Omoyeni rí ẹ̀wọ̀n he fẹ́sùn fífi abẹ ya ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lára

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní fúnra ra oníkọ́ ní ń fi ẹnu ara rẹ̀ pé ikú, bí ènìyàn bá sì ní ìkà méjì yóò fi ọ̀kan ṣe ara rẹ̀.
Ilé Májísíréètì kan nílùú Akure, ìpínlẹ̀ Ondo ti fi obìnrin kan Omoyeni Opeyemi sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta àti àbọ̀ fẹ̀sún pè ó fi ìyà tí kò tọ́ jẹ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, Joel Sunday.
Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni àjọ ọlọ́pàá nawọ́ gán Omoyeni Opeyemi nígbà tí fọ́nrán kan tó ṣàfihàn bó ṣe fi abẹ yá Joel Sunday, ọmọ ọdún méjìlá, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lára, ṣe gba orí ẹ̀rọ ayélujára kan.
- Ta ni Ajé tí àwọn ọmọ Yorùbá lágbáyé ń ṣọdún rẹ̀ ní Ile Ife lónìí?
- Victor Akinwa tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé o gún orí bàbá rẹ̀ nínú odó ti kó sí gbaga ọ́lọ́pàá ní Ondo
- Ọkùnrin kan dágbére fáyé lẹ́yìn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀
- Àwọn agbébọn rọ́jò ìbọn fún Ọba aládé l'Ekiti, ó dèrò ilé ìwòsàn
- Ilé ẹjọ́ ju Mínísítà sẹ́wọ̀n ogún ọdún fún ìwà àjẹbánu
- Àwọn agbébọn yabo ibi ètò ìgbéyàwó, jí ìyàwó gbé lọ
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Ọmọ ọdún méjìdínlógún jí ènìyàn gbé
- Kí ló wáyé níbi ìpàdé NANS àti ìjọba àpapọ̀? àlàyé rèé
Kini o sele nibe ki Adajo to da ẹjọ́ rẹ̀?
Nínú fọ́nrán náà, Joel ni àpá tútù wà ní ara rẹ̀, tí ẹ̀jẹ̀ bòó, tí kò sì le rìn dáadáa.
Opeyemi, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì tó tún jẹ́ opó, ni wọ́n ka ẹ̀sùn márùn-ún sí lọ́rún tó fi mọ́ ìfọmọṣerú, ìgbèrò àtipànìyàn, àti ẹ̀sùn mẹ́ta mìíràn.
Adájọ́ O. A. Edwin nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kálẹ̀ ní Opeyemi jẹ̀bi ẹ̀sùn mẹ́rin nínú márùn ún tí wọ́n fi kàn án.










