọ́n ti ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ tó ń dóòlà ẹ̀mí aráàlú 5-15 – èyí tí ikọ̀ bàbá Mahmoud, ẹni tí òun náà jẹ́ onímọ̀ ìlera tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì wà nínú rẹ̀.
Mahmoud àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ sáré lọ síbẹ̀ láti lọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi ìkọlù náà.
Nígbà tí wọ́n fi máa débẹ̀, wọ́n bá ọkọ̀ náà ní ẹ̀gbẹ́ kan tó ti jóná, tí gbogbo àwọn ènìyàn tó wà nínú rẹ̀ náà sì ti jóná kọjá mímọ̀.
Ìròyìn kan tí BBC Arabic tó ń tẹ̀lé àwọn pawọn òṣìṣẹ́ ìlera tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ṣàfihàn bí Mahmoud ṣe gbarata nígbà tó ri pé bàbá òun, Yosri àti àwọn méjì mìíràn ló wà níbẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Feras Al Ajrami
Ní ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ìyẹn ọjọ́ karùn-ún lẹ́yìn tí ogun bẹ̀rẹ̀ láàárín Gaza àti Israel.
Wọ́n fi aṣọ funfun wé òkú Yosri Al-Masry pẹ̀lú koto tó dé sórí.
Níbi ètò ìsìnkú bàbá rẹ̀, Mahmoud kúnlẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ òkú náà, tó sì ń fi ọwọ́ nu ojú rẹ̀ nù bí ó ṣe ń bomi lójú pẹ̀pẹ̀, tí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ sì ń tù ú nínú.
Akọ̀ròyìn Feras Al Ajrami ló ya àwòrán bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe lọ fún àkọ́ọ́lẹ̀ ìròyìn náà.
Lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀, Mahmoud, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n tí òun náà ní ọmọ mẹ́ta gba ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan láti fi kúrò ní ẹnu iṣẹ́ àmọ́ tó ní pẹ̀lú bí ọkàn òun ṣe pòruru, òun fẹ́ padà sí ẹnu iṣẹ́.
Ó ní ó wu òun láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ènìyàn Palestine.
Ó gbé àwòrán bàbá rẹ̀ sí ojú fóònù rẹ̀ nítorí ó ní òun fẹ́ máa rí i ní gbogbo ìgbà.

Oríṣun àwòrán, Feras Al Ajrami
Àkókò tí wọ́n jọ lò gbẹ̀yìn ni bíi wákàtí díẹ̀ kí Yosri tó kú. Ó ní kí Mahmoud ṣe kọfí fún òun èyí tó mu kó tó kírun ọ̀sán. Lẹ́yìn náà ni wọ́n pe ọkọ̀ rẹ̀ tó sì jáde lọ.
Ní ọjọ́ méjì ṣaájú àkókò náà ni Mahmoud farapa níbi tó ti fi ọrùn àti ẹ̀yìn ṣèṣe tí wọ́n sì gbe lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ilé ìwòsàn.
“Níṣe ni bàbá mi ń kọminú lórí àpá mi nígbà náà.
“Nígbà tí mo bá ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn, bí mo ṣe ń sáré lọ síbi ọkọ̀ rẹ̀, ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún mi láti bá bàbá mi tí ẹ̀yà ara rẹ̀ ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, tó sì ṣe mí bíi pé kí n dákú.”
Mahmoud ló ti ń ṣiṣẹ́ bí òṣìṣẹ́ ètò ìlera pàjáwìrì láti bí ọdún méje sẹ́yìn, tó sì wà ní ìlú Jabalia ní àríwá Gaza gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ Palestine Red Cross Society (PRCS) lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Láti ìgbà tí ikọ̀ Hamas ti ṣe ìkọlù sí Israel lọ́jọ́ keje, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 níbi tí èèyàn 1,200 ti pàdánù ẹ̀mí wọn, tí wọ́n sì fi èèyàn 250 sí àhámọ́ ni ikọ̀ tó ṣe àgbéjáde ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fídíò náà ti ń tẹ̀lé àwọn ọkọ̀ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì.
À ti ìgbà náà ni Israel náà ti ń ṣe ìkọlù padà sí Gaza.

