Àlékún owó ilé ń tú ìdílé ká ní ìlú Eko

Sade níwájú àwòrán kan nínú yàrá rẹ̀
    • Author, Dara Onipede
    • Role, Video Journalist
    • Reporting from, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Nígbà tí Sade George ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, Tade ní ọdún méjìdínlógún (18) sẹ́yìn, ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni pé àwọn máa bá ara àwọn lálẹ́. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn gidi, tí wọ́n sì bí ọmọ kan ṣoṣo. (Kìí ṣe orúkọ wọn gangan nìyí)

Àmọ́ kò fi ìgbà kankan rò ó wí pé ọ̀rọ̀ ilé gbígbé le fa ìpínyà láàárín òun àti ọkọ òun.

Fún ọdún mẹ́wàá, ilé oní yàrá méjì (two-bedroom) ni wọ́n ń gbé ní agbègbè Yaba ní ìpínlẹ̀ Eko. Ilé ìgbé wọn yìí kò jìnà sí ilé ẹ̀kọ́ gíga kan tí Sade ti ń ṣiṣẹ́.

Àmọ́, ọdún tó kọjá ni wàhálà bá ìdílé wọn nígbà tí ìyá onílé wọn mú àlékún bá owó ilé láti ₦650,000 tí wọ́n ń san tẹ́lẹ̀ di ₦1,800,000.

"Níṣe ni à ń gbé papọ̀ bíi ìdílé kó tó di pé ìyá onílé wá fi owó kún owó ilé, èyí ló mú mi kó lọ sí ilé ẹbí mi tó wà ní Ikorodu pẹ̀lú ọmọ mi ṣùgbọ́n ọkọ mi kọ̀ láti kó tẹ̀lé wá," Sade sọ fún BBC.

Bí àwọn tọkọtaya náà kò ṣe lè san owó ilé tuntun yìí, tí wọn kò sì lówó láti gba ilé tuntun, Sade rí àǹfàní láti máa gbé ní ilé ẹbí wọn tó wà ní Ikorodu, èyí tó wà ní ìwọ̀n kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n (32km) sì ibi tó ń gbé tẹ́lẹ̀. Ọkọ rẹ̀, Tade ń ṣiṣẹ́ ní Onipanu, kìlómítà mẹ́fà (6km) sí ilé ìgbé wọn tẹ́lẹ̀.

Nígbà tí wọ́n ń gbé ní Yaba, igba náírà (₦200) ni Sade máa ń ná lọ sí ibi iṣẹ́ lójúmọ́ ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta náírà (₦3,000) ló ń ná láti ibi iṣẹ́ lọ sí Ikorodu tó ń gbé báyìí.

Kìí ṣe ìpèníjà owó ọkọ̀ tó ti lọ sókè nìkan kọ́ ni Sade ń kojú báyìí, wàhálà lílọ bíbọ̀ náà ń ṣàkóbá fún ìlera rẹ̀.

Ó ní àìsàn kan tó ń ba fínra láti ọjọ́ pípẹ́, tó sì ti máa ń lọ fún àyẹ̀wò ní ilé ìwòsàn tó wà ní Ikeja, tó sì jẹ́ pé yóò rin ìrìnàjò kìlómítà mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n kó tó le dé ilé ìwòsàn báyìí.

Ọpọ idile lo ti tuka niko ikokuro lati agbegbe kan si omiran

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣíṣe àyípadà ilé tó ń fa wàhálà

Láti ọdún díẹ̀ sí àsìkò yìí, bí owó ilé ṣe ń pọ̀ si jẹ́ nǹkan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ̀rọ̀ lé lórí, táwọn èèyàn pàápàá ìdílé ń wá ọ̀nà láti kojú.

Bí àwọn kan ṣe ń mú àdínkù bá irú oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ ni àwọn mìíràn ń mú àyípadà bá irú igbe ayé tí wọ́n ń gbé. Ọ̀pọ̀ ló ń kó kúrò níbi tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ láti kó lọ sí àwọn ìgbèríko tí ìrètí wà pé owó ilé wọn kò ní pọ̀ tó ti tẹ́lẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ lórí fún Paul Jegede tó ń ṣiṣẹ́ ní Ajah, ìgbèríko kan ní Lagos Island. Mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún náírà (₦1,1m) ló ń ṣàn lọ́dún fún yàrá kan tó ń gbé ní Ajah.