Oríṣun àwòrán, Feras Al Ajrami
Èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn nínú oṣù Kẹwàá tí ìkọlù náà bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ètò ìlera tí ikọ̀ Hamas ń ṣàkóso rẹ̀ ṣe sọ, tí wọ́n sì ní ó ti wọ ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gbọ̀n ènìyàn tí ti kú báyìí.
Bí wọ́n ṣe ń ya àwọn òṣìṣẹ́ ìlera tí wọ́n ń wa ọkọ̀ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì níbi tí wọ́n ti ń lọ yọ àwọn ènìyàn nínú ewu pàápàá àwón ọmọdé lásìkò tí wọ́n bá farapa tàbí pàdánù ẹ̀mí wọn ṣàfihàn àwọn nǹkan tí ojú wọn ń rí.
Lásìkò tí ogun náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, òṣìṣẹ́ mìíràn, Rami Khamis ń sunkún ní ẹsẹ̀ táyà ọkọ̀ rẹ̀.
Ó ní wọ́n pe òun láti lọ dóòlà àwọn ènìyàn kan tí ilé wó lulẹ̀ mọ́ lórí tí ọ̀pọ̀ sì jẹ́ ọmọdé àti obìnrin. Ó ní nígbà tí òun wọ ilé kan òun bá òkú àwọn ọmọ obìnrin mẹ́ta kan nílẹ̀ tí ọkàn òun sì sáré lọ sára àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta òun.
“Mi ò le mú mọ́ra ló fà á ti mo fi bú sẹ́kún bí mo ṣe ri wọ́n ni fídíò mi tó gba ìgboro dá lé lórí.”
Òṣìṣẹ́ mìíràn, Alaa Al-Halaby ní ikọ̀ ọmọ ogun Israel ṣe ìkọlù sí ilé ìbátan òun kan, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló kú sí abẹ́ ilé náà tí wọn kò rí yọ.
Ó ní bí òun ṣe ń súnmọ́ ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti yọ àwọn èèyàn lábẹ́ ilẹ̀ ni àwọn kan sọ fún òun pé ẹ̀yà ara ọmọbìnrin kan wà níbẹ̀.
“Ohun tó máa ń wá sí ọkàn mi nígbà tí mo bá mú ẹ̀yà ara ọmọdé kan dání ni ìràntí ọmọ tèmi gan.”

Oríṣun àwòrán, Feras Al Ajrami
Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí ogun bẹ̀rẹ̀ láàárín Israel àti ikọ̀ Hamas ni Israel ṣèkìlọ̀ fún àwọn ará ìlú ẹkùn àríwá Gaza láti kúrò níbẹ̀ lọ sí ẹkùn gúúsù.
Ọ̀pọ̀ àwọn ikọ̀ ìlera náà ló kó àwọn àwọn ẹbí wọn nítorí ààbò àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìlera náà kò lè kúrò ni ti wọn.
Ní orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ni wọ́n ti máa ń bá àwọn ẹbí wọn sọ̀rọ̀.
Rami tó ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìlera pàjáwìrì náà ní nígbàkígbà tí ìkọlù kan bá ti ṣẹlẹ̀ ní Gaza ni ọmọ òun máa ń so mọ́ òun láti bẹ òun pé kí òun má ṣiṣẹ́.
Alaa náà ni àwọn ọmọ òun ń sunkún ni nígbà tí òun fẹ́ fi wọ́n sílẹ̀ àti pé òun máa ń gbàdúrà ní gbogbo ìgbà pé kí Ọlọ́run darí òun láyọ̀ tí òun báti ń jáde lọ.
Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn, lásìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera náà wà nínú ọkọ̀ wọn níwájú ilé ìwòsàn al-Awda, ìbúgbàmù kan wáyé tí oníkálùkù wọn sì ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
PRCS ní àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ mẹ́rìnlá ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn láti ìgbà tí ogun ti bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ keje oṣù Kẹwàá.
Agbẹnusọ PRCS, Nebal Farsakh ní gbogbo iṣẹ́ tí àwọn ń ṣe ló mú ewu lọ́wọ́ àti pé ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ló ti bá ogun lọ láti ìgbà tí ìkọlù náà ti bẹ̀rẹ̀.
Bákan náà ló ní wọ́n máa ń mọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe ìkọlù sí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn lásìkò tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ wọn lọ́wọ́.
Àjọ PRCS jẹ́ àjọ ẹlẹ́yinjú àánú tí kìí ṣe ti ìjọba, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àjọ International Federation of Red Cross and Red Crescent Societies (IFRC).

Oríṣun àwòrán, Feras Al Ajrami
Farsakh ní gbogbo ọkọ̀ tí àwọn fi ń ṣiṣẹ́ ní Gza ló ní àmì ìdánimọ̀ àwọn, èyí tó wà ní iwájú ọkọ̀ pàjáwìrì 5-15 tí wọ́n pa bàbá Mahmoud nínú rẹ̀.
Ó ní PRCS gbàgbọ́ pé ikọ̀ ọmọ ogun Israel mọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe ìkọlù sí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn náà ni.
“Pẹ̀lú gbogbo àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò fi ṣiṣẹ́, wọn ò lè sọ pé àwọn kò ri pé àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ni ọkọ̀ tí wọ́n ṣe ìkọlù sí.”
Àmọ́ iléeṣẹ́ ológun Israel ní àwọn kìí mọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe ìkọlù sí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera tó fi mọ́ àọn òṣìṣẹ́ àjọ PRCS.
Wọ́n ní àwọn ọmọ ogun ikọ̀ Hamas ni àwọn ń gbìyànjú láti ṣe ìkọlù sí, tí àwọn kò sì ní èròńgbà láti ṣe ìpalára fún àwọn aráàlú kankan.
Wọ́n fẹ̀sùn kan pé àwọn ikọ̀ Hamas ń lo àwọn ọkọ̀ òṣìṣẹ́ ìlera láti fi bojú ṣe ìkọlù, tí wọ́n sì fi ń kó ohun ìjà láti ibìkan sí òmíràn.
Farsakh ní láti ìgbà tí àwọn ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti pèsè ìtọ́jú fún àwọn ènìyàn ní Palestine, àwọn kò ṣe ojú ṣàájú pẹ̀lú àwọn tó ń ja ìjà náà.
“Iṣẹ́ wa níbí ni láti pèsè ètò ìlera àti ẹyinjú àánú fún àwọn èèyàn.”

Oríṣun àwòrán, Feras Al Ajramy
“Iṣẹ́ àti ìṣe wa kò yàtọ̀ sí ti àwọn International Red Cross and International Red Crescent, èyí tó dálé ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú òótọ́ inú láì sí àtojúbọ̀ láti ibikíbi. A ò gba ẹnikẹ́ni láyé láti tojú bọ iṣẹ́ wa tàbí sọ ohun ta máa ṣe fún wa.”
Ní bíi ìparí oṣù Kejìlá, PRCS mú àdínkù bá iṣẹ́ wọn ní àríwá Gaza lẹ́yìn tí ikọ̀ ọmọ ogun Israel ṣe ìkọlù sí ibùdọ wọn tó wà ní Jabalia.
Àmọ́ iléeṣẹ́ ogun Israel jiyàn pé àwọn ṣe ìkọlù sí ilé ìwòsàn náà, wan ní pé àwọn ṣàwárí pé àwọn ọmọ ogun Hamas ní ilé ìwòsàn Red Crescent èyí tí àwọn ti rí tí wọ́n wọ aṣọ iṣẹ́ Red Crescent.
Farsakh ní ira tó jìnà sí òótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà àti pé àwọn òṣìṣẹ́ àwọn, ọkọ̀ pàjáwìrì àti àwọn èèyàn tó farapa tí àwọn ń ṣe ìtọ́jú fún nìkan ló wà nílé ìwòsàn àwọn.
Alaa, Rami àti Mahmoud ni wọ́n ti kó lọ sí ẹkùn gúúsù Gaza láti tẹ̀síwájú iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìlera pàjáwìrì ní Khan Younis – àmọ́ Rami tún ti padà sí ẹkùn àríwá.
Ní ìparí oṣù Kìíní, ìkọlù tẹ̀síwájú ní agbègbè Khan Younis, Mahmoud kó ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta láti lọ máa gbé ní Mawasi, ibi tí Israel ti ṣáájú pèsè fún ààbò.
Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin tí bàbá rẹ̀ jáde láyé, ó ní ìfarajìn òun láti túnbọ̀ máa ṣe ìrànwọ́ fún àwọn tó ń ṣàárẹ̀ àtàwọn tó farapa àti pé nǹkan tí bàbá òun ń fẹ́ kó tó jáde láyé tí òun yóò sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú rẹ̀.