Nígbà tó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó tó sì ń wá ilé tó tóbi ló hàn si pe oun kò lè gba ilé sí Ajah mọ́ nítorí agbára rẹ̀ kò ká iye tí wọ́n ń pe àwọn ilé náà.

"Nítorí owó ilé àtàwọn nǹkan míì ló jẹ́ kí n kó kúrò ní Ajah lọ sí Egbeda," Jegede sọ fún BBC.

Ṣáájú kó tó kó lọ sí Ajah, ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún ló máa ń lò kó tó dé ibi iṣẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n tó máa ń lò tó wákàtí mẹ́rin báyìí lójú ọ̀nà bí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ bá ṣe pọ̀ sí.

₦900,000 ni Jegede ń san fún ilé oní yàrá méjì tó ń gbé ní Gowon Estate, Egbeda báyìí àmọ́ ₦80,000 ló fi ń wọ ọkọ̀ lọ síbi iṣẹ́ lóṣù dípò ₦35,000 tó máa ń ná nígbà tó wà ní Ajah.

Àwòrán àwọn ọ́fíìsì ní Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àlékún tó ń mú àdínkù bá owó tó ń wọlé

Yàtọ̀ sí èyí, aago mẹ́rin ìdájí ló máa ń jí nísìnín kó ba à lè rí bi jáde kúrò nílé ní aago márùn-ún kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún kó fi le dé ibi iṣẹ́ ní aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀.

"Lọ́jọ́ kan mo jí ní aago mẹ́rin ìdájí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sun ẹkún pé ṣé ó yẹ kí n lọ síbi iṣẹ́ lónìí?"

Ọ̀kan lára ohun ìnílò láti gbé ilé ayé ni ibùgbé jẹ́ ṣùgbọ́n fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé ní Eko, ohun tí ọ̀pọ̀ kò ní àǹfàní, tí wọ́n ń tiraka láti ní ni.

Báwọn kan ṣe ń sọ pé níṣe ni àlékún owó ilé ń sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di aláìnílé lórí mọ́, àwọn mìíràn ní kò jẹ́ kí àwọn rí owó fi pamọ́, tí owó tí àwọn ń ná láti fi rí ilé gbé pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.

Kofo Williams, akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe, tó tún ń ṣe èékánná ń gbé ní agbègbè Akoka, agbègbè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ pọ̀ sí, èyí tó máa ń jẹ́ kó rí àwọn èèyàn ra ọjà rẹ̀ dáadáa.

Nígbà tí àwọn onílé fi owó kún owó ilé àti ṣọ́ọ̀bù, ó pinnu láti sọ ilé rẹ̀ di ṣọ́ọ̀bù nígbà tí kò ní owó láti máa fi san owó ilé lọ́nà méjì.

Ó kó kúrò ní ibi tó ń gbé tẹ́lẹ̀ sí lọ sí Iyana Oworo níbi tó ti ń san ₦800,000 dípò ₦1,800,000 tí onílé rẹ̀ sọ owó ilé dì.

Àmọ́ Iyana Oworo jìnà sí ibi tí àwọn oníbàárà rẹ̀ wà àti ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀. Kofo, tó ń rán ara rẹ̀ lọ́wọ́ lórí ilé ẹ̀kọ́ ní òun máa ń pa tó ₦300,000 nígbà tí òun wà ní Akoka àmọ́ tí òun kò máa pa ju ₦50,000 tí òun wà báyìí.

Ìpínlẹ̀ Eko, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí oríkò ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, àmọ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé ibẹ̀ ń kọminú pé iye owó ilé ń ti àwọn kúrò ní ìlú náà.

Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ olùgbé tó lè ní mílíọ̀nù mọ́kànlélógún, nǹkan tí Paul, Kofo àti Sade ń kojú kò yàtọ̀ sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé ìlú Èkó ń kojú.